Jump to content

Hannah Idowu Dideolu Awolowo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Hannah Idowu Dideolu Awolowo
Àwòrán HID Awolowo ní ìwájú ilé ẹbí rẹ̀
Ìyàwó olórí ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà
In office
Ọjọ́ kínín Oṣù kẹwá ọdún 1954 – Ọjọ́ kínín Oṣù kẹwá ọdún 1960
Arọ́pòFaderera Aduke Akintola
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Hannah Idowu Dideolu Adelana

(1915-11-25)25 Oṣù Kọkànlá 1915
Ikenne, British Nigeria
Aláìsí19 September 2015(2015-09-19) (ọmọ ọdún 99) (ọ̀kàndínlọgọrún)
Ọmọorílẹ̀-èdèỌmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà
Ẹgbẹ́ olóṣèlúUnity Party of Nigeria (1978–1983)
Action Group (1950–1966)
(Àwọn) olólùfẹ́
Obafemi Awolowo
(m. 1937; died 1987)
ẸbíYemi Osinbajo (ọkọ-ọmọ ẹ̀)
Dolapo Osinbajo (ọmọ-ọmọ rẹ̀)
Àwọn ọmọSegun Awolowo
Tola Oyediran
Oluwole Awolowo
Ayodele Soyode
Tokunbo Awolowo-Dosunmu
ResidenceÌpínlẹ̀ Ògùn
EducationMethodist Girls' High School
ProfessionOníṣòwò obìrin

Hannah Idowu Dideolu Awolowo (àbísọ Adelana; Ọjọ́ karùndínlọgbọ̀n Oṣù kọkànlá Ọdún 1915 – Ojọ́ ọkàndínlógún Oṣù kẹsán Ọdún 2015), tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí HID,[1]  jẹ́ ọmọ bíbí ìlú kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Ikenne ní ìpínlẹ̀ Ògùn ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó kàwé ní Methodist Girls High School, ní ìlú Èkó.[2] Ó fẹ́ olóṣèlú tí a mọ̀ sí Obafemi Awolowo láti Ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n Oṣù kejìlá Ọdún 1937 di ìgbà tí olóṣèlú náà fi kú ní ọdún 1987. O máa ń pèé ní "Òkúta iyebíye tí kò lẹ́gbẹ́".[3]

HID jẹ́ ògbónta oníṣòwò àti olóṣèlú. Ó kó ipa ribiribi nínú òṣèlú ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. O dúró ti ọkọ rẹ̀ nìgbà àjọṣepọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú NCNC àti AG, tí wọ́n pè ní United Progressive Grand Alliance (UPGA), nígbà tí ó ń ṣẹ̀wọ̀n lọ́wọ́.

Èrò wọn ni wípé kí ó díje fún ìbò náà tí ó bá sì wọlé kí ó sì jẹ́ kí ọkọ rẹ̀ bọ́ sórí àléfà làtàri ìbò tiwantiwa. Kí ó lè di ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ó ń tẹ̀lé ọkọ rẹ̀ kákàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti rọ àwọn ènìyàn kí wọn ó dìbò fún. Ó tún jẹ́ adarí àwọn obìrin ẹ̀gbẹ́ òṣèlú náà tí ó sì maa ń wà ní gbogbo ìpàdé ẹgbẹ́ náà. Gẹ́gbẹ́ bí oníṣòwò, ó jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tí ó máa jẹ́ alábápin ọjà fún Nigerian Tobacco Company (NTC) ní ọdún 1957. Ohun ní ó máa kọ́kọ́ ko aṣo léèsì àti àwọn aṣo míràn bẹ́è wọ Nàìjíríà. Ní Ojọ́ ọkàndínlógún Oṣù kẹsán Ọdún 2015, ó jẹ́ olọ́run nípè lẹ̀yìn tí ó lo ọdún ọ̀kàndínlọgọrún láyé, oṣù mẹ́jì kí ó ṣe ọjọ́ ìbí ọgọ́rún ọdún.[4][5][6] Wọ́n sìnkú rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ̀ ọkọ rẹ̀ ní Ikenne ní Ojọ́ karún Oṣù kẹsán Ọdún 2015.[7]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Oyetimi, Kehinde. "Hannah Idowu Dideolu Awolowo(HID) clocks 95 on Thursday". Archived from the original on 17 December 2013. Retrieved 5 August 2013.  More than one of |accessdate= and |access-date= specified (help)
  2. Musa Odoshimokhe (November 25, 2015). "How Awolowo met, married HID". The Nation. http://thenationonlineng.net/how-awolowo-met-married-hid/. Retrieved June 16, 2016. 
  3. Adeniyi, Tola (1993). The jewel: the biography of Chief (Mrs.) H.I.D. Awolowo. Gemini Press. ISBN 978-978-31953-0-1. 
  4. "Late politician's wife dies at 99". Pulse Nigeria. 19 September 2015. http://pulse.ng/local/hid-awolowo-late-politicians-wife-dies-at-99-id4183795.html. Retrieved 19 September 2015. 
  5. Samuel Awoyinfa. "Mama died in my arms – Tokunbo Awolowo-Dosunmu". Nigeria: The Punch. http://www.punchng.com/news/mama-died-in-my-arms-tokunbo-awolowo-dosunmu/. Retrieved September 22, 2015. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  6. Earnest Nwokolo (September 20, 2015). "H. I. D. AWOLOWO 1915 – 2015 ‘Mama died singing, praying’". the Nation. http://thenationonlineng.net/hid-awolowo-passage-of-a-matriarch-mama-died-singing-praying/. Retrieved September 22, 2015. 
  7. Daud Olatunji (November 27, 2015). "Hannah Idowu Dideolu Awolowo: Buried in grand style". The Vanguard. http://www.vanguardngr.com/2015/11/hannah-idowu-dideolu-awolowo-buried-in-grand-style/. Retrieved December 6, 2015.