Yemi Osinbajo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Yẹmí Òṣínbàjò
Yemi Osinbajo 2017-05-27.jpg
Yẹmí Òṣínbàjò, Vice President of Nigeria, at the 43rd G7 summit
14th Vice President of Nigeria
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
29 May 2015
ÀàrẹMuhammadu Buhari
AsíwájúNamadi Sambo
President of Nigeria
Acting
In office
7 May 2017 – 19 August 2017
AsíwájúMuhammadu Buhari
Arọ́pòMuhammadu Buhari
In office
19 January 2017 – 13 March 2017
AsíwájúMuhammadu Buhari
Arọ́pòMuhammadu Buhari
In office
6 June 2016 – 19 June 2016
AsíwájúMuhammadu Buhari
Arọ́pòMuhammadu Buhari
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Oluyemi Oluleke Osinbajo

8 Oṣù Kẹta 1957 (1957-03-08) (ọmọ ọdún 64)
Lagos, British Nigeria
(now Nigeria)
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAll Progressives Congress
(Àwọn) olólùfẹ́Oludolapo Osinbajo
Àwọn ọmọ3
EducationUniversity of Lagos (LLB)
Nigerian Law School
London School of Economics (LLM)
WebsiteOfficial website

Olúyẹmí Olúlékè Òṣínbàjò (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹjọ oṣù karùn-ún ọdún 1947) jẹ́ òṣèlú àti igbákejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó gorí àléfà fún sáà àkókò pẹ̀lú Ààrẹ Muhammadu Buhari lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2015. Lọ́dún 2019, ó tún wọlé lẹ́ẹ̀kejì gẹ́gẹ́ bí igbákejì Ààrẹ, òun ti Ààrẹ Muhammadu Buhari. Òṣínbàjò jẹ́ agbẹjọ́rọ̀-àgbà (Senior Advocate of Nigeria, SAN).

Igbeyawo, ẹbi ati igbesi aye.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Yemi Osinbajo ni won bi sinu ebi Opeoluwa Osinbajo ni ojo kejo osu keta odun 1957 ni ile iwosan ti Creek ni eko. Osinbajo se igbeyawo pelu Dolapo Osinbajo eni ti orukeo baba re nje Soyode. Dolapo je omo si omo bibi inu oloye Obafemi Awolowo. Won ni awon omo meta-obinrin meji ti oruko won nje Damilola ati Kanyinsola ati okunrin kan ti oruko re nje Fiyinfoluwa Osinbajo.

Eko[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Yemi Osinbajo ko eko ni ile eko alakobere Corona ni eko. Laarin odun 1969 si odun 1975, O lo si koleji Igbobi, Yaba ni eko, orile ede Naijiria nibiti O ti gba ami eye ti ipinle ni odun 1971. O gba ebun ti ile-iwe fun fifo ede geesi ni odun 1972; ebun ti Adeoba fun fifo ede geesi lati odun 1972 titi de odun 1975; ebun Elias fun eni ti ise re darjulo ninu eko itan (History) ninu esi idanwo oniwe mewa (WASC) ti odun 1973; O tun gba ebun ile-iwe giga ti HSC fun eko Litireso ni odun 1975.

Lehinna, O lo keko gboye akoko ni ile eko giga Yunifasiti ti eko laarin odun 1975 si odun 1978. Igbayi ni o keko gba oye oni kilasi keji giga lori imo ofin. Nibi ni O tun ti gba ami eye ti Graham-Douglas fun ofin idokowo (Commercial Law). Ni odun 1979, O pari ikeko amodaju olodun kan ti o kan dandan ni ile eko imo ofin Naijiria nibiti ti won ti gba a lati ma sise gege bi Amofin ati Agbejoro ile ejo giga (Supreme Court) ti ile Naijiria ni odun 1980.

Iṣẹ Ofin.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lati odun 1979 si odun 1980, Osinbajo kopa ninu sinsin orile ede re ti o kan dandan fun odun kan gege bi oga amofin pelu ile ise ti o nri si idagbasoke ati eto Bendel (BDPA) ni Ipinle Bendel.

Ni odun 1981, won gba osinbajo si ise gege bi olukoni ni imo ofin ni ile eko giga Yunifasiti eko, Naijiria. Lati odun 1983 si odun 1986, O je oluko agba lori imo ofin ni Yunifasiti eko. lati odun 1988 si odun 1992, O je onimoran (onimoran ofi ati ejo) si Attorney-Gbogboogbo ati Minisita fun idajo, Bola Ajibola. Osinbajo bere ise olukoni ni omo odun metalelogun.

Lati odun 1997 si odun 1999, won so Osinbajo di ojogbon ninu imo ofin ati olori eka ofin ti gbogbo eniyan ti eka ikeko ofin ni yunifasiti eko. Lati odun 1999 si odun 2007, Osinbajo je omo egbe Igbimo ile ise idajo ti Ipinle Eko. Ni odun 2007 bakanna, won fi Osinbajo je oga alabasepo ti awon alabasepo SimmonsCooper (awon Amofin ati awon Agbejoro) ni naijiria. Osinbajo tun je olukoni agba ni Yunifasiti ti Ipinle Eko. O un tun ni Attorney-Gbogboogbo ati Koomisoanna fun eto Idajo. Lati odun 2007 si odun 2013, Osinbajo tun gba ise gege bi ojogbon onimo ofin ni Yunifasiti Eko.

Iṣẹ Oluso Aguntan[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Yemi Osinbajo ni oluso aguntan ti o nse amojuto ekun ile ijosin ikejidinladota (Olive Tree provincial headquarter) ti ijo irapada ti o wa ni eko.

Igbakeji Aare[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Igba akoko[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Awọn idibo ọdun 2015[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lehin ti won se idasile egbe onigbale (All Progressive Congress) ni odun 2013, won fun Yemi pelu awon olokiki omo ile Naijiria miran ni ise lati se agbekale akosile awon eto ati oun ti egbe tuntun yi ma mulo. eleyi lo yorisi akojopo ti won pe ni "ilana si Naijiria tuntun", eyi ni iwe akosile kan ti egbe oniigbale (All Progressive Congress) kede re gege bi akosile eto ati ise ti egbe yi ma se nigbati won ba yan won si ori alefa. Awon owun pataki ninu ilana yi ni eto ounje ofe fun awon omo ile-iwe, fifi owo ranse pelu gbendeke (conditional cash transfer) si Milionu meedogbon awon alaini julo omo ile Naijiria ti won ba fi oruko omo won sile lati lo ile-iwe ti won si tun gba abere ajesara fun won. Awon oniruru anfani eto si oro aje fun opolopo odo omo Naijiria ni o tun wa.

Ni ojo ketadinlogun odun 2014, oludije fun Aare labe egbe onigbale (All Progressive Congress), ogagun to ti fehinti, Mohammadu Buhari kede Osinbajo gege bi amugbalegbe re ati oludije fun igbakeji Aare fun idibo gbogboogbo ti odun 2015.

Ni ojo kokanlelogbon osu keta odun 2015, ajo ti o nri si eto idibo jerisi yiyan Buhari gege bi eni ti o bori idibo ti Aare. Bayi ni Osinbajo se di igbakeji Aare ti a dibo yan fun orile ede Naijiria. Won bura fun awon mejeeji ni ojo kokandinlogbon osu karun odun 2015. Ni ojo ketadinlogun osu kejo odun 2017, igbakeji Aare Yemi Osinbajo se apejiuwe oro ikorira gege bi eya ipanilaya.

Akoko[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Igbẹhin ti Igbakeji Aare

Yemi Osinbajo dawole ise gege bi igbakeji Aare orile ede Naijiria ni ojo kokandinlogbon osu karun ni gbagede ti Eagle ni Abuja (Eagle Square, Abuja). Ojuse re ni lati bojuto ati royin nipa egbe ti o nrisi eto oro aje ki O si se eto nipa igbani ni iyanju lo si odo Aare, eniti yio mu ipinnu wa gbehin. Gege bi ipinle re ninu imo ofin ati iriri re gege bi koomisoanna fun eto idajo ni ipinle eko fun odun mejo, opo eniyan lero pe yio kopa to joju ninu atunse ti a nilo ninu eto ofin ti orile. Nigbati egbe onigbale (All Progressive Congress) n polongo fun ibo ni odun 2014/15, Yemi Osinbajo se opolopo ipade pelu awon ara ilu yika orile ede ni ilodi si ipolongo gbangba ti opo omo orile ede Naijiria ati awon oloselu won ma nse tele. Okan ninu awon ileri ti O se nigba ipolongo ibo, ti O si tun so laipe yi ni ti eto lati fi ounje ekan lojumo bo omo ile-iwe kan. Yato si funfun omo ile-iwe ni ounje , O ti tenumo laipe pe eto yi yio pese orisirisi ise (ileri ipolongo ibo miran) fun awon ti o ba mu eto yi wa si imuse.

Adele Aare[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Aare Muhammadu Buhari ko akosile ni ojo kesan osu karun odun 2017 si Aare ile igbimo asofin agba ati ti ile igbimo asofin kekere lori ipinnu re lati bere irin ajo fun itoju ailera re. Won ka iwe yi ni ojo kesan osu karun odun 2017 ni ibi apero awon ile mejeeji, ti asofin agba ati ti kekere ni sise ntele. Igbakeji Aare ojogbon Yemi Osinbajo ni won jiroro le so di adele Aare fun akoko ti Aare Buhari yio fi wa ni isinmi nitori ailera re.

Ni ojo keje osu kejo odun 2018, Osinbajo yo oga agba ti o nri si abo ara ilu, Lawal Daura kuro lenu ise fun wiwo ile Asofin ti awon ti o di ihamora ogun pelu iboju lati eka ile ise re wo ni ona ti ko to. Daura ni won ti fi Mathew Seiyefa ropo re.

Akoko Keji[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Awon itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]