Jump to content

Nigerian Law School

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àdàkọ:Infobox law school

Nigerian Law School jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ tí ìjọba gbé kalẹ̀ ní ọdún 1962 fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ́ìmọ̀ Òfin yálà ní ́abẹ́lé ni tàbí fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òkè-òkun ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìmọ̀ òfin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣáájú ọdún 1962 ti ìjọba gbé ilé-ẹ̀kọ́ yi kalẹ̀ ni wọ́n ma ń lọ kọ́ èkọ́ ìmọ̀ òfin ní orílẹ-èdè England tí wọn sì ma ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi amòfin ní ìlú náà .[2]

Àtẹ ẹ̀kọ́ wọn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn ní àwọn ìmọ̀ bíi: ẹjọ́ ọ̀daràn àti ẹjọ́ aráàlú, ẹjọ́ àjọ àti dúkìá, tí ó fi mọ́ oríṣirìṣi ìmọ̀ nípa òfin, yálà nípa abẹ́lé ni tàbí ní ilẹ̀ òkèrè. Iye àwọn tí wọ́n ti kékọ̀ọ̀ jáde nílé èkọ́ yí ti tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin láti ìgbà tì wọ́n ti da sílẹ̀.[1] Ẹnìkéni tí ó bá ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nílé ẹ̀kọ́ fásitì ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni ó ní láti lọ sílé ẹ̀kọ́ òfin ti orílẹ-èdè Nàìjíríà ṣáájú kí ó tó lè siṣẹ́ bí akọ́sẹ́mọṣẹ́ agbẹjọ́rò tàbi amòfin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìgbìmọ̀ tí ó n rí sí ẹ̀kọ̀ ìmọ̀ òfin ní orìlẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọ́n yóò yọ̀nda ìwé́-ẹ̀rì fùn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó bá ti k'ógo já nínú ìdánwò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ti Bar Part II, ìwé-ẹ̀rí yí ni yóò jẹ́ kí wọ́n lè fi ẹ̀kọ́ wọn ṣiṣé jẹun.[3]

Àwọn ibi tí ilé-ẹ̀kọ́ náà wà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé-ẹ̀kọ́ yí tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Èkó ni wọ́n kọ́kọ́ dá sílẹ̀ ní ọdún 1962, tí wọn sì gbe lọ sí àyè tí ó wà nísìnín ní ọdún 1969. Wọ́n tún gbé ẹ̀ka tí ó ń darí ilé-ẹ̀kọ́ yí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ sí Bwari nítòsí ìlú Àbújá ní ọdún 1997.[1] Lásìkò tí wọ́n gbé ilé-ẹ̀kọ́ yí lọ sí Àbújá, kò tíì sí iyàrá ìgbèkọ́ tàbí ilé-ìgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ ní àsìkò yí. Bákan náà ni ìlú Buari yí kò tíì ní iná ẹ̀lẹ́tíríkì, ẹ̀rọ ìpè tàbí ílé-ìfowópamọ́ kankan nígbà náà. [4] Ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin ti Augustine Nnamani Campus ni ó wà ní agbègbè Agbani, ní Ìpínlẹ̀ Enugu. Nígbà tí àyè ilé-ẹ̀kọ́ ìkẹta wà ní Bagauda, ní Ìpínlẹ̀ Kano.[3] Bákan náà ni àwon mìíràn ti kún àwọn tí a ti mẹ́nubà ṣáájú wọ̀nyí tí ó fi mu pé méje. Ìkan wà ní ìlú Yenegoa ní Ìpínlẹ̀ Bayelsa, ìkan wà ní Yola, ìkan wà ní Ìpínlẹ̀ Adamawa nígbà tí ìkan tókù wà ní ìlú Port Harcourt ní Ìpínlẹ̀ Rivers.

Awọn laami-laaka ti on ti jade nibẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]


E tún wo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Portal box

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 "Nigerian Law School Lagos Campus: About Us". Nigerian Law School Lagos Campus. Retrieved 21 November 2009. 
  2. Leesi Ebenezer Mitee (29 March 2008). "Introduction to Nigerian Legal Education". Nigerian Law Resources. Archived from the original on 14 July 2011. Retrieved 21 November 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. 3.0 3.1 "Legal Education". International Centre for Nigerian Law. Archived from the original on 30 March 2010. Retrieved 21 November 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. Tunde Fatunde (13 February 1998). "Law school's mystery flit". Times Higher Education. Retrieved 21 November 2009. 
  5. "Ajulo: Pioneering online legal services for low and mighty". 19 October 2016. https://www.blueprint.ng/ajulo-pioneering-online-legal-services-for-low-and-mighty/. 

Àdàkọ:Authority control

Àdàkọ:Coord missing