Tahir Mamman

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Tahir Mamman

Tahir Mamman in 2023
Minister of Education
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
21 August 2023
ÀàrẹBola Tinubu
Minister of StateYusuf Sununu
AsíwájúAdamu Adamu
Director General of the Nigerian Law School
In office
2005–2013
Arọ́pòOlanrewaju Onadeko
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí7 Oṣù Keje 1954 (1954-07-07) (ọmọ ọdún 69)
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAll Progressives Congress (2014–present)
Education
Occupation
  • Lawyer
  • academic
  • politician

Tahir Mamman SAN tí wọ́n bí ní ọjọ́ keje osù keje ọdún 1954 jẹ́ amòfin , ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó jẹ́ Mínísítà lọ́wọ́lọ́wọ́ fún minister of education of Nigeria. ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni ó jẹ́ adarí àgbà fún Nigerian Law School láti ọdún 2005 sí ọdún 2013. Ó tún fìgbà kan ṣe Gíwá àgbà fún ilé-ẹ̀kọ́ Baze University, tí ó wà ní ìlú Àbújá, ó sì tún jẹ́ ìkan lára ìgbìmọ̀ alákòóso fún àjọ Niger Delta Development Commission (NDDC).[1]

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Bola Tinubu yànán sípò Minisità fún ètò-ẹ̀kọ́ ní ojọ́ kerìndínlógún oṣù kẹjọ ọdún 2023.[2]

Ó jẹ́ ìkan lára àwọn ọmọ egbé amòfin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní ọdún 2010, ó di ìkan lára ìgbìmọ̀ International Association of Law Schools tí ó fìkàlẹ̀ sí ìlú Washington, D.C. Ní inú oṣù kẹsànán ọdún 2015, wọ́n fun ní àmì-ẹ̀yẹ Senior Advocate of Nigeria (SAN), láti fi mọ rírì ipa rẹ̀, ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fi àmì-ẹ̀yẹ Officer of the Order of the Niger (OON) da lọ́lá.

Mamman darapọ̀ mọ́ ìṣèlú ránpẹ́ nígbà tí ó parí sáà rẹ̀ ní ọdún 2014 gẹ́gẹ́ bí adarí àgbà fún ilé-ẹ̀kọ̀ Nigerian Law School. O díje sípò gómìnà Ìpínlẹ̀ Adamawa lábẹ́ àbùradà ẹgbé ìṣèlú APC ní inú oṣù kèjìlá ọdún 2014. Nínú oṣù kẹfà ọdún 2020, ẹgbé APC yànán sípò ìgbákejì adelé ẹgbẹ́ náà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [3][4] Bákan náà ni ó tún jẹ́ olóyè Dan Ruwata ti Adamawa Emirate àti Dokajin Mubi ti Adamawa State.

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Mamman ni ọdún 1954 ní agbègbè MichikaÌpínlẹ̀ Adamawa. Ó ní ìwé-ẹ̀rí LL.B lọ́wọ́ láti ilé-ẹ̀kọ́ Ahmadu Bello University ní ọdún 1983, o sì di amòfin ní ọdún 1984. Ó gba ìwé-ẹ̀rí master's láti ilé-ẹ̀kọ́ University of Warwick ní ìlú England ní ọdún 1987, bákan náà ni ó tún kẹ́kọ̀ọ́ gbà'wé-ẹ̀rí ọ̀mọ̀wé PhD ní ọdún 1990 láti ilé-ẹ̀kọ́ University of Warwick, ní ìlù England.[5]

Iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Mammar bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́ni rẹ̀ nílé-ẹ̀kọ̀ University of Maiduguri ní agbọ̀n ẹ̀ka ẹ̀kọ́ Òfin tí ó sì d'àgbà dì Àdínì (Dean) ti ẹ̀ka ẹ̀kọ́ náà. Ó sì tún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí amòfin ní Ilé-ẹjọ́ ti Ìpínlẹ̀ Adamawa láàrín ọdún 1974 sí ọdún 1984. Ó tún di adarí fún ẹ̀ka ẹ̀kọ common law ní ọdún 1991 nílè ẹ̀kọ́ University of Maiduguri sí ọdún 1997. Bákan náà ni ó tún jẹ́ ìkan lára ọmọ ẹgbẹ́ National Universities Commission àti Local Government Election Tribunal, ní ìpínlẹ̀ nì ọdún 1997. Ó tún jẹ́ àdarí àgbà fún ẹ̀ka ti o ń bójútó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ̀ University of Maiduguri láàrín ọdún1997 sí ọdún 2000. Mammar tún jẹ́ alámọ̀ràn fún ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti ìpìnlẹ̀ Adamawa, ìpìnlẹ̀ Yobe àti ìpínlẹ̀ Borno State laarin ọdun 1999 si ọdun 2000. [6] O tun jẹ ikan lara ọmọ igbimọ amofin, Council of legal education, Nigerian Bar Association, Nigerian Association Of Law Teacher, Commonwealth Legal Education Association, Centre for Computer Assisted Legal Instruction USA, national association of vice chancellors of Nigeria, United Kingdom Centre for Legal Education, African Network of Constitutional Lawyers, International Bar Association, Body of senior advocates of Nigeria (BOSAN) àti member Governing Board of International Association of Law School Washington DC lati ọdún 2011 sí ọdún 2013.[7]

Àwọn ìwé tí ó ti kọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • The law and politics of constitution-making in Nigeria, 1862–1989 issues, interests and compromises. Maiduguri, ed; Ed-Linform Services, Tahir Mamman, con; Heaney N, Mamman M, Tahir H, Al-Gharib A. Lin C. 1998 Nigeria Constitutional law, ISBN 978314961X, 9789783149618, Àdàkọ:OCLC Unique ID: 7493122309
  • The law and politics of constitution making in Nigeria, 1900–1989 issues, interests and compromises. 1991, Ph.D, University of Warwick, Law Politics and political science. Tahir Mamman, Academic theses, Àdàkọ:OCLC

Àwon ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Habibie, Pejman; Burgess, Sally (2021), "Scholarly Publication, Early-Career Scholars, and Reflectivity", Scholarly Publication Trajectories of Early-career Scholars, Cham: Springer International Publishing, pp. 1–19, ISBN 978-3-030-85783-7, retrieved 2023-08-25 
  2. "TAHIR MAMMAN: RIGHT MAN, RIGHT JOB - THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-08-25. 
  3. "Baze University Abuja". bazeuniversity.edu.ng. Retrieved 6 October 2020. 
  4. Okeke, Chidimma C. (25 March 2020). "Baze University adopts virtual learning". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 6 October 2020. 
  5. Kwache, Emmanuel Y. (24 August 2013). "Dr. Tahir Mamman as a distinct administrator". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 6 October 2020. 
  6. "Prof. Tahir Mamman, SAN". J-K Gadzama LLP (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 6 October 2020. 
  7. Oladipo, Bimpe (14 January 2019). "MAMMAN, Prof Tahir, OON, SAN". Biographical Legacy and Research Foundation (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 6 October 2020. 

Àdàkọ:Authority control