Ilé-ẹjọ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
A trial at the Old Bailey in London as drawn by Thomas Rowlandson and Augustus Pugin for Ackermann's Microcosm of London (1808–11).
The International Court of Justice.

Ilé-ẹjọ́ ni ibi tí ìjọba gbé kalẹ̀ tí wọ́n sì fi àṣẹ si wípé kí ìgbẹ́jọ́ ati ìdájọ́ èyíkéyí tí ó bá láìẹ̀ hù láàrín àwùjọ ó ti ma wáyé pẹ̀lú ìlànà òfin ìjọba orílẹ̀-èdè náà.[1] Àti ìbú àti òró ètò ìdájọ́ orílẹ̀-èdè kan, Ilé-ẹjọ́ ni ibi tí adájọ́ ti ma ń fi ẹsẹ̀ òfin ṣe ìgbẹ́jọ́, ìdájọ́ àti ìpẹ̀tù-s'ááwọ̀ láàrín àwọn ènìyàn, ìlú tàbí ilé-iṣẹ́ méjì tí ìjà , tàbí fàá-kája bá ti ń wáyé nígbà tí wọ́n bá gbé ẹjọ́ wọn wá sile ẹjọ́. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá f'ẹ̀sùn kàn nílé ẹjọ́ ní ànfaní láti gba agbẹjọ́rò tí yóò jẹ́ agbẹnusọ fun níwájú adájọ́

Àṣẹ ìgbẹ́jọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àṣẹ ìgbẹ́jọ́ ni a lè pè ní àṣẹ ati agbara tí ilé-ẹjọ́ tàbí adájọ́ ní láti gbé ìdájọ́ kalẹ̀ ní ọ̀nà tí ó bá òfin mu nínú ìlú ati orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà.[2] Njẹ́ ilé-ẹjọ́ tàbí adájọ́ ní ẹ̀tọ́ láti gbọ́ ẹjọ́ tí wọ́n bá gbé wá sí iwájú wọn jẹ́ ìbéèrè kan pàtàkì tí ó yá kí ènìyàn ó bèrè.[3] Oríṣi ìdájọ́ mẹ́ta ló wà, akọ́kọ́ ni ìdájọ́ lórí ènìyàn, èyí ni ìdájọ́ lórí ohun tí ó jọ mọ́ ènìyàn ati ohun ìní wọn. Ikejì ni ìdájọ́ lórí ìṣélẹ̀, èyí ni kí wọ́n gbé Ìdájọ́ kalẹ̀ l'órí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ, ìkẹta ni ìdájọ́ ilẹ̀nàti ààlà-ilẹ̀. [3] Àwọn ìdájọ́ mìíràn tí ó tún wà ni ìdájọ́ gbogbo-gbò, ìdájọ́ àdágbọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. [3]

Àwọn itọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Walker, David (1980). The Oxford Companion to Law. Oxford: Oxford University Press. p. 301. ISBN 0-19-866110-X. https://archive.org/details/oxfordcompaniont0000walk. 
  2. Inc., US Legal. "Jurisdiction – Civil Procedure". Civilprocedure.uslegal.com. Retrieved 23 December 2017. 
  3. 3.0 3.1 3.2 Jurisdiction, Legal Information Institute, Cornell Law School.