Jump to content

Unity Party of Nigeria

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Unity Party of Nigeria
Ìdásílẹ̀1978 (1978)
ÌtúkáUnknown
IbùjúkòóIbadan
Ọ̀rọ̀àbáSocial democracy
Democratic socialism
Awoism
Ipò olóṣèlúCentre-left
Ìṣèlú ilẹ̀ Nigeria

Unity Party of Nigeria (UPN) ló ti fìgbà kan jẹ́ ẹgbẹ òṣèlú ilẹ̀ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ tó lààmì laaka ní àpá ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà lásìkò ìjọba àwa-arawa ẹlẹ́kejì  (second republic) ní ọdún 1978-1983. Ẹgbẹ́ òṣèlú náà ló dá lórí ipò aṣáájú ológbèé Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, ẹni tí ó ti fìgbà kan jẹ́ ìlú-mọ̀ọ́ka olóṣèlú ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó sì ti dípò ìṣèjọba mú rí lásìkò rẹ̀. Àmọ́, ànìyàn ẹgbẹ́ òṣèlú náà ló dá lórí ìṣèjọba àwùjọ àwa-arawa ló mú yàtọ̀ sí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tó kù. Ẹgbẹ́ UPN jogún ìmọ̀ wọn láti ẹgbẹ́ òṣèlú àtijọ́ tẹ́lẹ̀ tí  Action Group tí ó sì jẹ́ kí ó di ẹgbẹ́ òṣèlú fún gbogbo àwùjọ́. Òun ló jẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó ṣe ìgbé-lárugẹ fún ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Àríwòye ìjọ́ba ológun tí ọ̀gágun Ólúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ ni kí ó dá ẹgbẹ́ òṣèlú tí yóò mú ẹlẹ́yà-mẹyà kúrò lágbo òṣèlú ilẹ̀ Nàìjíríà lásìkò ìjọba àwa-arawa ẹlẹ́kejì. Ẹgbẹ́ òṣèlú UPN àti People's Redemption Party (PRP) ni wọ́n mú àbá tó dára jùlọ nípa dídìbò yàn tí ọdún 1979. 

Ẹgbẹ́ òṣèlú Action Congress of Nigeria ni wọ́n gbà wípé ó jẹ́ àrólé fún ìdàpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú méjèjì yìí: AG ati UPN.

Àwọn àríwòye ẹgbẹ́ náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Ẹgbẹ́ náà fara mọ́ kí wọ́n ma gba owó tí ó tó ìdá 30-40% láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀, ìdá 40-50% fún àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ tàbí ìdá 10% fún àwọn ìjọba ìbílẹ̀, lórí àrìyàn-jiyàn tó dá lórí ọ̀nà ìgbowó wọlé sápò ìjọba ilẹ̀ Nàìjíríà.
  • Ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ fún gbogbo gbò
  • Ètò ìwòsàn ọ̀fẹ́ fún gbogbo gbò
  • Ètò ìgbanisíṣẹ́
  • Ètò ìdàgbà sókè ìgbèríko
  • Ètò àkanṣe fún ìdàgbà sókè ilé-ẹ̀kọ́ àti àwọn ọ̀nà gbogbo
  • Ètò ìṣàtúnṣe sí òfin fún ìdásílẹ̀ àwọn ìjọba ìpínlẹ̀.

Àwọn ìtọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Larry Diamond, Cleavage, Conflict, and Anxiety in the Second Nigerian Republic, The Journal of Modern African Studies > Vol. 20, No. 4 Dec., 1982
  • C. S. Whitaker, Jr, Second Beginnings: The New Political Framework, Issue: A Journal of Opinion > Vol. 11, No. 1/2 (Spring, 1981)
  • Rotimi T. Suberu, The Struggle for New States in Nigeria, 1976-1990, African Affairs > Vol. 90, No. 361 (Oct., 1991), pp. 499–522