Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Obafemi Awolowo
Awolowo-Obafemi.JPG
Olórí Agbègbè Apáìwọ̀òrùn Nàìjíríà
In office
Ọjọ́ kínín Oṣù kẹwá ọdún 1954 – Ọjọ́ kínín Oṣù kẹwá ọdún 1960
Arọ́pòSamuel Akintola
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbíỌjọ́ kẹfà oṣù kẹta ọdún1909
Ikenne, Ipinle Ogun
AláìsíMay 9, 1987(1987-05-09) (ọmọ ọdún 77)
Ikenne
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAction Group
Professionamòfin

Jeremiah Obáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ (6 oṣù kẹta ọdún 1909 - 9 oṣù karún ọdún 1987), jẹ́ olósèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ẹ̀yà Yorùbá. Awólọ̀wọ̀ jẹ́ olórí fún àwon ọmọ ilẹ̀ Yorùbá àti ọ̀kan nínú àwọn olóṣèlú pàtàkì ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1][2][3]

Ìgbà èwe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Obafemi Awolowo

A bí ni ọjọ́ kẹfà osù kẹta ọdún 1909 ni Ìkẹ́nnẹ́ tó wà ní ìpínlẹ̀ Ogun lóòní. Omo àgbẹ̀ tí ó fi iṣẹ́ àti ògùn ìsẹ́ ṣọ ara rẹ̀ di ọ̀mọ̀wé, Awólọ́wọ̀ lọ ilé ẹ̀kọ́ Anglican àti Methodìst ni Ikénne àti ni Baptist Boys' High School ni Abéòkúta.[4] Lèyìn rè ó ló sí Wesley College ni Ibàdàn tí ó fi ìgbà kan jé olùìlú Agbègbè Apáìwọ̀òrùn Nàìjíríà láti ba di Olùko. Ní ọdún 1934 , ó di olùtajà àti oníròyìn. O se olùdarí àti alákóso Egbé Olùtajà Awon Omo Nàìjíríà (Nigerian Produce Traders Association) àti àkòwé gbogbogbo Egbé Awon Awako Igb'eru Omo Ilè Nàìjíríà (Nigerian Motor Transport Union). [2]

Awólówó tèsíwájú nínú èkó rè, ó sí gbà ìwé erí kékeré ni ọdún 1939, kí ó tó ló láti gbà ìwé erí èkó gíga nínú ìmò owó ni ọdún 1944. Igbà yí nà ló tún jé olóòtú fún ìwé ìròyìn Nigerian Workers (Osisé Omo Ilè Nàìjíríà). Ní ọdún 1940 ó di àkòwé Egbé Odò Awon Omo Ilè Nàìjíríà (Nigerian Youth Movement) èka Ibàdàn, ibi ipò yí ni ó tí s'olori ìtiraka láti se àtúnse Igbìmọ́ Aláse Idámòràn Fún Awon Omo Ibàdàn (Ibàdàn Native Authority Advisory Board) ni ọdún 1942.

Ìṣèlú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹ̀nu ọ̀nàn ilé Obafemi Awolowo

Ni ọdún 1944 o lo si ilu Londonu lati ko eko ninu imo ofin be ni o si se idasile Egbe Omo Oduduwa. Leyin igba to pari eko re ni ọdún 1947 o dari pada wale lati wa di agbejoro ati akowe agba fun Omo Egbe Oduduwa. Leyi ọdún meji, Awolowo ati awon asiwaju Yoruba yioku se idasile egbe oselu Action Group eyi ti o bori ninu ibo ọdún 1951 ni Agbegbe Iwo Oorun Ile Naijiria. Larin ọdún 1951-54 Awolowo je Alakoso Fun Ise Ijoba ati Ijoba Ibile, o si di Olori Ijoba Agbegbe Iwo Oorun Ile Naijiria ni ọdún 1954 leyin atunko Iwe Igbepapo Ati Ofin (constitution).Gege bi Olori Ijoba Agbegbe Iwo Oorun Ile Naijiria, Awolowo se idasile eko ofe fun gbogbo odo lati ri pe moko moka gba le ka.

Jagídíjàgan ní apá ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé ọnà Obafemi Awolowo

Nígbà tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà di olóm̀inira ní ọjọ́ kìnní oṣù kẹ́wàá ọdún 1960, Awólọ́wọ̀ di Olórí ẹgbẹ́ Alátakò (Opposition Leader) sí ìjọba Abubakar Tafawa Balewa àti Ààrẹ Nnamdi AzikiweÌlú Èkó. Àìṣọ̀kan tó wà láàrín òun àti Samuel Ládòkè Akíntọ́lá tó dipò rẹ̀ gẹ́gẹ́́ bí fìdí hẹẹ́ Olórí Ìjọba ní Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn mú ni ó dá fàá ká ja tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1962. Ní oṣù kọkànlá ọdún yí, Ìjọba Àpap̀ọ ilẹ̀ Nàìjíríà fi ẹ̀sùn kan Awólọ́wọ̀ wípé ó dìtẹ̀ láti dojú ìjọba bolẹ̀. Lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ ó tó oṣù mọ́kànlá, ilé-ẹjọ́ dá Awólọ́wọ̀ àti àwọn ọmọ ẹ̀gbẹ́ òṣ̀èlú rẹ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n (èjìlẹ̀wá sẹ́jọ) lébi èsùn ìdìtẹ̀, wọ́n sì rán wọn lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá. ọdún mẹ́ta péré ni ó lò ní ẹ̀wọ̀n ní ìlú Calabar tí ìjọba ológun Yakubu Gowon fi da sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ta oṣù kẹ́jọ ọdún 1966. Lẹ́yìn èyí Awólọ́wọ̀ di Alákòóso Ìjọba Àpapọ̀ fún Ọrọ Okòwò. Ní ọdún 1979 Awólọ́wọ̀ dá ẹgbẹ́ òṣèlú kan Ẹgbẹ́ Òṣèlú Ìmọ́lẹ̀ sílẹ̀.

Aláìsí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ṣaláìsí ní ọjọ́ àìkú ọjọ́ kẹsàn oṣù kárùún ọdún 1987 ní ìlú Ìkẹnẹ́. Lẹ́yìn ikú Awólọ́wọ̀ Ìjọba Àpapọ̀ yí orúkọ Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Ilé-Ifẹ̀ padà sí Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwòrán rẹ̀ wà lórí owó Ọgọ́rùún náị́rà fún ìṣẹ̀yẹ gbogbo ohun tó ṣe fún ìdàgbàsókè ilẹ̀ Yorùbá àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀.

Àwọn ìwé tó kọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Awo on the Civil War; Memoir, 1981
  • voice of Courage: Selected Speeches of Chief Obafemi Awolowo; Collection of Speeches, 1981
  • Voice of Reason: Selected Speeches of Chief Obafemi Awolowo; Collection of Speeches, 1981
  • Thoughts on the Nigerian Constitution; Ideological Text, Oxford University Press, 1968

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]