Èkó

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Lagos
Èkó

Àsìá

Seal
Map of Lagos Metropolis
Lagos is located in Nigeria
Lagos
Ibudo Eko ni Naijiria
Àwọn ajọfọ̀nàkò: 6°27′11″N 3°23′45″E / 6.45306°N 3.39583°E / 6.45306; 3.39583
Country  Nigeria
State Lagos State
LGA Lagos Island
Ààlà [1]
 - Urban 999.6 km2 (385.9 sq mi)
Olùgbé (2006 census, preliminary)[2]
 Ìṣúpọ̀ olùgbé 7,941/km2 (20,569.9/sq mi)
 Urban 7,937,932
Àkókò ilẹ̀àmùrè CET (UTC+1)
Ibiìtakùn http://www.lagosstate.gov.ng/

Ilu Èkó tabi Lagos je ilu to tobijulo ni orile-ede Naijiria. Ilu Eko fi igbakan je oluilu Naijiria.

Èkó ni orúko ti awon Yorubá npe ìlú erékùsù ti o ti di olú ìlú ati ibùjoko Ijoba gbogbo-gbòò fun ilè Naijiria ni ojó òní. Ìlú Yoruba ni, ṣugbọ́n orúkọ ti awọn enia agbaiye fi npè é ni eyi ti awọn Òyìnbó Potogi ti o kọ́ bẹ etíkun ilẹ̀ Yoruba wò fun un. Orúkọ náà ni “Lagos”, eyi ti ìtumọ rẹ̀ jasi “adágún” tabi “ọ̀sà”, nitoripe ọ̀sà ni o yi ilu náà ka...

Awon Eya Yoruba ti Awori ni o koko tedo si agbegbe Ilu Eko, labe isakoso ati Itona olori-i won, Olofin, awon Awori koko tedo si erekusu Iddo, lehin igba naa ni won bere si ni wonu-u awon agbegbe yoku Eko lati tedo. Ni senturi k'arun din l'ogun {15th Century}, Ilu Eko, bo si abe isakoso Ijoba Bini. Igba naa ni awon ologun Ilu naa so agbegbe ilu naa ni Eko, eleyii, ti o tumo si [Ibi ti awon Ologun ti n simi} Ni ede Edo/Bini. Gbogbo eleyii sele labe olori awon Bini ni igba naa- Oba Orogba. Leyin ti eyi sele,ni Ijoba Bini fi Baale je oye, lati maa M'ojuto/Se Akoso, ati Gbigba Isakole {Tribute} ilu naa bii agbegbe labe-e Ijoba nla ti Bini. Oba Yoruba akoko ti Ilu Eko je, ni Oba Asipa. Ni odun-un 1472, awon Oyibo Potoki{Portuguese} de si ile Eko, awon Potoki naa ni Oyinbo akoko, ti o maa de Ile -Eko lati Erekusu Orile-ede Yuropu ni igba naa....Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Summing the 16 LGAs making up Metropolitan Lagos (Agege, Ajeromi-Ifelodun, Alimosho, Amuwo-Odofin, Apapa, Eti-Osa, Ifako-Ijaiye, Ikeja, Kosofe, Lagos Island, Lagos Mainland, Mushin, Ojo, Oshodi-Isolo, Shomolu, Surulere) as per:
    The Nigeria Congress. "Administrative Levels - Lagos State". http://www.nigeriacongress.org/FGN/administrative/statedetails.asp?state=lagos. Retrieved 2007-06-29. 
  2. Summing the 16 LGAs making up Metropolitan Lagos (Agege, Ajeromi-Ifelodun, Alimosho, Amuwo-Odofin, Apapa, Eti-Osa, Ifako-Ijaiye, Ikeja, Kosofe, Lagos Island, Lagos Mainland, Mushin, Ojo, Oshodi-Isolo, Shomolu, Surulere) as per:
    Federal Republic of Nigeria Official Gazette (15 May 2007). "Legal Notice on Publication of the Details of the Breakdown of the National and State Provisional Totals 2006 Census" (PDF). http://www.nigerianstat.gov.ng/Connections/Pop2006.pdf. Retrieved 2007-06-29. 
  • J.F. Odunjo (1969), ÌLÚ ÈKÓ ATI ÌJÈBÚ, Isẹ́ Àtúnyèwò ẹ̀kọ́ nipa ọ̀rọ̀ gbígbàsọ Ojú-ìwé 49-54, Eko Ijinle Yoruba Alawiye, Fun Awon Ile Eko Giga, Apa Keji, Longmans of Nigeria.

Awon ile isimi towa Leko(Lagos Hotels).