Lagos Island

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Ìsàlẹ̀ Èkó (Lagos Island) jẹ́ àárín gbùngbùn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ (local government areaLagos), ìpínlẹ Èkó (Lagos State). Ó jẹ́ ọ̀kan lára ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n pín ìpínlẹ̀ Èkó sí (Lagos Division). Nínú ètò ìkànìyàn tó wáyé ní ọdún 2006 nílẹ̀ Nàìjíríà, ìjọba ìbílẹ̀ náà (LGA) ni ìwọ̀n  èrò tó pọ̀ tó 209,437 ní agbègbè tí kò ju ìwọ̀n ibùsọ̀ 8.7 km². Ìjọba ìbílẹ̀ Ìsàlẹ̀ Èkó ló kó ìlàjì nínú apá ìwò Oòrùn Lagos Island, nígbà tí apá ìlà Oòrùn Ìsàlẹ̀ Èkó tókù wà ní  abẹ́ àkóso ìjọba ìbílẹ̀ Etí-Ọ̀sà.

Àpèjúwe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìsàlẹ̀ Èkó yìí ló sún mọ́ afonífojì ìyẹn: Lagos Lagoon, níbi tí ó láàbò jùlọ ní erékùṣù ilè-Adúláwọ̀ (Africa), afonífojì yìí ni ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Yoruba kan tí wọ́n ń ṣiṣé ẹja pípa ní abúlé Èkó, agbègbè yìí náà ló di ìlú tun-tun tí tẹrú-tọmọ ti ń wá jíjẹ-mímu wọn lónìí tí ó sì ti tàn tí ó fi dé àwọn agbègbè tó wà ní ìtòsí rẹ̀ káà kiri tí tí dé mainland.

Ìsàlẹ̀ Èkó (Lagos Island) ni ó já pọ̀ mọ́ mainland ní ọ̀nà mẹ́ta pẹ̀lú àwọn afárá méta (1st-3rd mailand bridge) tí ó tóbi tó nà kọjá lórí afonífojì Èkó tí ó fi dé Èbúté Mẹ́ta. Bákan náà ni ó tún já pọ̀ mọ́ agbègbè tí ó sún mọ bíi: Ìkòyí sí  Victoria Island, tó fi dé ibùdókò ọkọ̀ ojú-omi ti Àpápá tí ó dajú kọ apá ìwọ̀ Oòrùn erékùṣù náà, tí ó sì jẹ́ ibùdó ìpatẹ ọjà láàrín ìgboro Èkó, nígbà tí ó jé pé Ìsàlẹ̀ Èkó ní ilé ìṣèjọba, ọjà ìpàtẹ àti àwọn ọfíísì lóríśi ríśi ìjọba ìbílẹ̀ náà wà .Bákan náà ni ilé ìjọ Catholic, ìjọ Àgùdà (Anglican Cathedrals) bẹ́ẹ̀ náà sì ni mọ́sálásí ńlá wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

Nínún ìtàn, Ìsàlẹ̀ Èkó jẹ́ ilé ìgbé fún àwọn ọmọ ilè Nàj̀íríà tí wọ́n bọ́ lóko ẹ̀rú láti ilẹ̀ Brazil ma ń dé sí láti forí pamọ́ sí. Ọ̀pọ̀ ẹbí ni ó ń gbé ní ibùgbé tí wọ́n ń pè ní Broad Street ní Marina.

Detailed map of Lagos Island

Apá àríwá ìsàlẸ̀ Èkó ni ọ̀pọ̀ ilé òun ọjà ti kò gbòòrò wà tí ó sì ma ń sábà kún fọ́fọ́ fún èrò tí ẹsẹ̀ kò sì gbèrò níbẹ̀. Ìjọba ti ń gbìyànjú láti kó àwọn ọ̀nà tún tún síbẹ̀ lóna  àti lè mú àdínkù bá súnkẹrẹ fàkẹre ojú pópó náà kí ọkọ̀ lè ma lọ gaaraga. Ó tún jẹ́ apá ibi tí Ọba Èkó ń gbé (king of Lagos). Bákan náà ni ó jẹ́ ìgbàgbọ́ pé apá agbègbè yìí nìkan ni ọdún Ẹ̀yọ̀ ti lè wáyé ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Ètò ọrọ̀ ajé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀pò ilé  ìfowó-pamọ́ ni ó ní olú ilé-iṣẹ́ wọn ní Ìsàlẹ̀ Èkó, ní èyí tí ilé ìfowó-pamọ́ First Bank of Nigeria jẹ́ ọ̀kan lára wọn tí ó ní olú ilé-iṣé rẹ̀ ní Marina. Ilé ìfowó-pamọ́ mìíràn tí ó tún ní olú ilé-iṣẹ́ níbẹ̀ ni ilé ìfowó-pamọ́ UBA (United Bank for Africa). Àwọn ilé iṣẹ́ ńlá ńlá àti kéréje kéréje mìíràn tí wọ́n wà níbẹ̀ ni : ilé-iṣẹ́ tí ó ń pèsè ohun ìfaná (electrical appliances manufacturers), ilé iṣé tí ó ń bani ralé àti báni kọ́lé (real estate consultancy firms), àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ló wà nísàlẹ̀ Èkó.

Àwọn Ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìjápọ̀ ìta[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]