Ilé-Ifẹ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Ilé-Ifẹ̀
—  Ìlú  —
Ilé-Ifẹ̀ is located in Nigeria
Ilé-Ifẹ̀
Àwọn ajọfọ̀nàkò: 7°28′N 4°34′E / 7.467°N 4.567°E / 7.467; 4.567
Orílẹ̀-èdè

Ilé-Ifẹ̀ je ilu ni Naijiria

ILÉ -IFÈ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. Ilé Ifè, Ifèe tèmi
 2. Ilé Ifè, ìlú àwon akoni
 3. Ibùgbé àwon ènìyàn jànkàn
 4. Ibi ìfisolè oríi Yoòbá
 5. Àbí béè kó, bí mo puró, e só 5
 6. Ibè nilé Àdìmúlà Oòni Ifè
 7. Àjàláyé Olófin Oòduà
 8. Òrànmíyàn oba aláyé lu jára
 9. Morèmi òngbà tíí gbará àdúgbò
 10. Èlà Ìwòrì, ikò àjàlórun 10
 11. Òrìsà bàmùtàtà bàmùtata tá a fi rómo èdá padà
 12. Ilé Ifè, ìlú àwon olùdá ayé
 13. Ifè, ìlú àwon àtòrunbò
 14. Ifè ni wón gbé gbolúbi dúdú, funfun
 15. Ìyín lèèyàn òòsà pàápàá forí rìn dé 15
 16. Njé ìwo Ifè oòyè dabò, olórí ayé gbogbo
 17. Mo rántí bíyàà mi àgbà se mó-on ń fi ó korin
 18. Létí odò èsìnmìrìn
 19. N kò rí o rí ká so pàtó
 20. Sùgbón mo ríyà tó o je lóríi wa 20
 21. Ojúù mi kò sàìtéjèè re
 22. Èjè tó o ta sílè fún wa
 23. Èjè tó towó ìyà wá
 24. Ìyà tó towó ìsé wá
 25. Ìsé tó towó ègbin ròólè 25
 26. Nígbà tómo tá a bí dé
 27. Wáá fowó orò júweelée baba è
 28. Tí funfun dé wáá kó o lérú
 29. Tó kó e tomo tòòsà
 30. Ògòrò òòsàa wa la fi sàféèrí 30
 31. Tá a firúnmolè sàwátì
 32. Òsùpá Ìjió ti lo tèfètèfè
 33. Ilé-Ifè, njé so fún mi, Ifè oòyè dabò
 34. Séwo náà làwon alára bátabàta se báyìí se?
 35. Tí wón dójú tì ó, tí wón kégbin bá
 36. o láa 35
 37. Njé kí la ó ti sòròò won sí, ìwo Ifè?
 38. Ká sáà fi wón sílè máa wòye
 39. Ká fòrò fúnrúnmolè
 40. Ká fáwon igbámolè lórò so
 41. Ká fòrò sebo ká fi sètùtù 40
 42. Kóhun rere tún lè padà sílé ifè
 43. Ení bá ní kébo má dà
 44. Kó máa bébo lo réré ayé.


Àwọn Akóìjánupọ̀: 7°28′N 4°34′E / 7.467°N 4.567°E / 7.467; 4.567