Jump to content

Samuel Ladoke Akintola

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Samuel Ladoke Akintola
Premier of Western Nigeria
In office
October 1, 1960 – January 15, 1966
AsíwájúObafemi Awolowo
Arọ́pòNone
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbíOṣù Keje 6, 1906(1906-07-06)
Ogbomosho, Nigeria
AláìsíOṣù Kínní 15, 1966 (ọmọ ọdún 55)
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAction Group
OccupationLawyer

Samuel Ladoke Akintola (July 6, 1906 - January 15, 1966) je oloselu omo orile ede Naijiria lati eya Yoruba ni apa ila oorun. A bi ni ojo kefa osu keje odun 1906 ni ilu Ogbomosho.

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Sámúẹ̀lì sínú ìdílé Akíntọ̀lá ní ìlú Ògbómọ̀ṣọ́, bàbá rẹ̀ ni Akíntọ̀lá Akínbọ́lá nígba tí ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Àkànkẹ́ Akíntọ̀lá. Bàbá rẹ̀ jẹ́ oníṣòwò tí ó jáde wá láti inú ẹbí oníṣòwò.[1] Nígbà tí ó kéré jọjọ, àwọn ẹbí rẹ̀ kó lọ sí ìlú Minna tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Naija lónìí. Ó kàwé léréfèé nílé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ́rẹ̀ Church Missionary Society. Ní ọdún 1922, ó padà wá sí Ògbómọ̀ṣọ́ láti wá bá bàbá bàbá rẹ̀ gbé tí ó tún tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Oníyẹ̀tọmi ṣáájú kí ó tún tó tẹ̀ síwájú ní ilé-ẹ̀kọ́ Kọlẹ́ẹ̀jì ti onítẹ̀bọmi ní ọdún 1925. Ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ Akádẹmì Onítẹ̀bọmi láàrín ọdún 1930 sí 1942, lẹ́yìn èyí ni ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ àjọ tó mójú tó ìrìnà Rélùwéè ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Lásìkò yí, ó ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú H.O. Davies, tí ó jẹ́ agbẹjọ́rò àti olóṣèlú, ó tún dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú Nigerian Youth Movement níbi tí ó ti ṣàtìlẹyìn fún Ikoli láti di ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tó ń ṣojú Ìpínlẹ̀ Èkò tako yíyàn tí wọ́n yan Samuel Akisanya, ẹni tí Nnamdi Azikiwe fara mọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò dépò náà. Akíntọ́lá tún dara pọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ ìwé ìròyìn gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́, tí ó sì di olóòtú fún.iwé ìròyìn náà ní ọdún 1953 pẹ̀lú àtìlẹyìn Akinọlá Májà tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olówó ìwé-ìròyìn náà tí ó sì rọ́pò Ernest Ikoli gẹ́gẹ́ olóòtú. Akíntọ̀lá náà sì dá Ìwé-ìròyìn Yorùbá tí wọ́n ń fi èdè Yorùbá gbé kalẹ̀ ní ojojúmọ́. Ní ọdún 1945, ó tako ìgbésẹ̀ ìdaṣẹ́ sílẹ̀ tí ẹ́gbẹ́ òṣèlú NCNC tí Azikiwe àti Michael Imoudu, fẹ́ gùn lé, èyí sì mu kí ó di ọ̀dàlẹ̀ lójú àwọn olóṣèlú bíi Anthony Enahoro.[1] Ní ọdún 1946, Akíntọ̀lá rí ìrànwọ́ ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ gbà láti kàwé ọ̀fẹ́ ní U.K, níbi tí ó ti parí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa ìmọ̀ òfin, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò lórí òfin tí ó jẹ mọ́ ìlú. Ní ọdún 1952, òun àti Chris Ògúnbanjọ,olóyè Bọ̀dé Thomas àti Michael Ọdẹ́sànyà kóra jọ pọ̀ di ọ̀kan.Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 ""Akintola: Remembering a controversial politician"". The Nation Online. Retrieved 18 January 2016.