Ògbómọ̀ṣọ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Ògbómọ̀ṣọ́
—  Ilu  —
Ilu Ogbomoso lati oju satellite
Ògbómọ̀ṣọ́ is located in Nigeria
Ògbómọ̀ṣọ́
Àwọn ajọfọ̀nàkò: 8°08′N 4°15′E / 8.133°N 4.25°E / 8.133; 4.25
Orílẹ̀-èdè  Nigeria
Ipinle Oyo
Agbegbe Ijoba Ibile Ogbomoso

Ògbómọ̀ṣọ́ je ilu ni Ipinle Oyo ni Naijiria.

ÌTÀN SÓKÍ LÓRÍ ÌLÚ MI ÒGBÓMÒSÓ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ogunlolá je ode, ògbótari, tí ó mòn nípa ode síse ó féràn láti máa lo sísé Ode nínú igbó ti a máa ni ìlú Ògbómòsó tí à pè ní igbó ìgbàlè, sùgbón okòrin yii ti o je ogunlolá se Baale àdúgbò tí ó Ogunlolá gbé nígbà nàá. Baale o ríi wí pe Ogunlolá gbé àdùtú àrokò náà lo sí òdò Aláàfin. Aláàfín àti àwon emèwà rè yìí àrokò náà títí, wón sì mò ó tì. Pèlú líhàhílo, ìfòyà, aibale okàn nípa OGUN ÒGBÒRÒ tí ń be ló de Òyó, kò mú won se ohunkóhun lórí òrò Ogunlolá, wón si fi í pamó si ilé olósì títí won yóò fi ri ìtumò sí àrokò náà. Ní ojó kan, Ogunlolá ń se ode nínú igbó ìgbàlè-àdúgbò i bi tí Gbòngàn ìlú ògbímòsó wà lonìí. Igbó yìí, igbó kìjikìji ni, ó sòro dojúkò kí jé pé ode ní ènìyàn, kó dà títí di ìgbà tí ojú tí là sí i bí odun 1935, èrù jéjé l’o tún jé fún òpòlopò omo ìlú láti wò ó ńitorí wí pé onírúurú àwon enranko búburú l’ó kún ibè. Àní ni odún 1959, ikooko já wo Ile Ògúnjé ńlé ni ìsàlè-Àfón gégé bi ìròyìn, ikooko já náà jáde láti inú igbó ìgbàlè yìí ni àwon ALÁGÒ (àwon Baálè tí wón ti kú je rí ní ògbómòsó, tí wón sì jé elesin-ìbílè) máà ń gbé jáde nígbà tí oba àti àwon omo rè bá ń se odun ÒLÈLÈ. Láti pa á mó gégé bi òpe títí di òní, nínú Gbòngàn Ògbómòsó ní àwon Alágà náà ń ti jáde níwòn ìfbà tí ó jé wí pé ara àwon igbí ìgbàlè náà ní ó jé. Ogunlolá kó tí í tin jìnnà láti ìdí igi Àjàbon (ó wá di òní) tí ó fi ń ri èéfín. Èéfín yìí jé ohun tí ó yá à lénu nítorí kò mò wí pé iru nnkan béè wà ní itòsí rè Ogunlolá pinnu láti to pasè èéfín náà ká má bá òpò lo sílé Olórò, àwon ògbójú ode náà rí ara won, inú swon sí dùn wí pé àwon je pàdé. Oruko àwon tí wón je pàdé awa won náà ní:- AALE, OHUNSILE àti ORISATOLU. Lèyìn tí won ri ara won tan, ti won si mo ara won; wón gbìdánwò láti mo ibi tí Olukaluku dó sí ibùdó won. Nínú gbogbo won Ogunlola níkan l’ó ni ìyàwó. Wón sì fi ìbùdó Ogunlolá se ibi inaju léyìn ise oojo won. Lórùn-ún-gbekun ń se èwà tà, ó sí tún ń pon otí ká pèlú; ìdí niyìí tí o fi rorun fún àwon òré oko Lórùn-un-gbékún láti máa taku-ròso àti lati máa bá ara won dámòràn. Bayíí, wón fí Ogunlola pamó sí òdò Olósì. Ìtàn fi yé wa wí pé Oba Aláàfin tí ó wà nígbà náà ni AJÁGBÓ. Rògbò dèyàn àti aápon sì wà ní àkókò ti Ogunlolá gbé aro ko náà lo si Ààfin Oba; Ogun ni, Ogun t’ó sì gbóná girigiri ni pèlú-Orúko Ogun ni, Ogun náà ni OGUN ÒGBÒRÒ. Nínú ilé tí a fi Ogunlola. sí, ni ó ti ráńse sí Aláàfìn wí pé bí wón bá le gba òun láàyè òun ní ìfé sí bí bá won ní pa nínú Ogun ògbòrò náà. Eni tí a fi tì, pàrowà fún Ogunlola nítorí wí pé Ogun náà le púpò àti wí pé kò sí bí ènìyàn tilé lé è ní agbára tó tí ó le ségun olòfè náà. Won kò lée se àpèjúwe òlòté náà; wón sá mò wí pé ó ń pa kúkúrú, ó sí ń pa gigun ni. Aláàfin fún Ogunlolá láse láti rán rán òun lówó nípa Ogun ògbòrò náà. Aláàfín ka Ogunlolá sí eni tí a fé sun je, tí ó fi epo ra ara tí o tún sún si ìdìí ààro, ó mú isée sísun Yá ni. Alaafin súre fún Ogunlolá. iré yìí ni Ogunlola bà lé. Ogunlolá dójú Ogun, ó pitu meje tí ode pa nínú igbo ó se gudugudu meje Yààyà méfà. Àwon jagun-jagun Òyó fi ibi ota gunwa sí lórí igin han atamatane Ogunlolá, Ogunloá sì “gán-án-ní” rè. Nibi ti ota Alaafin yìí tí ń gbiyanju láti yo ojú síta láti se àwon jagun-jagun lósé sé ofà tó sì loro ni olòtè yìí ń ló; mó kèjè ní Olòtè kò tí ì mórí bó sínú tí orun fi yo lówó Ogunlolá; lorun ló sí ti bá Olòtè; gbirigidi la gbo to Olòtè ré lule lógìdo. Inú gbogbo àwon jagun-jagun Òyó sì dún wón yo sèsè bí omodé tí seé yò mò eye. Ogunlolá o gbé e, o di òdò Aláàfin; nígbà yìí ni Aláàfin to mo wí pé Elémòsò ni ń se alèsà léyìn àwon ènìyàn òun. Bayìí ni Ogunlolá se àseyorí ohun ti ó ti èrù jèjè sí okan àyà àwon ara ilu òyó. Aláàfin gbé Osiba fún Ogunlolá fún isé takun-takun tí ó se, o si rò ó kìí ó dúró nítòsi òun; sùgbón Ogunlolá bèbè kí òun pasà sí ibùdó òun kí ó ó máa rańse sí òun. Báyìí Aláàfin tú Ogunlolá sílè láàfín nínú ìgbèkùn tí a fii sí kò ní jé àwáwí rárá láti so wí pé nínú ìlàkàkà àti láálàà tí Ogunlolá se ri èyín Elémoso ni kò jó sí pàbó tí ó sí mú oruko ÒGBÓMÒSÓ jade. Erédì re nìyìí Gbara tí a tú Ogunlola sílè tán pèlu ase Alaafin tí ó sì padà si ibùdó rè nì ìdí igi Àjàgbon ni bí èrò bá ń ló tí won ń bó, won yóò máa se àpèjuwe ibudo Ogunlolá gégé bíí Bùdó ò-gbé-orí-Elemoso; nígbà tí ó tún se ó di Ògbórí-Elemòsó kó tó wà di Ògbélémòsó; sùgbón lónìí pèlú Òlàjú ó di ÒGBÓMÒSÓ

Iselu ni Ogbomoso[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Baálè ni Olórí ìlú Ògbómòsó. Nínú ìlànà ètò ìjoba, agbára rè kò jut i ìgbìmò àwon ìjòyè ìlú rè lo. Àwon òjògbón ti se àlàyé wipe irú ètò báyìí wà láti rí pé Baálè tàbí Oba kò tàpá sí àwon ìgbìmò ìjòyè kí gbogbo nnkan lè máa lo déédéé ni ìlú. Irú ètò yìí yàto púpò sí ìlànà ètò Ìjoba àwon ìlú aláwò-funfun ninú eyi ti àse láti se òfin wà lówó ilé asòfin, tí ètò ìdájó wà lówó ìgbìmò ìjoba. Ekìínní kò gbódo yo enu sí isé èkejì, oníkálukú ló ni àyè tirè. Ní ti ètò ìjoba Yorùbá, Oba atì àwon ìjòyè ńfi àga gbá’ga ni nínú èyí tí ó jo pé ìjà le selè láàrin won bi òkan bá tayo díè sí èyí. Ohun tí ó mu un yàtò ni wípé Sòún, baba ńlá ìdílé àwon Baálè, dé sí ibi tí ó di Ògbómòsó lónìí léhìn tí àwon méta ti saájú rè dé ibè. Nipa akíkanjúu rè ló fi gba ipò asíwájú lówó àwon elégbé rè yókù. Akéhìndé sì di ègbón lati igba yi lo títí di òní, àwon baále ti a ti je ní Ògbómòsó kò jé kí àwon ìdílé eni méta ti o saáju Sòún dé ìlú je oyè pàtàkì kan. Èrù mbà wón pé ìkan nínú àwon omo eni méta yìí lè so wípé òun ní ètó láti se Olórí ìlú. Nitorina ni o fi jé pé àwon ìjòyè ìlú tí o mbá Baálè dámòràn láàrin àwon eni tí ó dé sí ìlú léhìn Sohún ní a ti yan wón. Síbè náà, Baálè kan kò gbodò tàpá si ìmòràn àwon ìjòyè ìlú, pàápàá nínú àwon oro tí ó je mo isèdálè. Èyí se pàtàkì jù ní nnkan ogórùn odún sí àkókò ti a ńso nípa rè yìí. Àwon ópìtàn ìlú Ògbómòsó so pé gbogbo àwon Baálè ti won tàpá si ìmòràn ìjòyè ìlú ni Aláàfin rò lóyè. Abé Aláàfin ni Ògbómòsó wà ní ìgbà náà....

  • Oludare Olajubu Ìwé Àsà ìbílè Yorùbá, Ojú-iwé 1-11, Ikeja; Longman Nigeria Limited, 1975.
  • Babátúndé Agírí. Ètò Ìsèlù ní Ògbómòsó ní ìwòn Ogórùn Odún séhìn; Ojú-iwé 97-104.


References[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Akóìjánupọ̀: 8°08′N 4°15′E / 8.133°N 4.25°E / 8.133; 4.25