Jimoh Oyewumi, Ajagungbade III
Jimoh Oladunni Oyewumi, Ajagungbade III | |
---|---|
Ṣọ̀ún of Ògbómọ̀ṣọ́
| |
Reign | 24 October 1973 – 12 December 2021 |
Coronation | 14 December 1973 |
Predecessor | Salami Ajiboye Itabiyi |
Successor | Ghandi Afolabi Olaoye, Orumogege III |
Spouse | Ayaba Olaronke Oyewumi |
Full name | |
Jímọ̀h Ọládùnní Oyèwùmí | |
House | Oluwusi |
Father | Oba Bello Afolabi Oyewumi Ajagungbade II |
Mother | Ayaba Seliat Olatundun Oyewumi |
Born | Ogbomosho, Nigeria | 27 Oṣù Kàrún 1926
Died | 12 December 2021 Nigeria | (ọmọ ọdún 95)
Ọba Jimoh Oladunni Oyewumi, Ajagungbade III (Yoruba: Jímọ̀ Ọládùnní Oyèwùmí; 27 May 1926 – 12 December 2021) fìgbà kan jẹ́ Sọ̀ún àti olórí ìlú Ògbómọ̀ṣọ́, fún ọdún méjìdínláàádọ́ta (48 years), títí di ìgbà tó kú ní ọdún 2021.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti ibi tó ti ṣẹ̀ wá
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Oba Jimoh Oladunni Oyewumi, Ajagungbade III, ni wọ́n bí gẹ́gẹ́ bí i Prince Jimoh Oladunni Oyewumi ní 27 May 1926 sínú ìdílé ọlọ́ba ti ilé Oluwusi ní ìlú Ògbómọ̀ṣọ́, sínú ìdílé oba tó wà lórí oyè nígbà náà, ìyẹn Oba Bello Afolabi Oyewumi, Ajagungbade I, àti ọ̀kan lára àwọn olorì, ìyẹn Seliat Olatundun Oyewumi. Bàbá rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyàwó, ó sì ní ọmọ mẹ́tàlélọ́gọ́ta (63 children), ìyẹn ọmọbìnrin mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31 daughters) àti ọmọkùnrin méjìlélọ́gbọ̀n (32 sons).[1] Òun ni àbígbẹ̀yìn láàrin àwọn ọmọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ìyá rẹ̀ bí.[2] Wọ́n bi ní ọdún kẹwàá tí bàbá rẹ̀ ti gun orí oyè.
Bàbá-bàbá rẹ̀, ìyẹn Oba Gbagungboye Ajamasa, Ajagungbade I, tó jọba láàárín ọdún 1869 sí 1871 (tàbí 1870 sí 1877). Bàbá bàbá-bàbá rẹ̀, ìyẹn Oluwusi Aremu tó jọba láàárín ọdún 1826 sí 1840. Oluwusi jẹ́ ọmọbà Toye Akanni Alebiosu ti Ogbomoso, tó jẹ́ Aare Ona Kakanfo keje ti ìlú Ọ̀yọ́ àti Sọ̀ún Ògbómọ̀ṣọ́.[3]
Ètò-ẹ̀kọ́ kí ó tó jọba
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Bàbá Oyewumi kú ní 18 February 1940, nígbà tó wà ní ọmọdún mẹ́tàlá. Lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀, ó ní láti dẹ́kun lílọ sí ìlé-ìwé ti St. Patrick Catholic School, ní Oke-Padre ní Ìbàdàn, ó sì padà sí Ògbómọ̀ṣọ́, níbi tí ó ti gbé pẹ̀lú ìyá rẹ̀ lásìkò ìsìnkú ọlọ́ba náà. Ó lọ sí Ogbomoso People's Institute, ní Paku, ní Ogbomoso láti lọ tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó í láti kúrò láti lọ kọ́ bí wọ́n ti ń hun aṣọ pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní Iléṣà. ibẹ̀ ni ó sì tí kọ́ bí wọ́n ti ń hun aso ofi. Ó padà rin ìrìn-àjò lọ sí ìlú Jos, ní Nàìjíríà ní 17 May 1944, níbi tí ó ti bẹ̀rẹ̀ ìdókòwò rẹ̀ nínú títà àti ríra ọtí òyìnbó láti United Kingdom. Ìmọ̀ rè láti sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ṣí ilèkùn owò púpọ̀ fún un, ó sì da owò pọ̀ mọ́ ọlpọ̀lọpọ̀ àwọn aláwọ̀ funfun. Lẹ́yìn náà ló ṣèdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ J.O.Oyewumi and Company (Nigeria) Limited, èyí tó jẹ́ ilé-ìgbàlejò.[4] Ó padà lọ sí Ògbómọ̀ṣọ́ láti Jos ní ọdún 1973, láti lọ forúkọsílẹ̀ fún ìdíjedupò ọba ti Sọ̀un lẹ́yìn ikú Oba Olajide Olayode II.
Ìgbésí ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Oyewumi jẹ́ oníyàwópúpọl, ó sì fé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyàwó. Ó fẹ́ ìyàwọ́ àkọ́kọ́ rẹ̀, ìyẹn Ayaba Igbayilola Oyewumi (tó ti ṣaláìsí báyìí), ní ọdún 1950. Lára àwọn ìyàwó rẹ̀ ni Ayaba Olaronke Oyewumi (b. 1949). Ó ní ọmọ mẹ́rìndínlógún (24 children) àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ọmọ àti ọmọ ọmọ-ọmọ.[5] Kunle Oyewumi ni ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kọkànlélógún rẹ̀.[6] Ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan láar àwọn gbajúgbajà onímọ̀, ìyẹn Oyeronke Oyewumi.[7] Ó jẹ́ Mùsùlùmí àmọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ àti ìyàwó rẹ̀ jẹ́ Kìrìsìtẹ́ẹ́nì.[8]
Ó wàjà ní 12 December 2021, ní ọmọdún márùndínlọ́gọ́run (95).[9]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Celebrating Soun of Ogbomoso, Oba Jimoh Oladunni Oyewumi @94". 27 May 2020.
- ↑ "At 90, Oba Oyewumi opens up… My life as Soun of Ogbomoso". 27 May 2016.
- ↑ "The Souns | The Land of Ogbomoso". Archived from the original on 2023-04-25. Retrieved 2023-12-03.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedauto3
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedauto22
- ↑ "Untold Story of Soun of Ogbomoso's son who is Orji Uzor Kalu's powerful aide | Prince Kunle Oyewunmi shares the story of his life with asabeafrika + He is the 21st son of the Soun | Asabeafrika". Archived from the original on 2023-09-19. Retrieved 2023-12-03.
- ↑ Oyewumi, Oyeronke (1997). The Invention of Women: Making an African Sense of Western Gender Discourses. University of Minnesota Press. pp. xvi. ISBN 0-8166-2441-0.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedauto32
- ↑ Soun Of Ogbomoso Jimoh Oyewumi Dies