Ilú-ọba Ọ̀yọ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Oyo Empire)
Orílẹ̀ Ọ̀yọ́  (Yorùbá)
Oyo Empire
Empire

Life span?
 

Location of Oyo Empire
Oyo Empire during the 17th–18th centuries
Capital
Language(s) Yoruba
Religion Yoruba religion, Islam, Christianity
Government Elective Monarchy
Alaafin
 - c. 1300 Oranmiyan
 - ????–1896 Adeyemi I Alowolodu
Legislature Oyo Mesi and Ogboni
History
 - Established Enter start year
 - Disestablished Enter end year
Area
 - 1680 [1] 150,000 km2 (57,915 sq mi)
Ní òní ó jẹ́ apá Yorubaland · Nigeria · Benin
Warning: Value not specified for "continent"
Oyo Empire and surrounding states, c. 1625.

Àdàkọ:Royal house Ilẹ̀ Ọba Ọ̀yọ́ jẹ́ ikan pataki lara ilẹ̀ Yorùbá ni apá iwọ̀ Oorùn ilẹ̀ Adúláwọ̀. Idagbasoke Ilẹ Ọba Ọyọ ko sé lẹyin bi wọn ṣe ni agekale oun itọsẹ iṣejọba to lọọrin ti wọn fi n tolu ati awọn ilu amọna ti wọn wa labẹ iṣakoso wọn laye atijọ. Bakan naa ni wọn n ṣe amulo awọn ifẹsẹmulẹ okowo to mulẹ ṣinṣin ati bi wọn ṣe ni agbekalẹ aato awọn ọmọ ogun ti wọn le lẹgbẹrun lẹgbẹrun ti wọn fi n koju iṣoro aabo ninu ilu ati leyin odi. Laarin ọrundun ketadinlogun si ọrundun kejidinlogun sẹyin, Ilu Ọyọ ni o ni eto iṣejọba ti o duro ṣinṣin julọ ni apa iwọ Oorun ile Adulawọ, [2] ti pupọ awọn ilẹ Ọba ti wọn sunmọ wọn si je ilẹ amọna labẹ wọn latari eto iṣejọba ati okowo to fi mọ eto aabo ni o mu ki awọn ilẹ ọba naa o sa si abẹ won fun aabo to peye. Lara awọn ile ọba wọnyi ni Fon, ilẹ ọba Kingdom of Dahomey ti o ti di orílẹ̀-èdè Benin loni.


Ìtàn ilè Ọba Ọ̀yọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn akọni ìwáṣẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Yoruba people Itan ilẹ Ọba Ọyọ bẹrẹ lati ori olupilẹṣẹ rẹ ti gbogbo ènìyàn mọ si Ọ̀rányàn tabi Ọ̀rànmíyàn ti o jẹ bikẹyin Oduduwa ni (Ilé-Ifẹ̀). Gẹgẹ bi itan ti ṣe sọ, Ọranmiyan ṣe ipinu pẹlu awọn ẹgbọn rẹ lati kọ ẹgbin ti o ta le baba re ti n ṣe Oduduwa lati ọdọ awọn alamulegbe wọn nipa kikogun ja wọn. Nigba ti wọn n lọ soju ogun naa, awọn t'ẹgbọn t'aburo ba ni ede aiye-ede laarin ara wọn ni gbogbo wọn ba fi pínyà ti wọn si lọ lọtọọtọ pẹlu awọn ọmọ gun ikọọkan wọn.[3] Latari eyi, awọn ọmọ ogun ti Ọranmiyan ni kere jọjọ lati tẹ siwaju lori ipinu ọkan re nipa ogun naa mọ, fundi eyi ni oun ati awọn ọmọ goun rẹ ba fi rin titi won fi de bebe odò Niger River ti wọn si fi de ilu Ibusà (Bussa). Ilu yi ni awọn alaṣẹ ibẹ ti gbaa ni alejo ti wọn si ro lagbara pẹlu bi wọn ṣe so ejò kan ti wọn fi oogun pese rẹ mọọ lọrun.

Awọn alaṣẹ ti wọn gba Ọranmiyan lalejo si sọ fun wipe ki o tẹle ejo naa titi de ibi ti ejo naa yoo duro lo ojọ meje ti yoo si wọnu ilẹ lọ. Ọranmiyan tẹle amọran wọn, ibi ti ejo naa wọlẹ si, ibẹ naa si ni wọn tẹ ibi ti o di ilu Ọ̀yọ́ loni. Ọgnagan ibi ti ejo yi wolẹ si ni wọn n pe ni Àjàká loni. Ọ̀ranmiyan tẹ ilu Ọyọ, oun naa si ni o kọkọ jẹ Ọba ti wọn si n pee ni "Alàafin Ọ̀yọ́" .[4]

Nigba ti wọn n kọ Ọyọ lọwọ, awọn ọmọ ogun Bariba gbogun lati gba ilu tuntun naa, amọ Ọrangun Ajagunla lati ile-Ila ti o jẹ ẹgbọn fun Ọranmiyan ni o ko awọn ọmọ ogun wa lati gbeja aburo rẹ ti o si gba ilu Ọyọ lọwọ awọn ọmọ ogun Bọ̀gú. Ko pẹ ti Ọranyan jagun ajaṣẹ ni iyawo re Torosi ti o jẹ ọmọ oba Nupe ti j je iyawo rẹ bi ọmọ ọkunrin kan ti o sọ orukọ rẹ ni Ajuwọn Ajaka. Lẹyin igba diẹ, ni Torosi tun bi ọmọ ọkunrin miran ti wọn pe ni Arabambi ti wọn n oe ni Ṣàngó. Gẹgẹ bi itan ṣe sọ, Ṣango jẹ oruko ti Arabambi gba lati ọdọ babba iya rẹ ti o tumọ si ọlọrun Àrá.

Ibẹrẹ ọdun (13th century sí 1535)[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ibẹrẹ ọdun 1300 CE (common era), ni awọn onimọ sọ wipe wọn da ilu Ọyọ silẹ.[5] Alaafin Ajuwọn Ajaka ni o gbapo Ọba lẹyin Ọranmiyan, amọ wọn yọọ nipo nitori wipe Ajuwọn Ajaka o fẹran alaafia ti ko si nigbagbọ wipe ogun ni o le yanju aawọ ti o ba ṣẹlẹ, ati wipe o faye gba gbogbo awọn oloye re lati ṣe ohun ti o ba wu wọn ninu ilu. [6] Ẹni ti wọn fi jọba lẹyin rẹ ni Àjàká ti a mọ si Ṣàngó, ti awọn eniyan pada sọ di òrìṣà mọ̀nà-mọ́ná leyin ikú rẹ. Lẹyin eyi ni Ajaka pada sori apere ọba ti oun naa si di arogunmasa, arogun malelo ati arogunyọ. Lẹyin Ajaka ni Alaafin Kori gorin itẹ ti o si jagun gba ilu ọpọ ilu ti àwọn ilu ti o di igboro Ọyọ lonii. [4]

Ọ̀yọ́ Ilé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀yọ́ Ilé ni aarin gbungbun ilu Ọyọ, ibẹ naa si ni wọn tun n pe ni Ọyọ Katunga, Ọyọ Atijọ' tabi Ọyọ-Oro [7] Ile tabi aye ti o ṣe pataki julọ ni Ọyọ ni Ààfin ati ọjà-Ọba. Wọn mọ odi yika gbogbo enu iloro ati aala igboro Ọyọ ti ẹnu abawọle rẹ si jẹ mẹtadinlogun. Aafin ati Ọja-Ọba yi ni wọn n fi pataki Ọba Ọyọ han, yala fun eni ti o je ọmọ ilu tabi alejo.

Ija akoso llu Ọyọ gba[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ni nkan bi ọdun 1535, awọn alagbara ile Nupe ja iṣakoso ilu Ọyọ gba nigba ti Tsoede ti o jẹ adari ọmọ ogun Nupe le Alaafin Onigbogi ati awọn ìjòyè rẹ kuro ti wọn sì sa lọ si ile Ọba Bogu tabi Ibariba. [8][9] Tsoede ati awọn ọmọ ogun re lo ilu Ọyọ titi di ibẹrẹ ọrundun metadilogun.[10]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Thornton104
  2. Forde,1967, p. 36
  3. "Oranyan" (in en-US). Litcaf. 2016-01-12. https://litcaf.com/oranyan/. 
  4. 4.0 4.1 Stride & Ifeka 1971, p. 291
  5. Franz, Alyssa; Franz, Alyssa (2009-06-16). "Kingdom of Oyo (ca. 1500-1837) •". Welcome to Blackpast •. Retrieved 2023-09-15. 
  6. "Ajaka" (in en-US). Litcaf. 2016-01-12. https://litcaf.com/ajaka/. 
  7. Goddard 1971, pp. 207–211.
  8. Stride & Ifeka p. 292
  9. Oliver & Atmore 2001, p. 89.
  10. Thornton 1999, p. 77.