Jump to content

Alaafin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Aláàfin, tàbí Ẹni tí ó ni aàfin lédè Yorùbá jẹ́ orúkọ oyè ọba Ọ̀yọ́ àti àgbègbè-ìṣèjọba rẹ́ láyé àtijó [1] àti ìlú Ọ̀yọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ ti apá ìlà - ìwọ̀-oòrùn ní Nigeria. Ó jẹ́ òye ọba Ọ̀yọ́.[2] Nígbà mìíràn, wọ́n máa ń túmọ̀ rẹ̀ sí ni àsìkò ijoba aláṣẹ. Ó jọba, ó sì ṣàkóso lórí àgbègbè-ìṣèjọba Ọ̀yọ́ àtijọ láti orílẹ̀-Olómìnira Benin sí Nigeria, lára àwọn àgbègbè náà ni àwọn Ìpínlẹ̀ kan ni apá gúsù àti iwọ̀-oòrùn sí apá àríwá àgbègbè-ìṣèjọba Ọ̀yọ́. Àwọn tí ó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀ ni wọ́n ń pè ní Yorùbá, tí wọ́n sì ń sọ Èdè|Yorùbá.

Alaafin Oyo & Sir Walter Egerton circa 1910 - Colorized
Outermost entrance to the palace of the Alaafin of Oyo called "Oju Abata"

Ìgbàgbọ́ àti ìtàn Yorùbá kan sọ pé Àlááfín Ọ̀yọ́ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọmọ méje Odùduwà tí ó wà padà di ọba, tí ó sì jẹ́ ìpìlẹ̀ṣẹ̀ orísun làjú àti ìdàgbàsókè àwọn ẹ̀yà Yorùbá.[1]

Àlááfín àti àwọn Ọ̀yọ́ Mèsì ni olórí ìgbìmọ̀ ìṣèjọ̀ba tí àgbègbè-ìṣèjọba Ọ̀yọ́ nígbà náà. The Alafin and the Oyo Mesi formed the central government of the Empire. Lábẹ́ wọn ní àwọn ọba aládé àti àwọn Baálẹ̀ t'ókù, tí wọ́n ń ṣe ìjọba àwọn ìlú àti àwọn àgbègbè tó wà lábẹ́ wọn[3] Ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín Àlááfín àti àwọn Ọba tókù ni ti ìjọba Àlááfín lóni gbogbo ilẹ̀ àti àwọn ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lábẹ́ wọ́n, tí ó sì ń pèsè fún àìní wọn aláṣẹ gbogbo ilẹ̀ tí wọ́n ń pèsè fún àwọn. Aláàfin ló ń ṣàkóso tí ó sì ń dá ààbò b'òwọ́n. Atọ́ba, ìjòyè, baálẹ̀ àti gbogbo ará ìlú ló nǹkan tí wọ́n ní láti máa ṣe fún Aláàfin.[4] Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1800, agbára Àlááfín àgbègbè-ìṣèjọba Ọ̀yọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní di kú nítorí ìjà láàárín Àlááfín àgbègbè-ìṣèjọba àti àwọn ọba aládé mìíràn àti àwọn olóyè tí wọ́n wà ní ìlú Ọ̀yọ́ tí tún jẹ́ Ọ̀yọ́ Mèsì, ìjà yìí jẹ́ kí agbára Àlááfín àgbègbè-ìṣèjọba bẹ̀rẹ̀ sí ní dínkù, tí àwọn àgbègbè-ìṣèjọba sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kúrò lábẹ́ Ọ̀yọ́ tí wọ́n sì ń dá dúró fún ara wọn.[5]

Orúkọ oyè Àlááfín yìí ni wón ṣì ń lò ní ìlú Ọ̀yọ́ lóde òní. tí ó wà ní Nigeria. Àlááfín jẹ́ olórí àwọn ijọba àwọn Yorùbá tí ó sì lágbára láti yan àwọn olóyè tí ó lè ṣojú gbogbo ilẹ̀ Yorùbá pátápátá.[6] Àpẹẹrẹ àwọn ìjòyè bẹ́ẹ̀ tí Àlááfín ní agbára láti yàn ni Ààrẹ-ọ́nà-kakanfò ti gbogbo ilẹ̀ Yorùbá, àti Ìyálóde tí ilẹ̀ Yorùbá.

Títí di ọdún 2021, Lamidi Adeyemi III, tí ó jẹ́ Aláàfin ẹlẹ́ẹ̀karùnúndínláàádọ́ta ni Aláàfin Ọ̀yọ́.[7] celebrated his 50th year on the throne.[8] Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi III, Iku Baba Yeye, Aláàfin ti Ọ̀yọ́ ni alága ayérayé ìgbìmọ̀ àwọn ọba àlàyé àti àwọn olóyè ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ títí ó fi kú lọ́jọ́ ẹ̀tì, ọjọ́ kejìlelógún oṣù kẹrin ọdún 2022.[9] Ìkíni tí wọ́n fi ń kí Aláàfin ni Ọlọ́lá Aláṣẹ ìjọba AgbègbèImperial Majesty.[10]

Ẹ kà á si[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 David D. Laitin (1986) (in en). Hegemony and Culture: Politics and Change Among the Yoruba. University of Chicago Press. p. 113. ISBN 9780226467900. https://books.google.com/books?id=dHbrDvGQEbUC&pg=PA113. 
  2. Jr, Everett Jenkins (2015-07-11) (in en). Pan-African Chronology II: A Comprehensive Reference to the Black Quest for Freedom in Africa, the Americas, Europe and Asia, 1865-1915. McFarland. pp. 220. ISBN 978-1-4766-0886-0. https://books.google.com/books?id=c4EwCgAAQBAJ&pg=PA220. 
  3. (in en) Nigerian Forum. Nigerian Institute of International Affairs. 2005. pp. 344. https://books.google.com/books?id=xhQOAQAAMAAJ&q=%22The+Alafin+(Oyo+Empire)+and+the+Oyo+Mesi+formed+the+central+government+of+the+Empire.+Local+provincial+government+was+in+the+hands+of+oba+(if+crowned+head)+or+bale+(if+not+entitled+to+wear+a+crown).%22. 
  4. Ezenwaji, Ifeyinwa U. (2002) (in en). Traditional Administrative System in Nigeria: A Study of Selected Nigerian Societies. Institute for Development Studies, University of Nigeria, Enugu Campus. pp. 154. ISBN 978-978-2409-41-6. https://books.google.com/books?id=zn4uAQAAIAAJ&q=%22The+relationship+between+the+Alafin+and+the+Obas+was+a+feudal+one,+that+is+for+his+rule+and+protection,+the+Obas,+the+Bales+and+chiefs+of+vassal+states+owed+him+certain+obligations%22. 
  5. Khapoya, Vincent (2015-07-14) (in en). The African Experience. Routledge. pp. 90. ISBN 978-1-317-34358-5. https://books.google.com/books?id=FPYoCgAAQBAJ&pg=PA90. 
  6. "No comparison between Alaafin, Aare Ona Kakanfo chiefs". Vanguard Newspaper. https://www.vanguardngr.com/2020/01/between-alaafins-chiefs-and-that-of-aare-onakakanfo-%E2%80%95gani-adams/. 
  7. Adebayo, Musliudeen (2022-04-24). "45th Alaafin of Oyo, Lamidi Adeyemi has joined his ancestors at Bara - Palace source". Daily Post Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-07-06. 
  8. "Lamidi Olayiwola Adeyemi: 50 Years on – Thisdaylive". 
  9. "Alaafin of Oyo, Oba Lamidi Adeyemi, is dead - Premium Times Nigeria". 23 April 2022. 
  10. "ALAAFIN OF OYO – This is the website for the Alaafin of Oyo" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-03-04. Welcome to the website of His Imperial Majesty, The Alaafin of Oyo, The Head and Paramount Ruler of the Yorubas.