Èdè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí

Orísìírísìí àwon Onímò ní ó ti gbìnyànjú láti fún èdè ní oríkì tàbí òmíràn sùgbón kí a tó bèrè sí ń se àgbéyèwò àwon oríkì wònyìí, èmi pàápàá yóò gbìnyìnjú láti so lérèfé ohun tí èdè túmò sí. Èdè ní í se pèlú ònà ìbánisòrò tí àwon ènìyàn ń lò ní àwùjo báyá fún ìpolówó ojà, ìbáraeni sòrò ojoojúmó, ètò ìdílé tàbí mòlébí àti béè béè lo. Ní báyìí mo fé se àgbéyèwò díè lára àwon onímò ti fún èdè. Gégé bí fatunsi (2001) se so, “Language Primarily as a System of Sounds exploited for the purpose of Communication bya group of humans.” Gégé bí ó ti so ó ní èdè jé gégé bí ònà ìrú kan gbòógì tí àwùjo àwon ènìyàn ń lò láti fi bá ara eni sòrò. Raji (1993:2) pàápàá se àgbékalè oríkì èdè ó sàlàyé wípé; “Èdè ni ariwo tí ń ti enu ènìyàn jáde tó ní ìlànà. Ìkíní lè ní ìtumò kí èkeji maa ní. Èdè máa ń yàtò láti ibìkan sí òmíràn. Ohun tó fà á ni pé èdè kòòkan ló ní ìwònba ìrú tó ń mú lò. Èdè kankan ló sì ní ìlànà tirè to ń tèlé.” Wardlaugh so nínú Ogusiji et al (2001:10) wí pé, “Language is a System of arbitrary Vocal Symbols use for human Communication.” “Èdè ni ni àwon àmì ìsogbà tí ó ní ìtumò tí o yàtò tí àwon ènìyàn ń lò láti fi bá ara won sòò.” Àwon Oríkì yìí àti òpòlopo oríkì mìíràn ni àwon Onímò ti gbìyànju láti fún èdè, kí a tó lè pe nnkan ní èdè, ó gbódò ní àwon èròja wònyí: èdè gbódò jé:

1. Ohun tí a lè fi gbé ìrònú wa jáde

2. Ariwo tí ó ń ti enu ènìyàn jáde

3. Ariwo yìí gbódò ní ìtumò

4. Aríwo yìí gbódò ní ìlànà ìlò tí yóò ní bí a ti se ń lò ó.

5. Kókó ni á ń kó o, kì í se àmútòrunwá

6. nnkan elémú-ín tó lè dàgbà sí i, tó sì lè kú ikú àìtójó ni èdè.

7. A lè so èdè lénu, a sì le kó sìlè.

Síwájú sí í, a ní àwon àbùdá ti èdè ènìyàn gégé bí àwon onímò se se àgbékalè rè. Fún àpeere

(1) Ìdóhùa yàtò sí ìtumò (Ar’bitransess)

(2) Àtagbà Àsà (Cultural transmission)

(3) Agbára Ìbísí (Productivity) àti béè béè lo. Gbogbo Ònà ìbánisòrò mìíràn yàtò láàrín èdè ènìyàn àti ti eranko kì í se ohun tí ó rorùn rárá. Nnkan àkókó nip é a gbódò wá oríkì èdè tó ń sisé lórí èyí tí a ó gbé ìpìnlè àfiwé wa lè. Sùgbón sá, kò sí oríkì tí ó dàbí eni pé ó sàlàyé oríkì èdè tàbí tí ó jé ìtéwógbà fún gbogbo ènìyàn. Charles hocket se àlàyé nínú Nick Cipollone eds 1994 wípé: Ònà kan gbòógì tí a fi lè borí ìsòro yìí nip é, kí a gbìnyànjú láti se ìdámò ìtúpalè àwon àbùdá èdè ju kí a máa gbìnyànjú láti fún èdá rè tí ó se pàtàkì ní oríkì. Torí náà, a lè pinu bóyá èdè eranko pàápàá ni àwon abida yìí pèlú… Ohun tí a mò nípa èdè eranko ni pé, kò só èdè eranko kòòkan tí ó ní àwon àbùdá èdè ènìyàn tí a ti so síwájú. Èyí ni ó mú kí á fenukò wípé àwon èdà tí kìí se àwon ènìyàn kì í lo èdè. Dípò èdè, won a máa bá ara win sòrò ní ònà tí ń pè ní ènà, àpeere ìfiyèsí (Signal Cocle). Gbogbo ònà Ìbánisòrò mìíràn yàtò sí èyí kì í se èdè. Àwon ònà náà ní:

(1) Ìfé sísú

(2) Ojú sísé

(3) Èjìká síso

(4) Igbe omodé

(5) Imú yínyín

(6) Kíkùn elédè

(7) Bíbú ti kìnnìún bú

(8) Gbígbó tí ájá ń gbó àti béè béè lo.

Gbogbo ariwo ti a kà sílè wònyí kì í se èdè nítorí pé;

(1) Wón kò se é fó sí wéwé

(2) Won kì í yí padà

(3) Won kì í sì í ní Ìtumò

Pèlú gbogbo àwon nnkan tí mo ti so nípa ìyàtò tó wà láàrín èdè ènìyàn àti eranko, Ó hàn gbangba wípé a kò le è fi èdè eranko àti ti ènìyàn wé ara won. Yorùbá bì wón ní “igi ímú jìnà sí ojú, béè a kò leè fi ikú wé oorun. Béè gégé ni èdè ènìyàn àti eranko rí. Nínú èdè ènìyàn lati rí gbólóhùn tí ènìyàn so jáde tí a sì leè fi ìmò èdá èdè fó sí wéwé. Àtiwípé ànfàní káfi èdè lu èdè kò sí ní àwùjo eranko gégé bí i ti ènìyàn. Fún bí àpeere. Olu ra ìsu Olú nínú gbólóhùn yìí jé òrò-Orúko ní ipò Olùwá, rà jé Òrò-ìse nígbà tí ísu jé òrò orúko ní ipò ààbò. A kò le rí àpeere yìí nínú gbígbó ajá, kike eye àti béèbéè lo. Nítorí náà èdè ènìyàn yàtò sí enà apeere, ìfiyèsí (Siganl Code) àwon eranko.

Àwon ìwé ìtóka sí ni àwon wònyìí.

Fatusin, S.A (2001), An Introduction to the Phonetics and Phonology of English. Green-Field Publishers, Lagos.

Rájí, S.M (1993), Ìtúpalè èdè àsà lítírésò Yorùbá. Fountan Publications, Ibadan.

Ogunsiji, A and Akinpelu O (2001), Reading in English Languag and Communication Skills. Immaculate-City Publishers, Oyo.

Nic Cipollone eds (1998), Language files Ohio State University Press, Columbus.Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]