Odùduwà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí

Odùduwà Bí abá porí akoni, áafidà halè gààràgà, táabá porí èya Yorùbá, dandan ni kí á sòrò débi eni tó jé babańlá won, Ìyen Odùduwà á tìe wòrò.

Ìtàn méjì gbógì ló sòrò tó seé gbámú nípa ibi tí Odùduwà ti wá, àkókó ìtàn náà ni ìtàn tó sórò nípa tí Odùduwà se wá láti wáá gba isé tí Olódùmarè kókó rán Obàtálá se.

Olódùmarè fún Oduduwa ní àwon nìkan máàmú ken, èyí tó mú wá láti wáá lo, ómú èwòn wá èyí tó fi rò wá, àti àkùko adìye èyí tó tan yèpè tó mú wá kálè, tí ìyàngbe ilè fi jáde.

Ó wá mú ìgbá dání, èyí tó gbìn àti alágemo tó lo wòó bóyá ilè náà ti gbe.

Ó dùduwà yìí ló wá dásèé gbogbo èdá tó wà lórí ilè ayé, ibi tó sì rò sí ni Ilé-Ifè, Ibi tí wón so pé ojúmó ti ń mó wá.

Nítóri náà, gégé bíi ìtàn yìí se so, Odùduwà kìíníkàn ńse bàbá ńlá Yorùbá nìkan, Sùgbón bàbá ńlá gbogbo aráyé, nígbà tí Ifè kìí níkàn ńse orírun Yorùbá nìkan, sùgbón orísun gbogbo èdá.

Ìtàn lejì so pé Mékà ni eni tí a mò sí Odùduwà ti wá, ìwà ìbòrìsà reè sì ló gbée kúrò ní Mékà.

Ìtàn yìí so pé Ìjà bé sílè láàrín-ín àwon elésìn musùlùmí àti àwon abòrìsà, ti Odùduwà je olórí won, inú ìjà yìí ni Lámúrúdu, eni tí ó jé bàbá Odùduwà kú sí, èyìn èyí ni Odùduwà gbéra kúrò ní Mékà tó sì wá tèdó sí Ilé-Ifè.

Ìtàn fi yé wa pé, Odùduwà bá àwon ènìyàn kan ní Ile-Ifè, àwon ènìyàn yìí ni Odùduwà bá fìjà peéta, tí ó sì borí won nígbèyìn gbéyìn ó bo rí won, ó sì wáá doba won.

Ìtàn yìí jé kí á mò wípé odùduwà ló mú ètò ìsàláóso wá sí Ilé-Ifè, èyí tó gbé wá láti ìlú Mékà.

Nígbà tí Odùduwà dàgbà títí ó wà fún àwon omo rè ní ade, ósì fún àwon kan ní ìlèkè. Àwon omo Odùduwà wònyín ló te àwon ìlú dó káàkiri ilè Yorùbá.