Jump to content

Mọ́remí Ájàṣoro

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ère Moremi Ajasoro

Mọ́remí Àjàsorò, jẹ́ akọnibìnrin kan gbòógì tó sì gbajúmọ̀ nínú ìtàn àwọn Yorùbá lápá ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà. Móremí fẹ ọ̀kan lára ẹbí Oduduwa, ti ìtàn àdáyébá sọ pé ó jẹ́ babańlá àwọn Yorùbá.[1][2][3]

Ìgbésíayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Mọ́remí jẹ́ Olorì Ọba ìlú Ilé-Ifẹ̀,[4] Omobíbí Ìlú Ọ̀fà, ó jẹ́ aḳonibìnrin tó gbajúmò ní séńtúrì méjìlá sẹ́yìn[5],  Lásìkò tí ó jẹ́ ayaba Ilé-Ifè yìí ní Ilé-Ifè àti ẹ̀yà tí ó wà ní ìtòsí wọn, tí wọ́n mọ̀ nígbà náà sí ará Igbó ń jagun lọ́wọ́lọ́wọ́. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kò fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ará Ìgbò yìí ní ìbáṣepọ̀ kankan pẹ̀lú ẹ̀ya Ìgbò tí wọ́n jẹ́ gbòógì ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní àkókò náà, opọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Ilé-Ifè ni àwọn ará Ìgbò yìí kó lẹ́rú lọ, nítorí ìdí èyí, gbogbo ẹ̀yà Yorùbá kórìíra wọn, wọ́n sí kà wọ́n sí ọ̀tá

Bí Mọ́remí jẹ́ akonibìnrin bẹ́ẹ̀  gẹ́gẹ́ ló rẹwà lópòlopò, kí ó ba lè yọ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ ìṣòro tó ń dojúko wọ́n, ó pinnu láti ṣe ìrúbọ yìówù tó nílò sí Òrìṣà Esimirin kí ó ba lè mọ àṣírí agbára àwọn Ọ̀tá tó ń fogun ja ilé-ifè

Lásìkò tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, àwọn jagunjagun Ìgbò kó Mọ́remí mọ́gun lọ sí ilẹ̀ wọ̀n, ṣùgbọ́n nítorí ẹwà àwòtúnwò tí Mọ́remí ní, Ọba àwọn Ìgbò fẹ́ e gẹ́gẹ́ bi Olorì. ó sì sọ ọ́ di ààyò láàaríń àwọn ayaba tó kù. Lẹ́yìn tí Mọ́remí lo ète Obìnrin láti mọ àṣírí agbára ọkọ rẹ̀ àti àwọn jagunjagun rẹ̀ tán, ó sá padà sí Ilé-Ifẹ̀, ó sìn tú àṣírí wọn fún àwọn Yorùbá, tí wọ́n sì lò ó láti ṣẹ́gun Ìgbò.[6]

Lẹ́yiǹ ogun tí àwọn Yorùbá gba ara wọn lẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Ìgbò, Mọ́remí padà sọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀ àárọ̀, t́í́ ń ṣe Ọba Ọ̀ràmíyàn ti Ilé-fẹ̀, tí ó sìn tún jọba Oyo lẹ́yìn ìgbá náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Kábíyèsí dá Mọ́remí lọ́lá nípa sísọ ọ́ di aàyò Olorí àti ̣Ọmọba bakan ná. Láti lè mú májẹ̀mú rẹ̀ kí ó tó riǹrìn àjò lọ sí ìlẹ̀ ̀gbò sẹ fún Orìṣà Esimirin, kété Ọba Ọ̀ràmíyàn dá ipo rẹ̀ padà gẹ́gẹ́ bí Ọmọba, Mọ́remí ṣe bí akọni, o sifi ọmọkùnrin re rubọ si ojúbọ Esimirin gẹ́gé bi májẹ̀mú.

Nǹkan ìrántí rè

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọn bẹrẹ ọdún edi ní kété tí Moremi kú lati fi déye ètùtù tí o fi ara rẹ ṣe fún ẹyà Yorùbá

Nǹkan ìrántí rè

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọn bẹrẹ ọdún edi ní kété tí Moremi kú lati fi déye ètùtù tí o fi ara rẹ ṣe fún ẹyà Yorùbá. Láìpẹ́ yìí, wọ́n ṣe àtẹ̀jáde ìtàn ìgbésí-ayé rẹ̀ nípa ìfẹ́, ìgbàgbọ́, ìboọlá fún, pàápàá jùlọ fífi ara rẹ̀ ṣe ètùtù fún ilẹ̀ Yorùbá lọ́nà orin àti eré-oíṣe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn gbọ̀ngán ìjọba ni wọ́n fi sọrí rẹ̀ káàkiri ilẹ̀ Yorùbá lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lára wọn ni Moremi High School àti àwọn ilé ìgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnri tí Lagos State University àti Obafemi Awolowo University

Lọ́dún 2017, Ọọ̀ni ti ìlú Ifẹ̀ [[Adeyeye Enitan Ogunwusi|Ogunwusi] ya ère rẹ̀ sí aafin rẹ̀ láti bọlá fún un. Ère yìí ló ga jù lọ ní Nigeria, tí ó gba ipò ère tí ó ga jù lọ lọ́wọ́ ère kan ní Ìpínlẹ̀ Imo. Ère Moremi yìí ní ó wà ní ipò kẹrin ní Afrika nínú àwọn ère tó ga jù lọ .[7]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Suzanne Preston Blier. "Art in Ancient Ife, Birthplace of the Yoruba". Harvard University. p. 83. http://scholar.harvard.edu/files/blier/files/blier.pdf. Retrieved December 22, 2016. 
  2. Dele Layiwola (1991) (pdf). The Radical Alternative and the Dilemma of the Intellectual Dramatist in Nigeria. Ufahamu: A Journal of African Studies. p. 67–68. http://escholarship.org/uc/item/4x1824zj.pdf. Retrieved December 22, 2016. 
  3. Segun Thomas Ajayi (2007). Moremi, the Courageous Queen. Indiana University (Publications Limited). ISBN 978-9-788-1250-75. https://books.google.com/?id=IuDyAAAAMAAJ&q=Moremi+Yoruba+princess&dq=Moremi+Yoruba+princess. 
  4. Sikiru, Adedoyin Olalekan (2018-05-13). "IFE HEROINE: What women can learn from Moremi". Vanguard News. Retrieved 2018-07-26. 
  5. "Proudly Yorùbá". Facebook. Retrieved 2018-07-26. 
  6. Oyeronke Olajubu (2003). Women in the Yoruba Religious Sphere (McGill Studies in the History of Religions). SUNY Press. p. 29. ISBN 978-0-791-4588-53. https://books.google.com.ng/books?id=w3CR1m0SZnkC&pg=PA29&dq=. 
  7. Bodunrin, Sola (2018-05-31). "Moremi Ajasoro: The woman who used her beauty to save her people where men failed". Legit.ng - Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-27.