Jump to content

Ilẹ̀ Yorùbá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Yorubaland)
Ilẹ̀ Yorùbá

Ilẹ̀ Yorùbá

Southwest Nigeria, Western Nigeria, South and Central Benin, Central Togo and Ghana
Cultural region
Nickname(s): 
Ilẹ̀ Káarò-Õjíire
Yorubaland Cultural Area of West Africa
Ibùdó ilẹ̀  Yorubaland  (green)

West Africa  (white)

Apá ilẹ̀ Benin
Nàìjíríà Nàìjíríà
 Togo
- Ibi ìtẹ̀dó ilẹ̀ Ifẹ̀400 BCE
- Oyo Empire1400
- British Colony1862
- French Colony1872
- Dahomey (Now Benin)1904
- Nigeria1914
Founded byPYIG (Proto Yoruba-Itsekiri-Igala)
Regional capitalIlẹ̀-Ifẹ̀ (Cultural/Spiritual)
Ibadan (Political)
Lagos/Eko (Economic)
Former seatOyo-Ile (Old Political)
Composed of
Government
 • TypeMonarchies
Oba (King)
Ògbóni (Legislature)
Olóye (Chiefs)
Balógun (Generalissimo)
Baálẹ̀ (Village/Regional heads in Western Yorubaland)
Ọlọja (Village/Regional heads in Eastern Yorubaland)
Area
 • Total142,114 km2 (54,871 sq mi)
Highest elevation
1,055 m (3,461 ft)
Lowest elevation
−0.2 m (−0.7 ft)
Population
 (2015 estimate)
 • Total~ 55 million
 • Density387/km2 (1,000/sq mi)
 In Nigeria, Benin and Togo
Demographics
 • LanguageYoruba
 • ReligionChristianity, Islam, Yoruba religion
Time zoneWAT (Nigeria, Benin), GMT (Togo)

Ilẹ̀ Yorùbá ni agbègbè ìgbéró àsà ilẹ̀ àwọn ọmọ YorùbáÌwọ̀òrùn Áfríkà. Ilẹ̀ Yorùbá fẹ̀ láti Nàìjíríà, Benin títídé Togo, agbègbè ilẹ̀ Yorùbá fẹ̀ tó 142,114 km2 106,016 km2 inú rẹ̀ (74.6%) bọ́sí Nàìjíríà, 18.9% bósí orílẹ̀-èdè Benin, àti 6.5% yìókù bósí orílẹ̀-èdè Togo. Ilẹ̀ ìgbéró àsà Yorùbá yìí ní iye àwọn ènìyàn bíi mílíọ́nù 55.[1][2]


Ìtàn Àkọọ́lẹ̀ Yorùbá

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí Àtàndá (1980), bí àwọn Yorùbá ṣe dé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti àsìkò tí wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀ kíi ṣe ìbéèrè tí ẹnikẹ́ni lè dáhùn ní pàtó nítorí pé àwọn baba nlá wọn kò fi àkọsílẹ̀ ìṣe àti ìtàn wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àjogúnbá.

Àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu tí a gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá yàtọ̀ sí ara wọn díẹ̀díẹ̀. Ìtàn kan sọ fún wa pé àwọn Yorùbá ti wà láti ìgbà ìwáṣẹ̀ àti láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé. Ìtàn ọ̀rùn pé kí ó wá ṣẹ̀dá ayé àti àwọn ènìyàn inú rẹ̀. Ìtàn náà sọ fún wa pé Odùduwà sọ̀kalẹ̀ sí Ilé-Ifẹ̀ láti ọ̀run pẹ̀lú àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Wọ́n sì ṣe iṣẹ́ tí Olódùmarè rán wọn ní àṣepé. Nípasẹ̀ ìtàn yìí, a lè sọ pé Ilé-Ifẹ̀ ní àwọn Yorùbá ti ṣẹ̀, àti pàápàá gbogbo ènìyàn àgbáyé.

Ìtàn mìíràn tí a tún gbọ́ sọ fún wa pé àwọn Yorùbá wá Ilé-Ifẹ̀ láti ilẹ̀ Mẹ́kà lábẹ́ àkóso Odùduwà nígbà tí ìjà kan bẹ́ sílẹ̀ ní ilẹ̀ Arébíà lẹ́yìn tí ẹ̀sìn Islam dé sáàrin àwọn ènìyàn agbègbè náà. Àwọn onímọ̀ kan nípa ìtàn ti yẹ ìtàn yìí wò fínnífínní, wọ́n sì gbà wí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe é ṣe kí àwọn Yorùbá ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Mẹ́kà àti agbègbè Arébíà mìíràn kí wọ́n tó ṣí kúrò, ibi tí wọ́n ti ṣẹ̀ wá gan-an ni íjíbítì tàbí Núbíà. Àwọn onímọ̀ yìí náà gbà pé Odùduwà ni ó jẹ́ olórí fún àwọn ènìyàn yìí.

Kókó pàtàkì kan tí a rí dìmú ni pé Odùduwà ni olùdarí àwọn ènìyàn tí ó wá láti tẹ̀dó sí Ilé-Ìfẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtàn méjéèjì tí a gbọ́ ṣe sọ. Tí a bá yẹ ìtàn méjéèjì wò, a ó rí i pé kò ṣe é ṣe kí Odùduwà méjèèjì jẹ́ ẹnìkan náà nítorí pé àsìkò tàbí ọdún tí ó wà láàrin ìṣẹ̀dá ayé àti àsìkò tí ẹ̀sìn Islam dé jìnna púpọ̀ sí ara wọn. Nítorí ìdí èyí a lè gbà pé nínú ìtàn kejì ni Odùduwà ti kópa. Ìdí mìíràn tí a fi lè fara mọ́ ìtàn kèjì ni pé lẹ́yìn àyẹ̀wò sí ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá fínnífínní, ó hàn gbangba pé Odùduwà bá àwọn ẹ̀dá Olọ́run kan ní Ilé-Ifẹ̀ nígbà tí ó dé ibẹ̀. Àwọn ìtàn kan dárúkọ Àgbọnmìrègún tí Odùduwà bá ní Ilé-Ifẹ̀. Èyí fihàn pé kìí ṣe òfìfò ní ó ba Ilé-Ifẹ̀, bí kò ṣe pé àwọn kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú Àgbọnmìrègún. Èyí sì tọ́ka sí i pé a ti ṣẹ̀dá àwọ̣n ènìyàn kí ọ̀rọ̀ Odùduwà tó jẹ yọ, nítorí náà, kò lè jẹ́ Odùduwà yìí ni Olódùmarè rán wá láti ṣẹ̀dá ayé gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́ ọ nínú ìtàn ìṣẹ̀dá.

Lọ́nà mìíràn ẹ̀wẹ̀, a rí ẹ̀rí nínú ìtàn pé Odùduwà níláti gbé ìjà ko àwọn ọ̀wọ́ ènìyàn kan tí ó bá ní Ilé-Ifẹ̀ láti gba ilẹ̀, àti pàápáà láti jẹ́ olórí níbẹ̀. Ìtàn Mọ́remí àjàṣorò tí ó fi ẹ̀tàn àti ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin kan ṣoṣo tí ó bí gba àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ìmúnisìn àwọn ẹ̀yà Ùgbò lè jẹ̀ ẹ̀rí tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Odùduwà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ja ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun kí wọ́n tó le gba àkóso ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ọ̀wọ́ ènìyàn kan tí wọ́n bá ní Ilé-Ifẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtàn àbáláyé ti sọ.

Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn ènìyàn Yorùbá wà káàkiri ìpínlẹ̀ bí i mẹ́sàn-án. Àwọn ìpínlẹ̀ náà ni Ẹdó, Èkó, Èkìtí, Kogí, Kúwárà, Ògùn, Òndò, Ọ̀ṣun àti Ọ̀yọ́.[3]

Lóde òní, Yorùbá wà káàkiri ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú (Áfíríkà), Amẹ́ríkà àti káàkiri àwọn erékùsù tí ó yí òkun Àtìlántíìkì ká. Ní ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú. A le ríwọn ní Nàìjíríà, Gáná, Orílẹ̀-Olómìnira Bẹ̀nẹ̀, Tógò, Sàró àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti àwọn erékùsù káàkiri, a lè rí wọn ní jàmáíkà, Kúbà, Trínídáádì àti Tòbégò pẹ̀lú Bùràsíìlì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Yàtọ̀ sí ètò ìjọba olósèlú àwarawa tí ó fi gómìnà jẹ olórí ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan, a tún ní àwọn ọba aládé káàkiri àwọn ìlú nlánlá tí ó wà ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Díẹ̀ lára wọn ni Ọba ìbíní, Ọba Èkó, Èwí tí Adó-Èkìtì, Òbáró ti Òkéné, Aláké tí Abẹ́òkúta, Dèji ti Àkúrẹ́, Olúbàdàn ti Ìbàdàn, Àtá-Ója ti Òṣogbo, Sọ̀ún ti Ògbòmọ̀ṣọ́ ati Aláàfin ti Ọ̀yọ́.[4]

Baálẹ̀ ní tirẹ̀ jẹ́ olórí ìlú kékeré tàbí abúlé. Ètò ni ó sọ wọ́n di olórí ìlú kéréje nítorí pé Yorùbá gbàgbọ́ pé ìlú kìí kéré kí wọ́n má nìí àgbà tàbí olórí. Aláàfin ni a kọ́kọ́ gbọ́ pé ó sọ àwọn olórí báyìí di olóyè tí a mọ̀ sí baálẹ̀.

Lábẹ́ àwọn olórí ìlú wọ̀nyí ni a tún ti rí àwọn olóyè orísìírísìí tí wọ́n ní isẹ́ tí wọ́n ń se láàrín ìlú, ẹgbẹ́, tàbí ìjọ (ẹ̀ṣìn). Lára irú àwọn oyè bẹ́ẹ̀ ni a ti rí oyè àjẹwọ̀, oyè ogun, oyè àfidánilọ́lá, oyè ẹgbẹ́, oyè ẹ̀ṣìn àti oyè ti agboolé bíi Baálé, Ìyáálé, Akéwejẹ̀, Olórí ọmọ-osú, Ìyá Èwe Améréyá, Mọ́gàjí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ní báyìí, tí a bá wo èdè Yorùbá, àwọn onímọ̀ pín èdè náà sábẹ́ ẹ̀yà Kwa nínú ẹbí èdè Niger-Congo. Wọ́n tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹ̀yà Kwa yìí ló wọ́pọ̀ jùlọ ní sísọ, ní ìwọ̀ oòrùn aláwọ̀ dúdú fún ẹgbẹ̣ẹgbẹ̀rún ọdún. Àwọn onímọ̀ èdè kan tilẹ̀ ti fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé láti orírun kan náà ni àwọn èdè bí Yorùbá, Kru, Banle, Twi, Ga, Ewe, Fon, Edo, Nupe, Igbo, Idoma, Efik àti Ijaw ti bẹ̀rẹ̀ sí yapa gẹ́gẹ́ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó dúró láti bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọ̀dún sẹ́yìn.

Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn èdè orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni èdè Yorùbá. Àwọn ìpínlẹ̀ tí a ti lè rí àwọn tó n sọ èdè Yorùbá nílẹ̀ Nàìjíríà norílẹ̀ èdè Bìní. Tógò àti apá kan ní Gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà bí i Cuba, Brasil, Haiti, àti Trinidad. Ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí a dárúkọ, yàtọ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, òwò ẹrú ni ó gbé àwọn ẹ̀yà Yorùbá dé ibẹ̀.

Ìràn Yorùbá jẹ́ ìran tó ti ní àṣà kí Òyìnbó tó mú àṣà tiwọn dé. Ètò ìsèlú àti ètò àwùjọ wọn mọ́yán lórí. Wọ́n ní ìgbàtbọ́ nínú Ọlọ́run àti òrìṣà, ètò ọrọ̀ ajé wọn múnádóko.

Yorùbá ní ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀lé láti fi ọmọ fọ́kọ tàbí gbé ìyàwó. Wọ́n ní ìlànà tó sọ bí a se n sọmọ lórúkọ àti irú orúkọ tí a le sọ ọmọ torí pé ilé là á wò, kí a tó sọmọ lórúkọ. Ìlànà àti ètò wà tí wọ́n ń tẹ̀lé láti sin ara wọn tó papòdà. Oríìsírísìí ni ọ̀nà tí Yorùbá máa ń gbá láti ran wọn lọ́wọ́, èyí sì ni à ń pè àṣà ìràn-ara-ẹni-lọ́wọ́. Àáró, ìgbẹ́ ọdún dídẹ, ìsingbà tàbí oko olówó, Gbàmí-o-ràmí àti Èésú tàbí Èsúsú jẹ́ ọ̀nà ìràn-ara-ẹni-lọ́wọ́.

Yorùbá jẹ́ ìran tó kónimọ́ra. Gbogbo nǹkan wọn sì ló létò. Gbogbo ìgbésí ayé wọn ló wà létòlétò, èyí ló mú kí àwùjọ Yorùbá láyé ọjọ́un jẹ́ àwùjọ ìfọ̀kànbalẹ̀, àlàáfíà àti ìtẹ̀síwájú. Àwọn àṣà tó jẹ mọ́ ètò ìbágbépọ̀ láwùjọ Yorùbá ní ẹ̀kọ́-ilé, ètò-ìdílé, ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ tàbí irọ̀sírọ̀. Ẹ̀kọ́ abínimọ́, àwòse, erémọdé, ìsírò, ìkini, ìwà ọmọlúàbí, èèwọ̀, òwe Yorùbá, ìtàn àti àlọ́ jẹ́ ẹ̀kọ́-ilé. Nínú ètò mọ̀lẹ́bí lati rí Baálé, ìyáálé Ilé, Ọkùnrin Ilé, Obìnrin Ilé, Ọbàkan, Iyèkan, Ẹrúbílé àti Àràbátan.

Oríṣìíríṣìí oúnjẹ tó ń fún ni lókun, èyí tó ń seni lóore àti oúnjẹ amúnidàgbà ni ìràn Odùduwà ní ní ìkáwọ́. Díẹ̀ lára wọn ni iyán, ọkà, ẹ̀kọ, mọ́ínmọ́ín àti gúgúrú.

Àwọn Ìwé Ìtókasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Adeoye, C.L. (1979): Àṣà àti Ìse Yorùbá, Oxford University Press.

Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Èdè Yorùbá, Ilé-Ẹ̀kọ́ Gíga ti Àwọn Olùkọ́ni Àgbà tí ó jẹ́ ti Ìjọba Àpapọ̀ ní Osíẹ̀lẹ̀, Abẹ́òkúta (2005): Ọgbọ́n Ìkọ́ni, Ìwádìí àti Àṣà Yorùbá.

  • Olatunji, O.O. (2005): History, Culture and Language, Published fro J.F. Odunjọ Memorial Lecture, Series 5.
  • Opadotun Tunji, Ẹ̀kọ́ Èdè Yorùbá Fún Ilé-Ẹ̀kọ́ Olùkọ́ni Àgbà, Àkọ́jọpọ̀ Ẹ̀kọ́ Èdè Yorùbá.
  1. "Geography and Society". The Yoruba from Prehistory to the Present. Cambridge University Press. 2019-07-04. pp. 1–28. doi:10.1017/9781107587656.001. 
  2. "ORIGIN AND EARLY HISTORY". The History of the Yorubas. Cambridge University Press. 2010-09-30. pp. 3–14. doi:10.1017/cbo9780511702617.006. 
  3. "Yoruba states". Encyclopedia Britannica. 1998-07-20. Retrieved 2023-06-13. 
  4. Eze, Chinelo (2022-10-30). "Historical Places To Visit In Yorubaland". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Archived from the original on 2023-06-13. Retrieved 2023-06-13.