Jump to content

Ife

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ife

C.O. Odejobi

Ifẹ̀ láti ọwọ́ C.O. Ọdẹ́jọbí, DALL, OAU, IFẸ̀ Nigeria.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aṣiwájú nínú ìmọ̀ ni wọ́n ti sọ ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ Ifẹ̀. Bákan náà Johnson1, Gugler, àti Flanagan2 tó fi mọ́ Fáṣọgbọ́n3 sọ ìtàn Ifẹ̀ nínú iṣẹ́ wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí, ọ̀nà méjì ni ìtàn Ifẹ̀ pín sí. Èkíní jẹ mọ́ ìgbàgbọ́ nípa pé láti ìpilẹ̀sẹ̀ ni Ifẹ̀ ti wà. Ìtàn kejì ni èyí tí ó sun jáde láti ara Odùduwà1. Ìtàn àkọ́kọ́ ni ti Ifẹ̀ Oòdáyé2 Ìtàn ìwásẹ̀ náà sọ pé Olódùmarè pe àwọn Òrìṣà láti lọ wo ilé ayé wá nígbà ti ó fẹ́ dá ayé. Ó fún wọn ní èèpẹ̀ tí ó wà nínú ìkarahun ìgbín, adìẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún, àti ọ̀ga. Nígbà tí wọ́n dé ilé ayé, wọ́n rí i pé omi ní ó kún gbogbo rẹ̀, àwọn òrìṣà da eèpẹ̀ tí Ooódùmarè fún wọn sí orí omi náà, adìẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún sì tàn án. Bí adìẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún ṣe ń tan ilẹ̀ yìí bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ ń fẹ̀ sí i èyí náà ló bí orúkọ Ifẹ̀.

Ìtàn kejì ni pé láti ìlú mẹ́kà ni Lámurúdu tí ó jẹ́ baba Odùduwà ti wá sí Ifẹ̀. Ogun Mohammed tí ó jà láàrin kèfèrí àti mùsùlùmí ìgbà náà ló ká Lámúrúdu mọ́. Èyí ti Lámurúdu ìbá fi gbà, ó fi ìlú Mẹ́kà sílẹ̀, ó sì tẹ Ifẹ̀ dó.3 Lẹ́yìn ikú Lámurúdu ni Odùduwà gba Ipò. Ilé Ọ̀rúntọ́ ti wà ní Ifẹ̀ kí Lámurúdu tó dé. àwọn ará ilé Ọ̀rúntọ́ ni ó gba Lámurúdu àti Odùduwà ní àlejò4. Àwọn ará ilé Ọ̀rúntọ́ gbà fún Odùduwà láti jẹ́ olórì wọn nítorì pé alágbára ni.

Ìtàn ti akọkọ yìí ló sọ bí Olódùmarè ṣe ran àwọn oriṣa láti wá dá ayé. Lẹ́yìn tí àwọn oriṣa dá ayé tan, ti wọ́n sì ti ń gbé ibẹ̀ ni Odùduwà tó wá sí Ile-Ifẹ̀ láti ìlú Mẹka. Abẹ́nà ìmọ̀ itan kejì yìí tilẹ̀ fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé Lámurúdu àti Odùduwà bá àwọn kan ni Ilé-Ifẹ̀ nígbà ti wọ́n dé Ifẹ̀. Ohun tí èyí èyí ń fi yé wa nip é nibi tí ìtàn akọkọ parí si ni ìtàn kejì ti bẹrẹ.

Àkíyèsí: A yọ iṣẹ́ yìí láti inú àpilẹ̀kọ Ẹ́meè C.O. Ọdẹ́jọbí .