Èdè Nupe
Appearance
Nupe | |
---|---|
Sísọ ní | Nàìjíríà |
Ọjọ́ ìdásílẹ̀ | 1990 |
Agbègbè | Ìpínlẹ̀ Niger, Ìpínlẹ̀ Kwárà, Ìpínlẹ̀ Kogí, Agbègbè Olúìlú Ìjọba Àpapọ̀ Abùjá |
Ẹ̀yà | Àwọn Nupe |
Ìye àwọn afisọ̀rọ̀ | 800,000 |
Èdè ìbátan | |
ìsọèdè | Nupe Tako (Bassa Nge)
|
Àwọn àmìọ̀rọ̀ èdè | |
ISO 639-3 | nup |
Èdè Tápà (tàbí Nupe, Nupenci, Nyinfe, Anufe) jẹ́ èdè ní Nàìjíríà (ní Ìpínlẹ̀ Niger, Kwárà, Kogí, Èkìtì, àti Agbègbè Olúìlú Ìjọba Àpapọ̀ Abùjá).[1]
Ìró Ohùn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Èdè Tápà jẹ́ èdè oníròó ohùn, ìró ohùn márùn-ún ló wà. Wọ́n fi àmì ohùn sórí fáwẹ́lì láti fi ìró ohùn sílébù kan hàn.
Ìró ohùn | Àmì ohùn |
---|---|
Ìró ohùn òkè | (´) àmì ohùn òkè |
Ìró ohùn àárín | kò sí àmì ohùn |
Ìró ohùn ìsàlẹ̀ | (`) àmì ohùn ìsàlẹ̀ |
Ìró ohùn ẹlẹ́yọ̀ọ́ròkè | (ˇ) àmì ohùn ẹlẹ́yọ̀ọ́ròkè |
Ìró ohùn ẹlẹ́yọ̀ọ́rodò | (ˆ) àmì ohùn ẹlẹ́yọ̀ọ́rodò |
Fọnẹ́tíìkì
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Fáwẹ́lì àìránmúpè márùn-ún ló wà nínú èdè Tápà: /a, e, i, o u/. Bákan náà ni fáwẹ́lì aránmúpè mẹ́ta ló wà: /ã, ĩ, ũ/.[2]
Afèjìètèpè | Afiyínfètèpè | Àfèrìgìpè | Afàjàfèrìgìpè | Afàjàpè | Afàfàsépè | Afàfàséfètèpè | Afitánnápè | ||
---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|
Aṣẹ́nupè | àìkùnyùn | p | t | k | kp /k͡p/ | ||||
akùnyùn | b | d | g | gb /ɡ͡b/ | |||||
Affricate | àìkùyùn | ts /t͡s/ | c /t͡ʃ/ | ||||||
akùnyùn | dz /d͡z/ | j /d͡ʒ/ | |||||||
Àfúnnupè | àìkùnyùn | f | s | sh /ʃ/ | h | ||||
akùnyùn | v | z | zh /ʒ/ | ||||||
Aránmúpè | m | n | |||||||
Àséèsétán | l | y /j/ | w | ||||||
Aréhọ́n | r |
Ìsọ̀rí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ẹ̀rí ti onímọ̀ èdè fi hàn pé èdè Tápà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka èdè Tápà ti ẹbí Bẹ́núé-Kóńgò. Ìgbìrà, Gbari àti Gade jẹ́ èdè mìíràn tó wà nínú ẹ̀ka yìí. Èdè àdúgbò Tápà tó nǹkan bí méjì ló wà: Tápà àárín gbùngbùn àti Nupe Tako.[3]
Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Ethnologue report on Nupe-Nupe-Tako
- PanAfriL10n page on Nupe
- Takada nya Aduwa nya Eza Kama kendona zizi nya Anglican Church yi na Portions of the Book of Common Prayer in Nupe.
Àwọn ẹ̀yà abínibí ilẹ̀ Naijiria | |
---|---|
- ↑ Project, Joshua (2014-11-01). "Nupe in Nigeria". Joshua Project. Retrieved 2023-06-14.
- ↑ "Nupe language, alphabet and pronunciation". omniglot.com. 2023-06-14. Retrieved 2023-06-14.
- ↑ "Nupe language". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2023-06-14.