Àwọn èdè Niger-Kóngò

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Niger-Kóngò
Niger–Kordofanian (obsolete)
Ìpínká
ìyaoríilẹ̀:
Sub-Saharan Africa
Ìyàsọ́tọ̀: one of the world's primary language families
Àwọn ìpín-abẹ́:
Katla (Kordofanian)
Rashad (Kordofanian)
Atlantic–Congo (noun classes)
ISO 639-2 and 639-5: nic
Niger-Congo.svg
Map showing the distribution of Niger–Congo languages (yellow). The area is divided into B (Bantu) and A (rest) to show the extent of the Bantu subfamily.

Àkójopò èdè tí a mò sí Niger-Congo dín mérin ni òjì-lé-légbéje. Grimes (1996) ríi gégé bíi èyí tí ó tóbi jùlo ní àgbáyé àti wí pé àwon èèyàn tí ó ń so òkan tàbí èkejì nínú. àwon èdè yìí fón ká orílè ayé ju àwon ìyókù akegbe won lo. Ní orílè èdè Afíríkà, àwon èdè tí ó ní èèyàn tí ó pò jùlo ni wón jé èyí tí a lè rí ní abé àkójopò èdè Niger-Congo. Bí àpeere, èdè tí ó tóbi jùlo ni Senegal, Wolof jé òkan lára àwon èdè Niger-Congo; Fulfude tí ó tàn káàkirí ìwò oòrùn àti àárín gbùngùn Afíríkà, okan níbè ni. Béè náà ni èdè Manding tí ó gbajú gbajà òpòlopò orílè èdè ní ìwò oòrùn Áfíríkà bí ó tilè jé pé onikaluku ni ó ní orúko tí ó ń pe èdè yìí, oun náà sì ni a mò sí Bambara tí ó jé èdè orílè èdè àti ìjoba Mali àti Dyala, èdè Okòwò gbalé-gboko. A kò gbodò gbàgbé Akan ní orílè èdè Ghana. Yorùbá àti Igbo náà kò gbéyìn níbè, èdè pàtàkì ni méjèèjì yìí ní orílè èdè Nàìjiria. Ní àárín gbùngbùn Áfíríkà, èdè Sango ni wón ń so. Àwon èdè Bantu bíi Ganda, Gikuyu, Kongo, Lingala, Luba-Kasari, Luyia, Mbundu (Luanda), Northern Sotho, Sukuma, Swahili, Tsonga, Tswana, Umbundu, Xhosa ati Zulu. Ó tó èèyàn bíi Mílíònù lónà otà-lé-lóòdúnrún sí Mílíònù irínwó tàbí jù béè lo tí wón ń so èdè Niger Congo ní Áfíríkà, gégé bí Grimes (1996) se so.

ISÉ ÌWÁDÌÍ LÓRÍ ÌPÍN ÈDÈ NIGER-CONGO

Okan gbòógì lára àwon èdè tí a rí lára ìpín èdè Niger-Congo ni àkójopò èdè Bantu jé. Àwon èdè yìí gbale tààrà ní ilè Áfíríkà, wón sì jora gidi. Ní abé gírámà re, a ríi wí pé àwon òrò orúko inú àwon èdè yìí jora gan-an, èyí ni ó sì mú àwon onímò tí ó jé aláwò funfun fi ara balè se isé ìwádìí ní orí àwon èdè wònyí. Koelle àti Bleek so wí pé òpòlopò èyà èdè tí àwon ènìyàn ìwò oòrùn Áfíríkà ń so ni ó ní òrò orúko tí a sèdá nípa àfòmó ìbèrè. Nínú ìwádìí tirè, Meinhof sa awon èdè kan jo tí wón fi ara pé ara won láti ara òrò orúko won sùgbón tí gírámà won yàtò díè. Èyí ni òún pè ní ‘Semi-Bantu’. Westerman se isé tí ó jo mó ti Meinhof díè. Ní tirè, ó se ìpìnyà láàrin àwon èdè tí ó farahàn ní ìlà-oòrùn àti ìwò-oòrùn ilè Sudan. Ó se àkíyèsi àwon èdè kan tí a rí ní apá ìwò oòrùn ilè Sudan; àwon náà ni ó pín sí ìsòrí méfà: Kwa, Benue-Cross, Togo, Gur, Mandingo, àti ti ìwò oòrùn Àtìláńtíìkì. Òpòlopò sílébù nínú àwon èdè wònyí ni wón jé ‘CV’. Greenberg yapa díè nínú èrò ti rè. Ó se àtúnpín àwon èdè wònyí láàrín odún 1949 sí 1954. Ní tirè, ó pín Bàntú àti ìwò oòrùn Sudan sí ònà kan soso tí ó pè ní Niger-Congo, ó sì se àdáyanrí ìlà oòrùn Sudan sí ìsòrí mìíràn òtò, ó pè é ni Nilo-Saharan. Isé rè sì fi ara pé ti Westerman tààrà ní abé ìsòrí yìí. Àwon kókó inú isé Greenberg ni ìwònyí:

(a) Orúko Mandigo yí padà sí Mande

(b) Àárín gbùngbùn Togo di ara Kwa

(d) Benue-Cross yí padè di Benue-Congo

(e) Bantu di ìsòrí kan lábé Benue-Congo

(e) Fulfude di ara ìsòrí ìwò oòrùn Àtìláńtíìkì; Serer àti Wolof sì di ara kan náà pèlú fulfude.

(f) Adamawa kún àkójopò èdè yìí


(g) Ní odún 1963, Kordofanian kúrò ní èdè Kòtó-n-kan ó di ògbà kan náà pèlú Niger-Congo. Orúko wá yí padà, ó di Niger-Kordofanian (tàbí Congo-Kordofanian).

Greenberg fura sí ipe èdè àwon èdè wònyí, ó sì tóka síi wí pé /ףּ/. Kordofanian ati /m/ Niger-Congo jo ara won. Èyí sì máa ń jeyo dáadáa nínú àwon àfòmó ìbèrè àti àwon òrò Kòsemánìí kan nínú àwon èdè yìí. Léyìn Greenberg ni Mukarovsky se àtúpalè àti àtúnpín àwon èdè yìí, Ó yo Kordofanian, Mande, Wolof-Serer-Fulfulde, Ijoid àti Adamawa kúrò níbè; àwon ìyókù ni ó sì pè ní ‘Western Nigritic’. Ayé sí téwó gba isé yìí gan-an ni láàrín àwon olùwádìí ìjìnlè. Àtúnse gbòógì wáyé láti owo Bennett àti Sterk (1977), Wón fi ojú lámèyító wo àwon òrò orúko tí ó fara jo ara won nínú àwon èdè wònyí. Ìgbàgbó won ni wí pé Kordofanian àti Mande ti yà kúrò lara won. Léyìn èyí ni ìwò oòrùn Àtìláńtíìkì yà kúrò lára ìsòrí èdè yìí tí a sì fún àwon tí ó kù ní orúko ààrín gbùngbùn Niger-Congo. Ara àwon wònyí ni Ila-oòrùn Adamawa, Gur, Kru àti Ijo wà. Òkan gbòógì isé lórí ìwádìí yìí ni The Niger-Cong Languages (Bender – Samuel 1989) jé. Àgbékalè ìsòrí èdè Niger-Congo gégé bí a ti mo lónìí ni a se àte rè sí ìsàlè yìí (Boyd 1989) nípa lílò àlàyé fún òkòòkan won.


Nínú ate yìí a rí, ‘Proto-Niger-Congo’ nínú èyí tó jé wí pé ‘Kordofanian’ ni ìsòrí àkókó tí ó kókó yapa. Mande àti iwo oòrùn Atlantic ni ìsòrí kejì tí ó tún yapa béè, èyí tí wón fi hàn wá lábé ‘Proto-Mande-Atlantic-Congo’. Àwon èyí tí ó tún dàbí rè ni àwon tí wón pín sí abé ìsòrí ààrín gbùngbùn Niger-Congo. Láti ara ‘Proto-Ijo-Congo’ ni ‘Ijoid’ ti yapa, lábé rè ni a tí rí Ijo ati Defaka. Lábé ‘Proto-Ijo-Congo’, a rí ‘Proto-Dogon-Congo’ èyí tí Dogon yapa láti ara rè. Lábé ‘Proto-Dogon-Congo’, a rí ‘Proto-Volta-Congo’ tí ó pín sí ìwò oòrùn Vota-Congo àti ìlà oòrùn Volta Congo (Proto-Benue-Kwa). Ní a pá ìwò oòrùn Volta-Congo ni a ti wá rí Kru, Pre, Senufo; ààrin gbùngbùn Gur àti Adawawa (Bikirin, Day, Kam ati Ubangi). A lè pè é ní Gur-Adamawa. Ní apá ìlà oòrùn, ni a ti rí ààrín gbùngbùn orílè èdè Nìjíríà tí òhun náà tún yapa, a sì rí Bantoid Cross lábé Ìlà oòrùn yìí. Lára Bantoid Cross yìí ni Cross River ti yapa, nígbà tí a wa rí Bantoid lábé Bantoid Cross.

KORDOFANIAN

Ní agbègbè orí òkè Nuba ní orílè èdè Sudan ni àwon ènìyàn tí ó n so èdè yìí wópò sí jùlo bí ó tilè jé pé Ogun àti òtè ti fón òpòlopò àwon ènìyàn yìí ká. Àte ìsàlè yìí ni ó se àkójopò àwon ìsòrí èdè tí ó wà ní abé ori èdè Kordofanian.

Nínú àte yìí a rí ‘Proto-Kordofanian’ tí ó pín sí ìsòrí mérin òtòòtò: Heiban, Tahodi, Rashad, Katla. Heiban pín sí Ìlà Oòrùn (Ko, Warnang); ààrín gbùngbùn (Koalib, Logol, Laru, Ebang, Utoro); lààrín ‘Central àti west’ a rí shirumba; Ní ìwò oòrùn (Tiro àti Moro). Talodi: lábé Tolodi, a rí Ngile (Masakin) àti Dengbebu, Tocho, Jomang, Nding, Tegem. Rashad: lábé rè ni Tagoi àti Tagali wà. Katla: lábé rè ni kalak (Katla) àti Lomorik (Tima).

MANDE

Ìwò oòrùn Áfíríkà ni àwon ènìyàn tí ó ń so èdè yìí Sodo sí jùlo. Àwon ìhú tí a sì ti rí àwon tí èdè won pèka láti ara orí èdè yìí ni Mali, Cote d’Ivoire, Sierra Leone, Liberia, Burkina Faso, Senegal, Gambia, Guinea Bissan, Mauretania, Banin, Ghana, Togo ati Nigeria (Dwyer 1989; Kastenholz 1991/2). Ó tó ènìyàn bíi mílíònù méwàá sí méjìlá tí wón ń so ó.

Nínú àte yìíu a rí ‘Proto-Mande’ tí ó pín sí ìwò oòrùn àti ìlà oòrùn ní ìbèrè pèpè. A wá rí ìwò oòrùn fúnrarè tí ó tún wá pín sí ààrín gbùngbùn tàbí Gúúsù-ìwò oòrùn àti Àríwá ìwò oòrùn. Láti ara ààrín gbùngbùn tàbí Gúúsù-ìwò oòrùn ni a ti rí: Mandaing ati Koranko, Vai àti Kono, Jogo (Ligbi, Nnmu, Atumfuor, Wela) àti Jeri, Sooso àti Yalunka, Kpelle, Loomu, Bandi, Mande ati Loko. Láti ara àríwá-ìwò oòrùn ni a ti rí Sorogama àti Tieyaxo, Tiema Cewe, hainyaxo, Soninke (Azer), Bobo (Sya), Dzuun (Samogo-Guan) àti Sembia, Jo (Samogo-Don). Ní ìlà Oòrùn a rí : Mano, Dan (Yakuba, Gio) àti Tura (Wen), Guro (Kweni) àti Yanre, Mwa àti Wan (Nwa), Gban àti Beng (Gan). Bákan náà, ni a rí: Bisa, Sane (Samogo-Tongan, Maya) àti San(South Samo, Maka), Busa (Bisa, Boko), Shanga àti Tyenga.

Oju-iwe Keji[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

ÀTÌLÁŃTÍÌKÌ

Gégé bí orúko rè ti fi ara hàn ìwò oòrùn Áfíríkà, ní èbá òkun Àtìláńtíìkì ni èdè yìí sodo sí jùlo. Ó fónká láti enu odò Senegal títí dé orílè èdè Liberia. Díè lára àwon èdè tí ó pèka sí abé orí èdè yìí ni a ti rí: Fulfulde, Wolof, Diola, Serer àti Remne. Sapir (1971) ni ó se àgbékalè àte ìsàlè yìí: Fig 2.4. Nínú àte yìí a rí ‘Proto-Atlantic’ tí ó pín sí Àríwá àti Gunsu. Ní àríwá ni a ti rí Fulfulde àti Wolof, Serer, Cangin, Diola ati Pupel, Balanta, Bassari/Bedik ati Konyagi, Biafada/Pajade, Kobiana/Kasanga àti Banyin, Nalu, Bijago(Proto-Atlantic), Sua, Temne, Sherbro àti Gola, Limba. IJOID Apá gúúsù ilè Nigeria ni a ti rí àwon tí wón ń so èdè yìí. Èdè náà ni a mò sí Defaka àti Ijo. Jenewari àti Williamson (1989) ni wón se àgbékalè àte isálè yìí Fig 2.5. Nínú àte yìí, a rí ‘Proto-Ijoid’ tí ó pín sí Defaka ati Ijo. Ijo pín Ìlà-oòrùn àti ìwò oòrùn. Lábé ìlà-oòrùn ni a ti rí: Nkoro, Ibani, Kalabari, Kirike (Okrika), Nembe ati Akaha(Akassa). Lábé ìwò-oòrùn ni a ti rí : Izon, Biseni, Akita (Okordia), Oruma.

DOGON

Àwon ènìyàn bíi ìdajì mílíònù tí a bá pàdé ní ilè Mali àti Burkina Faso ni wón n so èdè yìí. Bendor-Samuel àti àwon ìyókù (1989) ni ó gbé àte yìí kalè. Fig 2.6. Ínú àte yìí, a rí ‘Proto Dogon’ ti o pín si ìsòrí mefa. Àwon ìsòrí náà nìwòn yìí (a) Plain - Jamsay tegu, Toro teju, Tene ka, Tomo ka (b) Escarpment - Toro soo, Tombaco soo, Kamba soo (d) West - Dulerí dom, Ejenge dó (e) North west - Bangeri Me (e) North Platean - Bondum dom. Dogul dom (f) Ìsòrí kefà ni Yanda dom, Oru yille àti Naya tegu.

ARIWA VOLTA-CONGO Kru, Gur àti Adamawa-Ubangi ni àwon èka èdè tí a lè rí ní abé ìsòrí ‘ARIWA VOLTA-CONGO’ bí ó tilè jé wí pé àwon èdè yìí ti fónká orílè KRU Orílè-èdè Cote d’Ivoire àti Liberia ni a ti lè rí àwon ènìyàn tí wón ń so èdè yìí. Ó tó ènìyàn bíi mílíònù kan sí méjì tí wón ń so èdè yìí. Tí a bá wo àte ìsàlè yìí, a ó se alábápàdé àwon èdè bíi Kuwaa, Tiegba, Seme àti béè béè lo lára orí èdè ‘Kru’. Fig 2.7. Nínú àte yìí a rí ‘Proto-Kru’ tí ó pín sí ìsòrí méta. Àwon ìsòrí náà nìwòn yìí (a) Ìlà-oòrùn - Godie àti Kouya, Dida, Kwadia, Bakwe ati Wane. (b) Ìwò-oòrùn - Grebo complex, Guere complex, Bassa, Klao (d) Ìsòrí kéta ni àwon bíi Kuwaa, Tiegba, Abrako, Seme. GUR Èdè yìí gbajú gbajà dáadáa àti wí pé òpò ènìyàn ni ó ń so èdè yìí ní orílè ayé. A lè rí àwon ènìyàn tí wón ń so èdè náà ní orílè èdè bíi Cote d’Ivoire Ghana, Togo, Benin, Burkina Faso àti Nigeria. Ó tó èèyàn bíi mílíònù márùn-ún ati àbàbò tí wón ń so èdè yìí gégé bí Manessy 91978) ti se ìwádìí rè. Fig 2.8. Nínú àte yìí a rí ‘Proto Gur’. Ní ìbèrè pèpè ó pín sí:- Ààrin gbùngbùn Proto; Kulango àti Loron (Proto-Gur); Viemo, Tyefo, Wara-Natioro, Baatonum, Win (Toussian). Ààrin gbùngbùn Proto: eléyìí tún wà pín sí ìsòrí meji pere: Àríwá àti Gúúsù. Lábé àríwá, a rí : Kurumfe, Bwamu Buli-Konni, Ìlà-oòrùn Oti-Volta, Iwò-oòrùn Oti Volta, Gurma, Yom-Nawdm. Lábé gúúsù, a rí: Lobi àti Dyan, Kirma àti Tyurama, Ìwò-oòrùn Gurunsi, ààrin gbùngbùn Guruusì àti Ìlà-oòrùn Guruusi, Dogose àti Gan.


ADAMAWA-UBANGI Èdè tí ó gbòòrò ni èdè Adamawa-Ubangi. Ipèka rè bèrè láti apá Gúsù-Ìwò oòrùn Nàìjíríà títí dé Àríwá-Ìwò oòrùn Sudan. Àpapò iye àwon tí ó ń so èdè Adamawa tó mílíònù kan àti ààbò-Crozier àti Blench (1992); Grimes (1996). Mílíònù méjì lé légbèrún lónà òódúnrún ni Barreteau àti monino (1978) tóka sí gégé bí àwon tó ń so èdè Ubangi. Èyí túmò sí pé àpapò àwon tí ó ń so èdè Adamawa-Ubangi ní ìbèrè pèpè jé mílíònù mérindín ní egbàá lónà ogórùn-ún láì ka àwon tí ó ń so èdè Sango mó o. Fig 2.9. Nínú àte yìí a rí ‘Proto-Adamawa-Ubangi’ tí ó pín sí ònà méjì ní ìbèrè àpeerè. (a) Adamawa (b) Ubangi Adamawa - eléyìí tún pín sí àwon àwon ìsòrí mìíràn bíi: Leko, Duru, Mumuye/Yendang ati Nimbari; Ubum, Bua, Kim, Day; Waja, Longuda, Jen, Bikwin, Yungur. Bákan náà ni a rí: Ba (Kwa), Kam, Fali. Ubangi - Gbaya; Banda, Ngbandi, Sere, Ngbaka àti Mba; Zande.

SOUTH VOLTA-CONGO Bennett ati Sterk (1977) pe ‘South Volta-Congo ni ààrin gbùngbùn àríwí Niger-Congo. Atótónu wáyé nípa yíyapa tí ó wá yé láàrin Kwa àti Benue Congo nítorí pé wón sún mó ara won pékípékí-Greenberg (1963). Pàápàá jùlo yíyapa láàrin èdè kwa, Gbe àti Benue –Congo: Bennett àti Sterk (1977) àti síse àtúnse. Kranse (1895) ni ó se ìfihàn orúko ‘Kwa’ fún ayé. Bíi mílíònù lónà ogún ni Grimes (1996) fi yé wa wí pé ó ń so èdè náà. Greenbery (1963a) pín-in sí ìsòrí méjo, ó sì so àwon èdè ààrin gbùngbùn Togo po mo ìsòrí tirè. Stewart 1994 ni o se àgbékalè àte ìsàlè yìí. Fig 2.10. Nínú àte yìí a rí ‘Proto-Kwa’ tí ó pín sí ìsòrí méfà ni ìbèrè pèpè. Àwon ìsòrí náà nìwòn yìí: (a) Ega, Avikan ati Alladian, Ajukru, Abidji, Abbey, Attie (b) Potou Tano (d) Ga ati Dangme (Proto-Kwa) (e) Na – Togo (e) Ka – Togo (f) Gbe

Òpòlopò àwon ìsòrí wònyí ni o tún jé àtúnpín sí ìsòrí mìíran bí àpeere :- Potou-Tano, Na-Togo, Ka-Togo, Gbe. Potou-Tano: èléyìí pín sí Potou àti Tano.

Lábe Potou ni a ti rí Ebríe àti Mbatto 

Tano – eléyìí pín sí ìsòrí mérin. (a) Krobu (b) Ìwò-oòrùn Tano: Abure, Eotilé (d) Ààrin gbùngbùn Tano: Akan, Bia (Nzema-Ahanta) àti (Anyi, Banle, Anufo). (e) Guan – O tun pín si Gúúsù níbi ti a ti rí Efutu –Awutu ati Larten-Cherepong-Anum. Bákan náà ni Àríwá Guang. Na-Togo:- Ó pín sí Lelémi – Lefana, Akapatu-Lolobi, Likpe, Santrokofi; Logba (Na Togo); Basila, Adele. Ka-Togo ;- Ìsòrí eléyìí pín sí Avatime, Nyangbo-Tafi; Kposo, Ahlo, Bowiri (Ka-Togo); Kebu, Animere. Gbe :- Lábé èyí ni a ti rí: Ewe ati Gen/Aja, Fon-Phla-Phera

BENUE CONGO Èka méjì òtòòtò ni èdè yìí ni: Ìwò-oòrùn àti Ìlà oòrùn Benue-Congo. Àwon orílè èdè púpò ni ó ní àwon èèyàn tí wón ń so èdè yìí, ó sì sodo sí apá gúúsù ilè Nigeria dáadáa. Béè náà ni ìlú bíi Cameroon, Congo, CAR, DRC, Tonzania, Uganda, Kenya, Mozambique, Angola, Rwanda, Burundi, Namibia, Zambia, Malawi, Zimbabwe, Gabon, Lesotho, Samalia àti àwon èdè yìí kalè. Gégé bí Grimes (1996) se wádìí rè, èdè Yorùbá àti Igbo ni ó tóbi jùlo nínú èka èdè tí a pè ní Benue-Congo, ìsòrí ìwò oòrùn Benue-Congo ni ó sì pín àwon èdè wònyí sí. Àte náà nìyí. Fig 2.11. Nínú àte yìí a rí ‘Proto-Benue-Congo’ ti o pín sí ìsòrí meji pàtàkì.

(a) Ìwò oòrùn Benue Congo

(b) Ìlà oòrùn Benue Congo

Ìwò oòrùn Benue Congo:- Ó pín sí YEAI (Yoruboid, Edoid, Akokoid, Igboid); Akpes; Ayere-Ahan; NOI (Nupoid, Oko, Idomoid). Ìlà oòrùn Benue Congo :- Ó pín sí ìsòrí méta pàtó.

(a) Àárín gbùngbùn orílè-èdè Nàìjíráà:- Ó pín sí: Kainji, Àríwá-Ìwò Plateane, Beromic, Àárín gbùngbùn Plateane, Ìlà-oòrùn Gúúsù Plateane, Tarok, Jukunoid.

(b) Ukaan

(d) Bantoid-Cross:- Lábé èyí ni Bantoid ti yapa. Nígbà tí a sì rí Cross River ní abé Bantoid-Cross. Láti ara Cross River ni Bandi ti wá yapa. Nígbà tí a wá rí Delta-Cross lábé Cross River.

Ní ìparí, ó fihàn gbangba wí pé èdè Niger-Congo tóbi tààrà àti wí pé orílè èdè Áfíríkà ni ó pèka sí òpò nínú àwon èdè yìí ni ó gbalè lópòlopò sùgbón a rí lára won tí ìgbà ti férè tan lórí won. Àwon wònyí ni èdè mìíràn ti fé máa gba saa mo lowo Àwon ìdí bíi, òsèlú, ogun, òlàjú àti béè béè lo ni ó sì se okùnfà èyí. Ní pàtàkì jùlo, gbogbo èdè yìí náà kó ni àwon Lámèyító èdè fi ohùn se òkan lé lórí lábé ìsòrí tí wón wa sùgbón òpòlopò ni ‘ebí’ re fi ojú hàn gbangba. Ní ìparí, òpòlopò àwon òmòwé ni wón ti se isé ìwádìí lórí rè sùgbón ààyè sì tún sí sílè fún àwon ìpéèrè túlè láti se isé ìwádìí àti lámèyító lórí èkà èdè Niger-Congo.


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]