Ìjòyè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ìjòyè nílẹ̀ Yorùbá túmọ̀ sí àwọn ènìyàn péréte kan tí wọ́n ma ń ṣe ìṣàkóso ìjọba ìlú pẹ̀lú Ọba tí ó jẹ́ aláṣe pátápátá lórí gbogbo ìlú àti Ìgbìmọ̀ àwọn Ìjòyè.[1]

Oyè jíjẹ gẹ́gẹ́ bí ogún ìdílé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Ìjòyè kọ̀ọ̀kan ni wọ́n jẹ́ aṣojú ìdílé kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ti jáde wá. Ìdílé kọ̀ọ̀kan tí Ìjòyè kọ̀ọ̀kan ń ṣojú fún ni wọ́n ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin ìlú láti yan ọmọ oyè tí yóò bá Ọba tukọ̀ ìlú. [2]

Orúkọ àwọn oyè pàtàkì[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀tún Oloye Ọ̀tún gẹ́gẹ́ orúkọ oyè rẹ̀ ni ó ma ń wà ní apá ọ̀tún ìtẹ́ Ọba, tí yóò sì ma ṣàkóso ìlú nígbà tí Ọba kò bá sí nile. Oyè yí lò sábà Ma ń jẹ́ oyè ìdílé, àyà fi tí Ọba bá fínú-fíndọ̀ yan ẹnìkan sipò yí gẹ́gẹ́ bí oyè ìdáni lọ́lá nígbà tí a kò bá ti rí ẹbí kan tí wọ́n ti ń jẹ̀ irúfẹ́ẹ́ oyè bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀. [3]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Lloyd, P. C. (2012-08-21). "The Yoruba Lineage - Africa" (in fr). Africa 25 (3): 235–251. doi:10.2307/1157104. ISSN 1750-0184. JSTOR 1157104. 
  2. Lloyd, P. C. (1955). "The Yoruba Lineage". Africa: Journal of the International African Institute 25 (3): 235–251. doi:10.2307/1157104. JSTOR 1157104. 
  3. Okion Ojigbo, Anthony (1973). "Conflict Resolution in the Traditional Yoruba Political System." (in fr). Cahiers d'Études Africaines 13 (50): 275–292. doi:10.3406/cea.1973.2712.