Ṣàngó

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí

Ṣàngó Olukoso, Oko Oya.

Ṣàngó Je Okan lara Awon Orisa ti awon yorùbá n bò wọ́a ni àjànàkú kojá a morí nnkan fìrí, bí a bá rí erin, káwípe a rí erin ní òrò Ṣàngó jé láàárin àwon òrìsà ilee Yorùbá. Ṣàngó jé òrìsà takuntakun kan gbòógì láàárín àwon òrìsà tókù ní ilèe Yorùbá. Ó jé orisà tí ìran rè kún fún ìbèrù. Ìrísí, ìṣe àti ìsọ̀rọ̀ rẹ̀ pàápàá kún fún ìbèrù nígbàtí ó wà laaye nítorípé ènìyàn la gbọ́ pé Ṣàngó jẹ́ télè kí ó tó di òrìṣà àrá. Ìtàn so wí pé omo Òrányàn ni sàngó i ṣe àti pé Oya, Òṣun ati Obà jẹ́ ìyàwó rẹ̀.

Ìhùwàsí búburú ati dídá wàhalá ati ìkolura pèlú ìjayé fàmílétè-kí-n-tutó pò lówó sàngó gégé bí Oba tó bẹ́ẹ̀ títí ó fi di òtéyímiká, èyí jásí wí pé tọmọdé tàgbà dìtè mó o. Wón fi ayé ni í lára. Ó sì fi ìlú Òyó sílè nígbèyìn-gbéyín. Ó pokùnso sí ìdí igi àyàn kan lébà ònà nítòsí Òyó nígbàtí Oya: Ìyàwó rẹ̀ kan tókù náà sì di odò.

Ogbón tí àwon ènìyàn sàngó tókù dá láti fi bá àwon òtá rè jà nípa títi iná bolé won àti béèbéè lo ni ó so sàngó di òrìṣà tí wọ́n ń bo títí dòní tí wón sì ńfi enu won túúbá wí pé sàngó kò so: Oba koso.

ÀWON ORÚKO TÍ SÀNGÓ Ń JÉ

Oríṣiríṣi orúko ni a mọ sàngó sí nínú èyí tí gbogbo won sì ní ìtumò tàbí ìdí kan pàtó ti a fi ńpè wọ́n béè. Àwon orúko bíi ìwònyìí:

1. Olúkòso: Ẹnití a mò mọ́ kòso tàbí oba tí ó wolè sí kòso.

2. Arèkújayé:

3. Àjàlájí:

4. Ayílègbe Òrun:

5. Olójú Orógbó: nítorípé orógbó ni obì tirè, òun ni ó sì máa ń ṣàféérí nígbà ayé rè. Orógbó náà sì ni a máa ń lo ní ojúbo sàngó títí di òní.

6. Èbìtì-àlàpà-peku-tiyètiyè: Òrìṣà tí ó máa ń fi ìbínú gbígbóná pa ènìyàn ni àpalàyà tàbí àpafòn.

7. Onibon òrun: gégé bí òrìsà ó ń mú kí àrá sán wá láti ojú òrun pèlú ìrókèkè tó lágbára.

8. Jàkúta: gégé bí òrìṣà tí ń fi òkúta jà (edùn àrá). Irúfẹ́ òkúta kékeré kan tí ó máa sekúpa ènìyàn nípasẹ̀ sàngó

9. Abotumo-bí-owú: Òrìsà léè wolé pa ènìyàn bi eni pé erù ń lá ni ó wólu irú eni bẹ́ẹ̀.

10. Èbìtì-káwó-pònyìn-soro: Irúfẹ́ Òrìṣà tí ó jẹ́ wí pé ìṣowó-sekúpa asebi rẹ̀ máa ńya ènìyàn lénu gidigidi.

11. Alágbára-inú-aféfé: Òrìsà tí ó jé wípé owọ́jà a re, máa ńwá láti inú aféfé tàbí òfurufú ni.

12. Abánjà-májẹ̀bi: òrìṣà tíí jà láì ṣègbè léyìn aṣebi tàbí ṣe àṣìmú elòmíràn fún oníṣé ibi.

13. Lánníkú-oko-oya: Òrìsà tí o ni èrù iku níkàwó.

14. Òkokonkò èbìtì: Òrìsà tí ó le subú lu ènìyàn bii ìgànnán tí ó ti denukọlè.

15. Eléèmò: Òrìsà tí ó ni èèmò.

AWON IWE ITOKASI

1. Daramola Olu [1967] Awon Asa ati Orisa Ile Yoruba. Lati owo Olu Daramola ati jeje Adebayo

2. Adeoye C. L. [1985] Igbagbo ati Esin Yorùbá. Ibadan. Evans Brother. Press