Òrìṣà Agẹmọ

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Òrìṣà Agẹmọ jẹ́ òrìṣà tí a mú orúkọ rẹ̀ láti inú ọ̀rọ̀ "Akẹ́mọ" tí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tí a lè fi ṣàpèjúwe èni tí ó ma ńtọ́jú ọmọ. Òrìṣà Agẹmọ jẹ́ òrìṣà tí ó gbilẹ̀ láàrín àwọn ará Ìjẹ̀bú tí ó sì jẹ́ ohun tó so wọ́n pọ̀ gidi fún ìlọsìwájú ilẹ̀ Ìjẹ̀bú lápapọ. Wọ́n ma ń bọ òrìṣà Agẹmọ lọ́dọdún nínú oṣù Agẹmọ ìyẹn oṣù (Augus). [1]

Ìtàn bí Agẹ́mọ ṣe wọ ìlẹ̀ Ìjẹ̀bú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀pọ̀ ìtàn ló rọ mọ́ bí òrìṣà Agẹ́mọ ṣe dé ilẹ̀ Ìjẹ̀bú-Òde tí ó jẹ́ olú ìlú ìjọba fún gbogbo ilẹ̀ Ìjẹ̀bú. Apá ìtàn kan sọ wípé Olú-Ìwà, tí ó tẹ ilẹ̀ Ìjéú fó ni ó mú Agèmọ wó ilẹ̀ Ìjẹ̀bú ní ǹkan bí ọdún 900 A.D. Bí ìtàn náà ṣe só síwájú, Tami Onírè Aládésogun tí ó ṣèrìn àjò pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kan Olú-Ìwà àti àwọn amojú òrìṣà kan láti Waddai ní ilẹ̀ Sudan ní orílẹ̀-èdè Ijípítì. Wọ́n dé pélú àwọn ọmọ àti àwọn ẹrú pérete kan. Gẹ́gẹ́ bí Olùwá-Ìbẹ̀rù àti Abọrẹ̀ Obìnein Òjòwú pẹ̀lú Olóyè Ràsákì Oṣímodi, gbogbo wọn lápapọ̀ gba Ilé-Ifẹ̀ kọjá láti forí balẹ̀ fún Odùduwà, ṣìwájú kí wòn tó kúrò nílé-Ifẹ̀, Olú-Ìwà fi ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ Gborowo fún Odùduwà gẹ́gẹ́ bì ìyàwó tí ó sì bí ọmọ mẹ́ta fun. Lára àwọn ómọ tó bí fun ni ' Ogborogannida' tí ó oadà di Ọbanta; Lénúwà tí ó di Óba Òde Omi, àti Líken tì òun náàpadà di Ọba Ìwòpin létí Ọ̀sà.

Pàtàkì ọdún Agẹmọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Pàtàkì ọdún Agẹmọ ni ilẹ̀ Ìjẹ̀bú ṣe kókó sí àwọn ọmọ Ìjẹ̀bú nítorí wípé wọ́n gbàgbọ́ wípé lásìkò ọdún yìí, obìnrin tí ó vá ń wá ọmọ tí ó bá tọrọ ọmọ lọ́wọ́ òrìṣà Agẹmọ nínú ọdún náà yóò sì dọlọ́mọ láìpẹ́. Pàá pàá jùlọ òrìṣà náà yóò tún wúre fún gbogbo ìlú àti Ọba pẹ̀lú. Lára pàtàkì ọ̀dún Agẹmọ náà ni wípé àwón obìnri kìí fojú kàn án lásìkò tí ó bá jáde tàbí tí ó bá padàsí Ìgbàlẹ̀. Fúndìí èyí, àwọn obìnrin bẹ̀rù rẹ̀ gidi, nítorí agbára àti ẹ̀rù-jẹ̀jẹ̀ tí ó rọ̀ mọ́ọ. Agẹmọ jẹ́ òrìṣà pàtàkì tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ jùlọ láàrín àwọn ará Ìjẹ̀bú, bẹ́ẹ̀ sì ni ó sì wà tí tí dòní.

Àwọn ilẹ̀ Ìjẹ̀bù[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gbogbo ilẹ̀ ìjẹ̀bú tó fi mò Ìjẹ̀bú-Òde tì ó jẹ́ olú ìlú fún wọn tí wọ́n padà pín sí ìsọrí tí ó kó Ìjẹ̀bú Igbó, Ìjẹ̀bú Rẹ́mọ, Ṣàgámù, Ejìnrìn,Ìkòròdú, tó fi dé Ẹ̀pẹ́, Ìpẹru, Àgọ́ Ìwọ́yè, Lẹ́kkí, Ìṣarà, tó fi dé Kétu ní ilẹ̀ ilẹ̀ olómìnira Benin. Àwọn ìlú wọ́nyí ni ó wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọba Awùjalé ti ilẹ̀ Ìjẹ̀bú.

Àwọn ìtọ̀ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Onanuga, Adebisi (2014-09-23). "Why Ijebu love their Agemo". The Nation Nigeria. Retrieved 2019-03-19.