Ọ̀rúnmìlà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Ọ̀rúnmìlà
Wisdom, Knowledge, Ifa Divination, Fate, Destiny, Prophecy
Member of Orisha
Script error: The module returned a nil value. It is supposed to return an export table.
Other namesOrunmila or Orunmilá; Orúnla or Orúla or Agbonniregun
Venerated inYoruba religion, Umbanda, Candomble, Santeria, Haitian Vodou, Folk Catholicism
SymbolIfa divination
RegionNigeria, Benin, Latin America
Ethnic groupYoruba
ParentsAlayeru and Oroko

Orunmila tí amọ̀ gẹ́gẹẹ́ bí (Orúnmila, Orunmilá, Orúnla, tàbí Orúla ní ilẹ̀ Nàìjíríà àti Latin America) jẹ́ Òrìṣà. Ó jẹ́ òrìṣà Ọlọgbọ́n, Oníìmọ̀ , àti Alásọṣẹ, ìdí tí òrìṣà yí fi rí bẹ́ẹ̀ ni wípé ó nímọ̀ tó peregedé nípa ọmọnìyàn tí ó sì ń ṣe gbogbo ǹkan rẹ̀ ní ìlànà mímọ́., tí gbogbo ohun tó bá sọ kìí ṣaláì ṣẹ. [1][2][3]


Ìtàn Ọ̀rúnmìlà àti Lítíréṣọ̀ àtẹnudẹ́nu tó rọ̀ mọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀rúnmìlà gẹ́gẹ́ bí òrìṣà ìwáṣẹ̀ jẹ́ ọkan pàtàkì nínú àwọn òrìṣà tí ó lọ́wọ́ nípa dídá ayé, tí ó sì tún ti wàláti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé tí ó sì tún gbé pẹ̀lú ọàwọn ọmọ ènìyàn gẹgẹ́ bí olùmọ̀ràn tí ó sì tún ń ṣe àkóso tàbí àgbàwí láàrín ènìyàn àti Ẹkẹ́dàá wọn nígbà tí wọ́n bá tọ̀ọ́ wá láti ṣèbérè lorí ohun tó bá rú wọn lójú lọ́dọ̀ Babaláwo wọn. Ọ̀rúnmìlàni ó kọ́kọ́ wá sáyé gẹ́gẹ́ bí Babaláwo àkọ́kọ́ ní àwòrán ènìyàn tí ó sì kọ́ àwọn ní ifá dídá kí wọ́n lè má báa ní gbólóhùn nígbà tí ohun-jóhun kò bá fẹ̀ yé won. Ọ̀rúnmìlà ni ó jẹ́ ọlọgbọ́n àti àti onímọ̀ ìjìnlẹ̀ jùlọ láàrín àwọn òrìṣà tókù, tí ó sì ma ń sọ́ òkodoro bí kádàrá ẹni bá ti rí nípa sísọ àsọtẹlẹ̀ lórí ayé ẹni náà. Ìsí nìyí tí wọ́n fi ń kìí wípé:

" Igbákejì Olódùmarè àti

"Ẹkẹ́rìí ìpín" (witness of fate). Òun kan náà yí ló ṣagbátẹrù gbígbé Ifá (Ìmọ̀ Elédùmarè) wá sílé ayé. Àwọn olùsìn Ifá lọ́kùnrin ni a mọ̀ sí.[2] Babaláwo nígbà tì àwọn olùbọfá lóbìnrin jẹ́ Ìyá Onifá.[3]

Ọ̀rúnmìlà gẹ́gẹ́ bí ọ̀jọ̀gbọ́n, nìkan ni ó mọ ipọò tí Olódùmarè togẹ́gẹ́ bí Ori (intuitive knowledge) láàrín àwọn Orìṣà tókù, nítorí Orí nígbeni òrìṣà kìí gbànìyàn.[1][2][3]

Awo àti ìjọ́mọ awo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹni tó bá jẹ́ Ao nínú àlàkalẹ̀ gbọ́dọ̀ kọ́ kí ó sì nọ̀ gbogbo Odù Ifá Igba àti Mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (256), tí ó sì gbọ́dọ̀ má sọ àwọn ìtàn àti ìwúre tó bá Odù Ifá kọ̀ọ̀kan mu lẹ̀lú bí ó ṣe rí nígbà tí Ọrúnmìlà jọ́kọ́wá sáyé gẹ́gẹ́ bí òjìṣẹ́ Elédùà.[1][4][5]

Apá kan nínú Ìlànà ìgbaniwọlé gẹ́gẹ́ bí ọmọ awo ni wípé, ọmọ awo gbọ́dọ̀ jẹ̀ ọkùnrin nìgbà tí apá kejì wípé wọn le gba obìnrin náà gẹ́gẹ́ bí ọmọ Awo. Gbólóhùn ."Awo" jẹ́ tó níṣe pẹ̀lú àkọ àti abo ní ó bá ń kọ́ṣẹ Ifá dídá. Àwọn àríwísí ọlọ́kan-ò-jọ̀kan nípa ìṣakọ tàbí ìṣabo nínú ọmọ awo Ifá ni ó rọ̀ mọ́ ìtàn oríṣiríṣi tí a gbọ́ nípa Ifá fúnra rẹ̀. Ní Latin America àti àwọn apábibìkan ní West Africa, ohun tí a mọ̀ ni wípé Ọkùnrin nìkan ló lẹ jẹ Àràbà Ọ̀rúnmìlà, nígbà tí àwọn apá ibìkan ní West Africa bákan náà sọbwípé ipò yí náà tọ́ sí àwọn Obìnrin pẹ̀lú. Àwọn olùsifá gbàgbọ́ nínú ẹ̀mí takọ-tabo nítorí wípé akọ ń ṣẹ̀mí nítorí abo; bákan náà ni abo ń ṣẹ̀mi nítorí akọ ni . Fúndí èyí, kálukú wọn ló lẹ́tọ̀ọ́ sí jíjoyè nínú ẹgbẹ́ awo.[6]

Gbogbo ẹsẹ̀ Ifá pátá ni ó ní ó kọ̀ni nípa ìwà. Ìwà tí a ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yí, ni ó rọkiriká òfin ẹ̀sìn náà, rí ó sì tún jẹ́ ọkan pàtàkì nínú ìṣe ẹ̀dá láwùjọ àti níbi gbogbo , tíOlódùmarè gan yọ̀nú sí.[7]

Ẹ tún le wo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtọ́ka sì[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. 1.0 1.1 1.2 William R. Bascom: Ifa Divination: Communication Between Gods and Men in West Africa
 2. 2.0 2.1 2.2 Chief FAMA Fundamentals of the Yoruba Religion (Orisa Worship) ISBN 0-9714949-0-8
 3. 3.0 3.1 3.2 Chief FAMA Practitioners' Handbook for the Ifa Professional ISBN 0-9714949-3-2
 4. Adeoye, C. L. (1989). Ìgbàgbọ́ àti ẹ̀sìn Yorùba (in Yoruba). Ibadan: Evans Bros. Nigeria Publishers. pp. 285–302. ISBN 9781675098
 5. Bàbálàwó Ifatunwase Tratados Enciclopédicos de Ifá (Colección Alafundé), ISBN 978-0-9810387-04
 6. . 
 7. Ifaloju , Iwòrì Méjì: Ifá speaks on Righteousness, (an extract from S.S. Popoola, Ifa Dida, Library, INC) 2011

Àwọn ìwé àmúlọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]


 • Chief S. Solagbade Popoola & Fakunle Oyesanya, Ikunle Abiyamo: The ASE of Motherhood 2007. ISBN 978-0-9810013-0-2
 • Chief S. Solagbade Popoola Library, INC Ifa Dida Volume One (EjiOgbe - Orangun Meji) ISBN 978-0-9810013-1-9
 • Chief S. Solagbade Popoola Library, INC Ifa Dida Volume Two (OgbeYeku - OgbeFun) ISBN 978-1-926538-12-9
 • Chief S. Solagbade Popoola Library, INC Ifa Dida Volume Three (OyekuOgbe - OyekuFun) ISBN 978-1-926538-24-2
 • James J. Kulevich, "The Odu of Lucumi: Information on all 256 Odu Ifa"
 • Ayele Fa'seguntunde' Kumari, Iyanifa:Women of Wisdom ISBN 978-1500492892