Ajé
Ìrísí
Ajé jẹ́ òrìṣà tí Yorùbá gbàgbọ́ pé ó ṣẹ̀dá owó. Ajé jẹ́ orúkọ mìíràn tí Yorùbá máa ń pe owó. Láwùjọ Yorùbá, wọn a máa pe "owó" ní "ajé". Owó Ẹyọ ní Àrokò tí ó dúró gẹ́gẹ́ bí "Owó" tàbí "Ajé" láwùjọ Yorùbá. [1] [2]. Nílẹ̀ Yorùbá, wọ́n máa ń bọ Ajé gẹ́gẹ́ bí òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. [3]
Oríkì Ajé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ajé Káàárọ̀ Ajé olókun Ajé Ògúgúlúṣọ̀, Ajé onísọ̀ ibòji Asèwe dàgbà Asàgbà dèwe Ẹni tí ẹrú àti ọmọ ń fi ojojúmọ́ wá kiri Ìwọ ni àbámọ̀ tí ó borí ayé Ajé, Ìwọ làjíkí Ajé, Ìwọ làjígẹ̀ Ajé, Ìwọ làjípè Eni amúṣokun Eni amúsedè Iwo lani ra opolo aran aso oba ti kona yanranyanran Aje agba orisha je ki ni lowo maje ki ni e lorun Aje fi Ile MI se ibugbe, fi odede MI se ibura, aje o jire loni óò. [1]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 Salami, Segilola (2018-04-26). "Oriki Aje: Praise Poetry for the Goddess of Wealth and Prosperity". Segilola Salami. Retrieved 2019-12-31.
- ↑ Webmaster (2019-12-31). "Understanding Wealth Creation (Aje) Through the Concept of Yoruba Traditional Religion". NICO. Archived from the original on 2019-12-31. Retrieved 2019-12-31.
- ↑ "AJE: Yoruba deity of wealth". The Sun Nigeria. 2018-03-07. Retrieved 2019-12-31.