Jump to content

Èṣù

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
A mask representing Eshu.

Èṣù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Òrìṣà tí àwọn ìran Yorùbá ń bọ. Ó wà lára àwọn òrìṣà tí Olódùmarè rán láti ìkọ̀lé ọ̀run wá sí ayé. Èṣù ni a lè pè ní olópàá tàbí agbófiró àwọn òrìṣà yòókù tí Olódùmarè rán. Ìdí nipé òun ní o máa rí i dájú pé wọ́n tèlé òfin.[1] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ Eṣù tí yàtọ̀ láti orílè-èdè kan sí òmíràn, ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sìn í kò yàtọ̀.

Àwọn orúkọ mìíràn tí wọ́n ń pe Èṣù ni Ẹlẹ́jẹ̀lú, Olúlànà, Ọbasìn, Láarúmọ̀, Ajọ́ńgọ́lọ̀, Ọba Ọ̀dàrà, Onílé Oríta, Ẹlẹ́gbára Ọ̀gọ, Olóògùn Àjíṣà, Láàlú Ògiri Òkò, Láàlù Bara Ẹlẹ́jọ́, Láaróyè Ẹbọra tí jẹ́ Látọpa.[2]

Èṣù jẹ́ alágbára, òrìṣà tó wúlò, bẹ́ẹ̀ sì ni o jẹ́ òrìṣà tó wà ní ibi gbogbo to bẹ́ẹ̀to jẹ́ pé nínú ọjọ́ mẹ́rin ti Yorùbá ní, gbogbo rẹ̀ ní wọ́n fi ń bọ Èṣù. Èyí yàtọ̀ sí àwọn òrìṣà mìíràn tó jẹ́ pé wọ́n máa ń ni ọjọ́ kan nínú ọ̀sẹ̀láti fi bo wọ́n, ọjọ́ gbogbo ni ti Èṣù Ọ̀darà".[3]

Wọ́n máa kí Èṣù báyìí A-bá-ni-wá-ọ̀ràn-bá-ò-rí-dá "'Onílé- oríta"' "'Láàlú"' "'Òkiri-oko"' àwọn oríkì tàbí orúkọ yìí fihàn irú ẹni tí Èṣù jẹ́. Oríta ní Èṣù máa ń gbé. Èṣù jẹ́ alárèékérékè èdá. Òun ni ó ń kọ́ àwọn ènìyàn láti máa pé ojú méjì ni gbogbo ọ̀rọ̀ máa ń ní. Ó máa ń ṣọ̀tún, ṣòsì má ba ìbìkan jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ó máa ń tọ́ni sọ́nà. Ìdí nì yìí tí wọ́n fi sọ pé Ẹ̀ṣù ṣe pàtàkì láti ní ayé tó létò.

Gg bí ohun tí Oluwo Aderemi Ifaoleepin Aderemi láti Ọ̀yọ́ Aláàfin, sọ, ó ní Èṣù Láàlù jẹ́ ẹ̀dá tó burú, tó kún fún ìkà, àrékérekè nígbà tí Láaróyè Ajọ́ńgọ́lọ̀ Ọkùnrin Òde jẹ́ ẹ̀dá tó dára, máa ń fẹ́ òtítọ àti ìwà Omolúàbí. Ìránṣẹ́ Olódùmarè nìkan kọ́ ni Èṣù jẹ́, óò máa ń jiṣẹ́ fún àwọn òrìṣà mìíràn. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ alárinnà láàárín àwọn Ajogun àti àwọn èèyàn. Bẹ́ẹ̀ náà ni Èṣù lo wa nídìí gbígba ẹbọ àti pinpin ẹbọ fún àwọn  Ajogun.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Falola, Toyin (March 2013). Esu: Yoruba God, Power, and the Imaginative Frontiers. Carolina Academic Press (June 24, 2013). ISBN 978-1611632224. 
  2. Fatunmbi, Awo Baba Falokun (June 1993). Esu-Elegba: Ifa and the Divine Messenger. Original Pubns (January 1, 1993). ISBN 978-0942272277. 
  3. Fatunmbi, Awo Baba Falokun (June 1993). Esu-Elegba: Ifa and the Divine Messenger. Original Pubns (January 1, 1993). ISBN 978-0942272277.