Olódùmarè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Olódùmarè Káàkìri àgbáyé ni a ti mò pé olódùmarè wà, eni tí ó dá ayé àti òrùn àti ohun gbogbo ti ń be nínú won òyígíyigí oba àìrí arínú-róde Olùmòràn Òkàn, alèwílèse, alèselèwí, Oba atélè bí eni téní, Oba atésánmo bí eni téso, Oba lónìí, Oba lóla, Oba títí ayé àìnípèkun, Olówó gbogbogbo tí ń yomo rè nínú òfin, Oba Olójú lu kára bí ajere, Oba onínú fúnfún àti béè béè lo.[1][2][3]

Èyí ni pe oríkì Olódùmarè pọ̀ lọ jáǹtìrẹrẹ, bí a bá sì gbọ́ tí àwọn Yorùbá bá sọ pé ‘orí mi o tàbí olọ́jọ́ ọ̀ní o, Olódùmarè ni wọ́n ń pè ní orí, èyí tí ó dúró fún ẹlẹda orí àti ọlọ́jọ́ òní tí ó dúró fún ẹ̀ni tí ó nì ọjọ́ òní. Tàbí nígbà mìíràn tí àwọn Yorùbá bá rí Ohun tí ó ya ni lẹ́nu wọn á ní ‘Bàbá ò’ èyí tí ó dúró fún Olódùmarè.[4][5]

Àwọn ọmọ ènìyàn gbà wí pé ọlọ́run tóbi ju gbogbo ẹ̀dá lọ ó sì jẹ ẹni tí wọ́n gbọ́dọ̀ má a bọlá fún, èrò ọkàn àwọn Yorùbá ni pé ọlọ́run tàbí olódùmarè tóbi púpọ̀, ó sì ju ẹnikẹ́ni lọ àti nítorí èyí kò yẹ kí wọ́n máa dárúko mọ́ ọ lórí bí wọ́n ti ń ṣe sí ẹgbẹ́ àti ọ̀gbà wọn, láti bu ọlá fún-un àti láti fi ìtẹríba wọn hàn fún un wọ́n ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ pè é, wọn a ní ẹlẹda, èyí ní ẹni tí ó dá ọ̀run, àti ayé, òyígíyigì, èyí ni ẹni tí ó tóbi tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò sí ohun tí a lè fi wé. Ọba àwámárìdí, èyí ni ẹni tí a kò lè rí ìdí iṣẹ́ rẹ̀, Alábàláṣe, èyí ni ẹnì tí ó ni àbá àti àṣẹ, Bàbá, èyí ni baba gbogbo ẹ̀dá inú ayé, Ọ̀gá ògo; èyí ni ẹni tí ó ni ọ̀run èyí tí ó jẹ́ ògo ẹ̀dá tàbí nígbà mìíràn a lè túmọ̀ rẹ̀ sí ẹni tí ògo tàbí ìgbéga ẹ̀dá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, Atẹ́rẹrẹkáríaye, èyí ni ẹni tí ó tóbi, tí ó sì ní gbogbo ayé ní ìkáwọ́ rẹ̀, ẹlẹ́mìí, èyí ni ẹni tí ó ni ẹ̀mí ẹ̀dá.

Bí a bá tún gbó nígbà mìíràn tí àwọn àgbàlagbà ń lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi ‘Èdùàrè tàbí wọ́n ń lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi ‘olú’ olódùmarè kan náà ni wọn ń tọ́ka sí. Àwọn àgbàlagbà a máa sọ pé:

“Àṣegbé ọmọ Èdùàrè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

mo ló dàṣegbé

Àṣegbé ọmọ Èdùàrè…

Ohun tí àkọlé yìí ń tọ́ka sí ni pé ohun tí ọmọ Èdùàrè, èyí tí ó dúró fún olódùmarè bá ti ṣe àṣegbé ni ìgbà gbogbo là ń gbọ́ tí àwọn àgbàlagbà máa ń sọ pé “ẹni olúwa dá kò ṣe é fara wé”. Ohun tí wọn ń tọ́ka sí nínú gbólóhùn yìí nip é ẹni tí Olú, èyí tí ó dúró fún olódùmarè “bá ti dá àyànmọ́ kan mọ́ ẹnìkan, a kò lè fara wé irú ẹ̀nìyàn bẹ́ẹ̀.

Àwọn àkíyèsí tí a lè rí tọ́ka sí ni pé ọ̀pọ̀ ìtàn ìwásẹ̀ ni ó sọ bí Olódùmarè ṣe sẹ̀dá ayé àti ọ̀run, Yorùbá gbàgbọ́ pé ọ̀run ni olódùmarè wà, tí ó ti ń ṣe àkóso ayé àti ọ̀run, èrò Yorùbá ni pé kò sí ohun tí a ‘lè fi wé olódùmarè nítorí àwọn àwẹ̀mọ́ tàbí abuda rẹ tó tayọ àwa ẹ̀dá lọ fún àpẹẹrẹ a lè pe olódùmarè báyìí pé ‘Ẹlẹda, Ẹlẹ́mìí, Ọlọ́run Ọba ní í fọ́n èjí iwọ́rọ́ iwọ́rọ̣́, òun ló ni ọ̀sán àti òru dọ́jọ́ òní, òní ọmọ Ọlọ́fin, Ọ̀la ọmọ Ọlọ́fin, Ọ̀tunla ọmọ Ọlọ́fin, ìrènì ọmọ Ọlọ́fin, ọ̀rúnní ọmọ Ọlọ́fin, Yorùbá máa ń sọ pé ìṣẹ́ Ọlọ́run tóbi tàbí àwámárìdí ni iṣẹ́ Ọlọ́run, Ọ̀rúnmìlà fẹ̀yìntì ó wò títí o ní “ẹ̀yín èrò okun, ẹ̀yin èrò ọsa, ǹ jẹ́ ẹ̀yin ò mọ̀ pé iṣẹ́ Olódùmarè tóbi: A tún lè sọ pé Ọba Ọ̀run ọ̀gá Ògo, atẹ́rẹrẹ káyé ẹlẹ́ní àtẹ́ẹ̀ká, Ọba ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì í yẹ̀, alábà láṣẹ̀ á tun le pe ni alágbára láyé àti lọ́run.

Adùn ún ṣe bí ohun tí olódùmarè lọ́wọ́ sí, aṣòro o ṣe bí ohun tí olódùmarè kò lọ́wọ́ sí, Alèwílèṣe, Aṣèkanmákù. Ìgbà mìíràn a tún lè sọ pé ọlọ́run nìkan ló gbọ́n, ó rí ohun gbogbo, ó sì lè ṣe ohun gbogbo, Arínúróde Olùmọ̀ràn ọkan, Yorùbá sọ pé “Amòòkùn ṣolè bí Ọba ayé kò ri, Ọba ọ̀run ń wò ó, èyí túmọ̀ sí wí pé kò sí ohun tí a ṣe ní ìkọ̀kọ̀ tí Olódùmarè kò rí, kedere ni lójú Olódùmarè, àwọn òrìṣà ló máa ń jẹ àwọn arúfin ní ìyà ṣùgbọ́n Olódùmarè ló máa ń dájọ́ fún wọn, fún àpẹẹrẹ ní ìgbà kan gbogbo òrìṣa fẹ̀sùn kan ọ̀rúnmìlà níwájú olódùmarè lẹ́yin tí tọ̀tún tòsì wọ́n rojọ́ olódùmarè dá ọ̀rúnmìlà láre, odù ifá kan jẹri sí eléyìí, odù náà lọ báyìí “Ọ̀káńjùa kì í jẹ́ ka mọ nǹkan pínpín, Adíá fun odù. Mẹ́rìndín lógún níjọ́ ti wọn ń jìjà àgbà relé olódùmarè, nígbà tí àwọn ọmọ ìrúnmọlẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rìndínlógún tán ń jìjà ta ni ẹ̀gbọ́n ta ni àbúrò láàárin ara wọn, wọ́n kẹ́jọ́ lọ sódọ̀ olódùmarè, níkẹyìn, olódùmarè dá ẹjọ́ pé èjìogbè ni àgbà fún àwọn odù yókù. Yorùbá gbàgbọ pé onídàjọ́ òdodo ni olódumarè, ìdí nìyí tí Yorùbá fi ń sọ pé ọlọ́run mú u tàbí ó wà lábẹ́ pàṣán ‘Olódùmarè. Òyígíyigì ọba Ọta àìkú fẹ̀rẹ̀kufẹ̀, a kì í gbọ́kú Olódùmarè. Tí a bá tún wo Ọ̀kànrànsá (odù ìfa) òun náà tún sọ pe olódùmarè kì í ku, fún àpẹẹrẹ, Odù ọ̀kànrànsá yìí sọ pé:

Ọ̀dọ́mọdé kì í gbọ́kú asọ

yẹyẹyẹ laṣọ ogbó

àgbàlagbà kì í gbọ́kù aṣọ

yẹyẹyẹ laṣọ ogbó

Olódùmarè náà ni Ọba àìrí, àwámárìdí Yorùbá tún gbà pé ó jẹ Ọba mímọ́ tí kò léèérí, alálà funfun òkè. Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé bí àwọn áńgẹ́lì tí jẹ́ Olùrànláwọ́ fún Olódùmarè lóde ọ̀run ni àwọn òrìṣà náà jẹ́ aṣojú rẹ̀ lóde ìṣálayé, àwọn òrìṣà wọ̀nyí jẹ́ alágbàwí àwọn ènìyàn níwájú olódùmarè. A gbọ́ wí pé ìbáṣepọ̀ wà láàárin àwọn òrìṣà tàbí òòṣà ilẹ̀ Yorùbá àti Olódùmarè, àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pe òòṣà wọ̀nyí nì wọ́n lè rán sí olódùmarè yálà láti tọrọ nǹkankan lọ́wọ́ rẹ̀ tàbí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ohun ribiribi tí ó ṣe fún wọn. Erò yìí hàn nínú òwe Yorùbá kan pé “ẹni mojú ọwá là ń bẹ̀ sọ́wá, olójú ọwá kan kò sí bíkòṣe ayaba”. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ pé bí a bá fẹ́ kí Ọba ṣe ohun kan fún ni a ó bẹ ayaba sí i, ipò alágbàwí láàárin àwọn abòòṣà àti olódùmarè ni àwọn òòṣà wà.

  1. "Olódùmarè and The Concept of God of the Yoruba People.". Métissage Sangue Misto. 2020-03-25. Retrieved 2023-06-12. 
  2. Sanford, David (2022-04-07). "Who Is God? 5 Truths of God's Divinity". Christianity.com. Retrieved 2023-06-12. 
  3. "Who Is God?". Answers in Genesis. 2022-02-14. Retrieved 2023-06-12. 
  4. Denova, Rebecca (2022-11-15). "God". World History Encyclopedia. Retrieved 2023-06-12. 
  5. "Why God has different names in different ages and the significance of His names". Grow in Christ - Jesus Christ - Bible Study. 2020-04-21. Retrieved 2023-06-12.