Jump to content

Gẹ̀lẹ̀dẹ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Gelede)
Gelede costume from the Yoruba-Nago of Benin, 2013
Ìbòjú Gẹ̀lẹ̀dẹ́ ti ẹ̀yà Yorùbá tí wọ́n tọ́nú sí Birmingham Museum of Art
Àwòrán Gẹ̀lẹ̀dẹ́ tí wọ́ tọ́jú sí ilé-ìṣẹ̀mbáyé, Voodoo Museum Collection, Strassburg May 2014
Gelede Body Mask

Gẹ̀lẹ̀dẹ́ Jẹ́ òrìṣà kan nílẹ̀ Yorùbá tó níṣe pẹ̀lú àwọn obìnrin tí ó sì ń ṣàfihàn ipa àwọn obìnrin ní ilẹ̀ Yorùbá, pàápàá àwọn akínkanjú àti àwọn orìṣà tó ní ṣe pẹ̀lú àwọn obìnrin, pẹ̀lú agbára tó rọ̀ mọ́ ẹ̀mí àìrí bí ẹ̀mí àjẹ́ tí wọ́n ní. Ẹ̀wẹ̀, àwọn agbára wọ̀nyí ní ìpalára fún àwùjọ. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń lo Òrìṣà Gẹ̀lẹ̀dẹ́ láti fi rọ̀ wọ́n. [1]

Ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa Gẹ̀lẹ̀dẹ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Yorùbá gbàgbọ́ nínú gbólóhùn kan "ẹ̀sọ̀ layé" (The world is fragile). Ìdí ni wípé ayé ṣòro, ó sì gba jẹ́jẹ́, pàá pàá jùlọ kí a bára ẹni gbé ní ìrẹ́pọ̀, ìbọ̀wọ̀ àti àlááfíà.[2]

Ìtàn Ìwáṣẹ̀ Gẹ̀lẹ̀dẹ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Gelede mask, Afro-Brazilian Museum, São Paulo

Ọ̀pọ̀ ìtàn ìwáṣẹ̀ tó rọ̀ mọ́ òrìṣà Gẹ̀lẹ̀dẹ́ ni a ti rí púpọ̀ rẹ̀ nínú Odù Ifá. Ifá tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí ni ó ní Odù tí ó tó Igba ó lé Mẹ́rìnlélọ́gọ̀ta Odù, tí ìkọ̀ọ̀kan rẹ̀ sì ń dá lórí ènìyàn, ẹranko, àti àwọn Òrìṣà pẹ̀lú ìṣòro àti ọ̀na àbáyọ sí ìṣòro wọn èyí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀ sẹ́yìn. Ẹsẹ̀ Ifá ṣàlàyé bí Gẹ̀lẹ̀dẹ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Òrìṣà Yemọja tí ń ṣe 'ìyá gbogbo Òríṣà àti ohun abẹ̀mí. [3]Yemọja ló ń fomi ojú ṣògbéré ojú látàrí àìrọ́mọ bí rẹ̀, tí ó sì lọ bá Ifá fún ọ̀nà àbáyọ. Ifá ní kí ó rúbọ kí ó sì gbe ère ọmọ lángidi rù sórí jó, pẹ̀lú ẹ́gba irin lẹẹ́sẹ̀, ìgbà náà ni ó tó lè dọlọ́mọ láyé. Lẹ́yìn tí ó rúbọ náà tán, Yemọja finú ṣoyún ó sì fẹ̀yìn súnmọ sókè. Àkọ́bí ọmọ rẹ̀ jéọkùnrí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ "Ẹ̀fẹ̀" (the humorist); Ẹ̀fẹ̀ ma ń dàwọ̀n bojú láti fi àwọn ènìyàn ṣe yẹ̀yẹ́ àti àwàdà nítorí orúkọ rẹ̀. Àbíkéjì Yemọja tó jẹ́ obìnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ "Gẹ̀lẹ̀dẹ́" ni ó sanra gẹ́gẹẹ́ bí ìyá wọn, tí ó dì fẹ́ràn ìyá wọn gidigidi, tí òun náà sì fẹ́ràn láti ma jó. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọm méjèjì náà deni tí ń láya òun ọkọ, wọ́n níi. Ṣùgbọ́n, àwọn náà kò rọ́mọ bí, nìyá wọn bá tún gboko Aláwo lọ̀. Ifá ní kí Ẹ̀fẹ̀ òun Gẹ̀lẹ̀dẹ́ ó rúbọ tí ìyá wọ rú kí àwọn náà ó lè dọlọ́mọ láyé. Wọ́n rúbọ gẹ́gẹ́ bí ifá ti wí; ni wọ́n bá dọlọ́mọ wẹẹrẹ lọ́ọ̀dẹ̀. Ètùtù tí wọ́n ṣe yí ni ó di danadan láti ṣe lásìkọ́ ọdún Gẹ̀lẹ̀dẹ́ , tí wọnbyóò sì ma ṣe ẹ̀fẹ̀ lásìkò náà. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ wípé àwọn obìnrin ló ma ń gbé Gẹ̀lẹ̀dẹ́.

Àwọn ìtọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Yoruba Gelede Masquerade - The University of Iowa Museum of Art". Art & Life in Africa. Archived from the original on 2021-07-02. Retrieved 2021-05-29. 
  2. "Gelede". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2021-05-29. 
  3. "ATH 175 Peoples of the World". www.units.muohio.edu. Retrieved 2021-05-29.