Odù Ifá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Odù Ifá jẹ́ ọ̀rọ̀ tàbí ohùn ẹnu Ifá tí ó ní ìtumọ̀ sí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ sí ìgbésí ayé ẹni tí a ń dífá fún níbàámu pẹ̀lù ìṣẹ̀lẹ̀ ohun tó ti ṣẹ̀ kọjá. Bí a bá ń sọ̀rọ́ nípa àwọn Yorùbá àti ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wọn, kò ṣeé ṣe láti kó ọ̀rọ̀ Ifá kéré nínú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wón, pàá pàá jùlọ nínú gbogbo ẹ̀kọ́ tó rọ̀ mọ́ lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá.[1]

Ojú Odù[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Odù Ifá pín sí ojú odù igba ó lé Mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (256) nígbà tì àwọn ojú odù wọ̀nyí náà pín sí ọ̀nà mẹ́rìndínlógún tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ oríṣiríṣi bíi: ìmọ̀ ẹ̀rọ, ìmọ̀ ní bí ayé ṣe wà, ìmọ̀ ìṣègùn, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Odù ifá àti àwọn ẹ̀sẹ̀ ifá tí wọ́n pín sí tún dá lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ayé, òdodo, tí ó kún fọ́fọ́ fún àlàyé níoa àyànmọ́ ẹ̀dá òun ọ̀nà ibùlà fún ọmọ adáríhurun. Bákan náà ló tún jẹ́ ìmọ̀ ọ̀nà ìwádìí tí Elédùà yọ̀nda fú Ọ̀rúnmìlà baba Àgbọnìrègún láti fi ṣọmọ aráyé lóore. Àwọn odù Idá wọ̀nyí dà bí ojúpọ̀nà tí ọmọ ènìyàn lè gbà láti rí àyànmọ́ wọn lò ní kíkún, nípa bì àwọn Babaláwo tí wọ́n jẹ́ olùkọ́ ifá bá ṣe ṣàlàyé rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú Odù tì ó bá yọ fún ẹni abdífá fún gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rúnmìlà tí ó jẹ́ Babaláwo àkọọ́kọ́ ṣe làá kalẹ̀.

Àwọn Odù Ifá[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

1. Èjì ogbẹ 2. Ọ̀yẹ̀kú méjì 3. Ọ̀bàrà méjì 4. Òdì méjì 5. Ìwòrì méjì 6. Òfún méjì 7. Ìrosùn méjì 8. Ọ́wọ́rín méjì 9. Ọ̀kànràn méjì 10. Ògúndá méjì 11. Ọ̀sá méjì 12. Òtúúpọ̀n méjì 13.ìká méjì 14. Ìrẹtẹ̀ méjì 15. Ọ̀sẹ́ méjì 16. Òtúá méjì.[2][3]Àwọn àmì tí ó dúró fún odù kọ̀ọ̀kan ní wọ̀yí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

1 | |

| |

| |

| |

Èjì ogbè

2 || ||

|| ||

|| ||

|| ||

Ọ̀yẹ̀kú méjì

3 || ||

| |

| |

|| ||

Ìwórì méjì

4 | |

|| ||

|| ||

| |

Òdí méjì

5. | |

| |

|| ||

|| ||

Ìrosùn méjì

6 || ||

|| ||

| |

| |

Ọ̀wọ́nrín méjì

7 | |

|| ||

|| ||

|| ||

Ọ̀bàrà méjì

8 || ||

|| ||

|| ||

| |

Ọ̀kànràn méjì

9 | |

| |

| |

|| ||

Ògúndá méjì

10 || ||

| |

| |

| |

Ọ̀sá méjì

11 || ||

| |

| |

| |

Ìká méjì

12 || ||

|| ||

| |

|| ||

Òtúúrúpọ̀n méjì

13 | |

|| ||

| |

| |

Òtúá méjì

14 | |

| |

|| ||

| |

Ìrẹtẹ̀ méjì

15 | |

|| ||

| |

|| ||

Ọ̀sẹ́ méjì

16 || ||

| |

|| ||

| |

Òfún méjì

ídá[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]


[4]Àwọn ohun èèlò Ifá dídá[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. Ikín
 2. Ọ̀pẹ̀lẹ̀
 3. Ibò
 4. Ìrọ́kẹ́
 5. Ọpọ́n Ifá
 6. Agere Ifá tàbí Àwo Ifá
 7. Àpò Ifá
 8. Ìlù Ifá
 9. Ọ̀pá ọ̀rẹ̀rẹ̀ tábì Òsùn

 10. Àwọn ìwé ìtọ́ka sí

Àwọn ìwé ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. "Iwe fun Odu Ifa: Ancient Afrikan Sacred Text". Kilombo Restoration & Healing. Retrieved 2019-03-14. 
 2. "Odu Ifa". Farinade Olokun. 2018-12-30. Retrieved 2019-03-14. 
 3. ISBN 9780309063
 4. ISBN9780309063