Jump to content

Òrìṣà Egúngún

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Egúngún)
An egungun masquerade dance garment in the permanent collection of The Children’s Museum of Indianapolis

Egúngún tàbí Eégún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn òrìṣà àkúnlẹ̀bọ ní ilẹ̀ Yorùbá. Egúngún ni a tún mọ̀ sí ará ọ̀run.

Ìgbagbọ́ Àwọn Yorùbá nípa Egúngún

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ wípé nigba tí eégún bá jáde wípé òkú-ọ̀run ló wá bá àwọn ènìyàn rẹ̀ péjọ áti láti bá wọn jíròrò lará ohun kan tàbí òmíràn. Eégún jẹ́ òrìṣà kan tó ma ń daṣọ bórí ati gbogbo ara, aṣọ yí la mọ̀ sí ẹ̀kú tàbí agọ̀. Lásìkò tí egúngún bá jáde, ọjọ́ yí ma ń jẹ́ ọjọ́ ayẹyẹ àti ìdùnú fún àwọn ènìyàn, nítorí àwọn Yorùbá gbọ̀gbọ́ wípé ará-ọ̀run tó wá sáyé yóò lè bá àwọn gbé àdúra ati ẹ̀bẹ̀ ohun tí wọ́n bá fẹ́ lọ sí òkè ọ̀run tí àdúra wọn yóò sì gbà kíákíá. Egúngún jẹ́ òrìṣà kan ni ilẹ̀ Yorùbá tí a ma ń bọ láti rí àánú, ojú-rere, ọmọ, ìyàwó tàbí ohun tí a bá fẹ́ gbà. Fúndí èyí wọ́n ma ń fún egúngún lẹ́bùn kí ó lè bá wọn jíṣẹ́ẹ̀bẹ̀ wọn.

Àwọn Eléégún tàbí Ọlọ́jẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn tí wọ́n mú egúngún ṣíṣe níṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ olùsìn egúngún ni a mń pè ní Eléégún tàbí Ọlọ́jẹ̀. Àwọn wọ̀nyí.ni wọ́n ma ń ṣètò àti kòkárí ohun-kóhun tí ó bá ti jẹ̀ mọ́ egúngún gẹ́gẹ́ òrìṣà, tí wọ́n sì mo púpọ̀ nípa àṣírí egúngún.

Àwọn olóyè Egúngún

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Díẹ̀ lará àwọn olóyè eégún ni:

  1. Aláàgbáà: Òun ni olórí aláwo tàbí baba maríwo fún gbogbo eléégún pátá nínú ìlú kan.
  2. Alapini: apini ari pekun awo,agba oye leyo
  3. Ìyámọdẹ̀: Òun ni olórí fún àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ eléégún.
  4. Atọ́kùn egúngún: Èyí ni àwòrò tàbí ẹni tí ó mojú eégún kan tí ó sì ma ń mu káàkiri láti ojúlé sí ojúlé láàrín ìlú láti wúre fún àwọn ènìyàn.
  5. Ìyá àgan abbl.
  6. Ato: ato kekere abenu jele,atori oje ti nro namunamu nigbale
  7. Amusan:ogogo omo eru pasan
  8. Oloje: oje o koso arewa ni igbale oje
  9. Olota: ota giri agba
  10. Ologbin: esa ologbojo bajide
  11. Akio/Akewe:

Àwọn èwọ̀ tó rọ̀ mọ́ egúngún

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lára àwọn èwọ̀ egúngún ni:

  1. Èwọ̀ ni kí á fi ọkọ́ kọlẹ̀ ní ìgbàlẹ̀.
  2. Èwọ̀ ni kí eégún tẹ kùkù àgbàdo mọ́lẹ̀.
  3. Èwọ̀ ni kí òjò ó rẹ̀ lásìkò tí eégún bá ń pidán lọ́wọ́ ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

O je okan pataki lara ewo oro; a ki I foko ko le nigbale, omiran tun ni pe eegun o gbodo te fuku agbado mole, atiwipe bi eegun ba n padan lowo ojo o gbodo ro ba. Atokunrin atobinrin lo n sawo egungun. Osan gangan si ni eegun ma n jade.

Àwọn oríṣi eégún tó wà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Oríṣiríṣi ẹ̀yà eégún ni ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá, tí orúkọ wọn sì yàtọ̀ láti àdúgbò kan sí òmíràn àti ní ìlú sí ìlú.

  • Egúngún alábala. Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n ma ń pidán tí wọ́n sì ma ń yí aṣọ.
  • Egúngún Apẹ̀ṣà. Irúfẹ́ àwọn egúngún wọ̀nyí ló m a ń kọrin ki àwọn ènìyàn.
  • Egúngún Aláago. Àwọn eégún wọ̀nyí jẹ́ egúngún oní fàájì àti bbl. Orúkọ tí wọ́n ń pe àwọn egúngún wọ yí tún yàtọ̀ síra wọn ní ìlú sílú ati àdúgbò sí àdúgbò.

Ìtàn nípa Egúngún

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Onirunrun itan lo ro mo Iwasayi tabi ibere egungun sugbon eyi ti a o salaye ni Itan akoni ti a mo si Ogogo omo kulodo. Ogogo omo kulodo je akinkanju jagunjagun ni Ilu Oyo, no ojo kan iro kan Alaafin Oyo leti pe awon kan n kogun Bo lati wa ba Ilu Oyo, kin ni Alaafin gbo yii si ni o yara ke si Ogogo jagunjagun lati wa lo koju awon ota sebi koju ma ribi gbogbo ara bayi logun e. Nigba ti Ogogo omo kulodo doju ogun o ja ajasegun o Segun ota o reyin odi, bi o Se fe ma pada sile isele buruku kan se! Okan ninu awon ota won ni o moribo ninu iku ojona ti o si pawoda to tun Awo Se lo ba mu kini kan jade lati inu apo e loba fi meji kun ookan lo sa a bi oloogun ti n gbe sa a Lo ba fe fife to fe kini ohun konge ara ku lodo lo se, ni kulodo o ba le sokunrin mo, Ogogo wa so fun awon omo ogun e pe ko lo so fun won Nile pe ohun Ogogo omo kulodo ti bogun lo ati wi pe ohun a ma yoju si won lorekore. Leyin odun kan Ogogo ranse si awon ara oyo pe ohun n Bo ki won gbalugbajo, ki no mura ati gba alejo ohun, o si tun so fun omo e pe ki o ran aso wa fun ohun, eyi ti yio boju buse ti ko si ni fi ago ara kankan sile. Ojo ti Ogogo da ohun pe awon ara Ilu Oyo n reti alejo to n bo, awon kan tile n seye meji pe bawo ni ara orun sele waye, Ogogo o de titi o fi dojoro nigba ti oorun ti pari Ise oojo e. Nigba ti Ogogo wolu ko si eni to RI Oju tabi nnkankan lara e sugbon ohun re je tan Omole si iru eni ti n be ninu eku. Ogogo si n se bayi ni ododun. Eyi je okan lara ITAN to ro mo iwasaye egungun. Ko fe e si Ilu kan ni ile Yoruba ti ko ni egungun.



Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

The History of the Yorùbás by The Rev. Samuel Johnson. Síkírù Sàlámi Èsù e a ordem do universo.