Amẹ́ríkà Látìnì

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Amẹ́ríkà Látìnì
Ààlà21,069,501 km²
Olùgbé569 million[1]
DemonymLatino American, American
Àwọn orílẹ̀-èdè20
Dependencies10
Àwọn èdèSpanish, Portuguese, French
Time ZonesUTC-2  Brazil
UTC-8 Àdàkọ:MEX
Àwọn ìlú tótóbijùlọ1. Mexico City
2. São Paulo
3. Buenos Aires
4. Rio de Janeiro
5. Lima
6. Bogotá
7. Santiago
8. Belo Horizonte
9. Caracas
10. Guadalajara

Ìfáàrà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

“Ẹ tọ́kọ́ máa wa ìjọba òsèlú ná

Èyí tókù a ó sì fi fún yin

Àpilẹ̀kọ yìí ṣe àgbéyẹ̀wò ìbásepọ̀ láàrin Afíríkà (Yorùbá) àti ètò ìsèjọba ni Latin America, àti ní pàtàkì jùlọ bi wọn se igbógun tí àwọn ènìyàn Afíríkà nípa kíkópa nínú ìsèjọ̀ba Latin Amẹrika. Nígbà tí Brazil yóò dúró gẹ́gẹ́ bii burè fún síse àlàyé ní ọ̀rín kinníwín Afro-Brazilian ni a o máa fiwé àwọn ohun tí ó sẹlẹ ni orílẹ̀-èdè Afro-Latin America nípa ètò ìsèjọba àti ìgbési aye wọn ni ayé àtijọ́ àti ayé òde òní.

Iṣẹ́ yìí yóò yiri bi àwọn ènìyàn ilẹ̀ Afíríka tí se àmúlùmálà àṣà ọ̀làjú àti òsèlú ibi ti wọn ba ara wọn. Ìbéèrè ni pé ǹ jẹ́ ìgbé ayé àwọn ènìyàn ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni orílẹ̀ èdè Latin America dábòbò àṣà àti ìse wọn láti ẹ̀yìn wà bí? Tàbí ó mú ki àyípadà o de bá àjọsepọ̀ wọn?

Nígbà tí a bá sọ̀rọ̀ nípa Afíríkà ni àsìkò òwò ẹrú, Yorùbá jẹ́ ẹ̀yà kan pàtàkì tí àṣà àti ìse wọn borí to si gbajúmọ̀ jú láàrin àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ Afíríká yòókú. Fún àpẹẹrẹ gbogbo àṣà àti ìse Yorùbá bíi ẹ̀sìn, ìbọ̀risà àti ìgbàgbọ́ wọn ni wọn mu ni ọ̀kúnkúndùn ní òkè òkun níbi tí wọ́n kó wọn lọ gẹ́gẹ́ bíi ẹrú. Èyí kìí se àsọdùn rárá pé kàkà ki kìnníùn ṣe akápò Ẹkùn, oníkálukú yóò ṣe ọdẹ tirẹ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Nítorí náà a rí àwọn ẹrú tí wọ́n gbà pé àwọn yóò maa se àṣà àti ẹ̀sìn wọn bi àwọn ti ń se nígbà tí wọ́n wà ni Afíríkà, àwọn ẹrú ti wọn gbà pé wọn kò ní se àṣà àti ẹ̀sìn ìlú aláwọ̀ funfun ni wọn pàgọ́ (cadomble) tí Yorùbá si jẹ asaájú fún àwọn yòókù.

Ohun tí a ń sọ ni pe kàkà ti Yorùbá yóò fi faramọ́ àṣà, ẹ̀sìn àti ìse ibi ti wọn ba ara wọn, ẹ̀sìn àti àṣà ti wọn ni wọn gbe lárugẹ tí ó si gbilẹ̀ débi pe àwọn ẹ̀yà Afíríkà mìíràn darapọ̀ mọ wọn ti wọn si jọ ń bọ àwọn òrìṣà bíi Ẹ̀là, Ògún, Sàngó, Ọbàtálá, sanpọnna, Ọbalufọn àti àwọn irúnmọlẹ̀ yòókù ni òkè okun. Lára àwọn ìlú tí àwọn ènìyàn wa ni: Lati America, Bahia, Guayana, Brazil, Haiti, Alagre, Cuba, Columbia, Trinidad abbl. Nínú iṣẹ́ yìí a o lọ Afíríkà tàbí àwọn ènìyàn ilẹ̀ Adúláwọ̀ dípò Yorùbá fún ìtumọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́ nípa ìgbésí ayé wọn ní orílẹ̀-èdè Amẹrika.

Afro-American ni àwọn ènìyàn tí wọn kó ni ẹrú ní Afíríkà lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹrika (New world) àwọn ni wọn n sisẹ tí wọ́n si ń gbé àárín Amẹrika. Afro-Latin America ni àwọn ẹrú láti ilẹ̀ Afíríkà ti wọn kó wọn gba Amerika lọ si Gúsù Amerika (south American) ní àwọn ìlú bíi. Agentina, Mexico, Haiti, Cuba, Brazil abbl.

Ìyàtọ̀ tí ó wa láàrin Afro-America àti Afro-Latin America ni pé wọn kò gbà àwọn Dúdú (Afíríkà) láàyè láti ni ìbásepò pẹ̀lú àwọn aláwọ̀ funfun (oyinbo) ni Afro-America, ṣùgbọ́n kò sí ẹlẹ́yà-mẹ̀yà ní Afro-Latin America.

Ìsòro mìíràn tí ó tún kojú àwọn ènìyàn Afíríkà ni èdè, ni Afro-America, èdè ìsèjọba wọn ni èdè Gẹ̀ẹ́sì (English) ṣùgbọ́n èyí kò ri bẹ́ẹ̀ ní Afro-Latin America, èdè ìsèjọba ni èdè Faransé, Potogi àti Spanish (French, Prtuguese and Spanish). Èyí mú kí ó sòro fún àwọn ènìyàn láti ní ìbásepọ̀ tàbí ìfikùnlukùn àyàfi ki wọn o ri ògbufọ̀. Títí di ọdún 1970 si 1972 ni Brazil ó jẹ́ ìsòro fún àwọn ènìyàn ti o ń ṣe akọ̀ròyìn láti kọ nǹkan nípa Afíríkà.

Àwọn ìsòro mìíràn tí ó tún kojú àwọn ènìyàn Afíríka ni Àríwá Amẹrika n títa kò àti ìkórira àwọn Dúdú gbogbo ohun ti ko ba ti dara wọn gbà pé ọwọ Afíríkà lo ti wa. Wọn kò gbà ki àwọn Afíríkà ni asojú nínú ètò òsèlú àti ìjọba, bákan náà ni wọn ko ni ètò òsèlú àti ìjọba, bákan náà ni wọn ko ni ẹ̀tọ́ láti dìbò tàbí díje fún ipò kankan. Òfin kò fi ààyè sílẹ̀ fún àǹfààní bẹ́ẹ̀. Bí ìgbógun tí àwọn Adúláwọ̀ àti ìwà ẹlẹyamẹya se nípọn tó. Síbẹ̀, àwọn ènìyàn Afíríkà si ri ara wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà kanna, ibi yòówù ki wọn o wa, ìsòro yòówù ki wọn o maa la kọja.

Bi gbogbo ìsòro tí ó n kojú àwọn Afíríkà se pọ̀ tó yìí, ipa ti àwọn ti ó wà ni ìpàgọ́ kò se fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn, ni oṣù kinni ọdún 1976 àwọn ẹgbẹ́ tí ó wà ni ìpàgọ́ ni Bahia kò gba ìwé àsẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá kí wọn tó se ìpàdé tàbí ìwọ́de.

Bákan náà ni Colombia, ni agbègbè Caribbean (àwọn ẹru ti wọn sa) ni wọn pàgọ́ síbẹ̀, àwọn Palenquenos kò tijú láti fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí Afíríkà nípa ìgbé ayé wọn títí di òní.

Bákan náà ni a kò le sai mẹnu ba ipa ribiribi ti Manuel Zapeta Ollivella ti se onísègùn, òpìtàn àti òǹkọ̀wé ọmọ Afro – Colombian kó, láti ìgbà tí o ti wa ni akẹ́kọ̀ọ́ ni o ti fi ìfẹ́ hàn si ìjàgbara àwọn ènìyàn ilẹ̀ Afíríkà lọ́wọ́ àwọn amúnisìn. Ní ọdún 1950 o kópa nínú ìwọ́de ìta gbangba tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Afro-Colombian University se láti tako ìwà amúnìsìn. Ọmọ rẹ̀ obìnrin tí ó jẹ́ ọdọ Edeluma náà kọ ewì lórí àwọn adúláwọ̀. Nicomedes Santa Cruz ti o jẹ ọmọ Peru ni ẹni àkọ́kọ́ ti o kọ nǹkan nípa ìsòro tí ó ń kojú àwọn ènìyàn adúláwọ̀ tí o pe akọ̣le rẹ ni “congo Libre” tí o fi sọri Patrice Lummba. Nínú ìwé tí o kọ ni o se àfihàn ìbásepọ̀ to wà láàrin Afíríkà àti Peru. Ó sọ nínú ìwé rẹ ọgbọ́n tí àwọn alawọ funfun n da láti mu àdínkù ba àwọn Afíríkà àti bi wọn ó se. din agbára wọn kù, o fi ìwé rẹ náà tako ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà.

A o ni kógo jà bí a bá kùnà láti mẹ́nubà Abdias do Nascimento ti òun náà kọ ìwé lórí Afro-Latin America, iṣẹ́ òǹkọ̀wé yìí ni o gbegba orókè láàrin àwọn òǹkọ̀wé Afro-Brazilian.

Ìgúnlẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ni ibẹ̀rẹ̀ pẹpẹ ìbásepọ̀ láàrin adúláwọ̀ àti funfun dàbí ọmọ ọdọ si ọga rẹ (olówó rẹ) ṣùgbọ́n kò pẹ́ kò jìnnà, ìfarakínra nípa ìgbéyàwò , ẹ̀sìn bẹ̀rẹ̀ sí ní da àwọn méjèèjì papọ̀.

Àsẹ̀yìnwá, àsẹ̀yìnbọ̀ ikọlura àti ifagagbaga àṣà bẹ̀rẹ̀ si ni kò ara wọn jọ wọn n dá ẹgbẹ́ sílẹ̀ tí a mọ̀ sí ẹgbẹ ajìjagbara lọ́wọ́ amúnisìn. Àwọn dudu bẹ̀rẹ̀ si ni ri ara wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan láìwo ẹya tàbí ìlú tàbí gbe òsùnwọ̀n le bi iya ti ń jẹ wọn si.

Bí ó ti lẹ jẹ pé ìjàgbara láti kópa nínú ìsèjọba wáyé, ṣùgbọ́n kò so èso rere. Ní ọdún 1920 àwọn aláwọ̀dúdú dá ẹgbẹ́ òsèlú ti wọn sílẹ̀ ni orílẹ̀ èdè Brazil urugay àti Cuba. Ní orílẹ̀ èdè Brazil ni a ti dá ẹgbẹ́ tí a pè ní Frente Negra Brasilaira (Brazil Front) wọn forúkọ ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn elétò ìdìbò gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ òsèlú, ṣùgbọ́n ìjákulẹ̀ dé báa ìgbésẹ̀ yìí látàrí ìfipá gba ìjọba ológun lọ́wọ́ ìjọba lágbádá tó wáyé. Ní ọdún 1937 tí o si fi òfin de ẹgbẹ́ òsèlú síse. Lẹ́yìn èyí ẹgbẹ́ náà tún bẹ̀rẹ̀ ìpàdé wọn ṣùgbọ́n ojú àpá kò jọ ojú ara nítorí pé ìpàdé yìí kò lọ́wọ́ òsèlú nínú bíi ti tẹ́lẹ̀.

Láàrin ọdún 1973 – 5 ni àwọn àyípadà díẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní dé bá àwọn adúláwọ̀ tí ó wà lábẹ́ ìjọba Brazil. Gbigba ominira orílẹ̀-èdè guinea-Bissau Mozambique àti Angol kò sàì lọ́wọ́ ipa ti orílẹ̀ - èdè Brazil kó nínú. Bákan náà ni ipa ti Brazil ko nípa èdè àti àṣà Afíríkà kìí se kèrémí. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn Angola ni wọn ń ṣe àtìpó ní Brazil.

ÌWÉ ÌTỌ́KASÍ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Anani Dzidizienyo (African Yoruba) Culture and the Political Kingdom in Latin America. Afro-American Studies Brown University Providence, Rhodeisland

Charles Aderenle Alade: Aspect of Yoruba culture in diaspora . Roger Bastide (1971) African Civilization in the New world. Hurst London.



  1. "CIA — The World Factbook -- Field Listing — Ethnic groups". Archived from the original on 2018-11-16. Retrieved 2008-02-20.