Ìpínlẹ̀ Ògùn

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Ipinle Ogun)
Ìpínlẹ̀ Ògùn
Nickname(s): 
Ibudo Ìpínlẹ̀ Ògùn ni Naijiria
Ibudo Ìpínlẹ̀ Ògùn ni Naijiria
Coordinates: 7°00′N 3°35′E / 7.000°N 3.583°E / 7.000; 3.583Coordinates: 7°00′N 3°35′E / 7.000°N 3.583°E / 7.000; 3.583
Orile-ede Nigeria
Ojoodun idasile3 February 1976
OluiluAbẹ́òkúta
Government
 • GominaDapo Abiodun (APC)
 • Deputy GovernorNoimot Salako-Oyedele
 • Awon Alagba
 • Ile-asofinOgun State House of Assembly
Area
 • Total16,980.55 km2 (6,556.23 sq mi)
Area rank24k ninu 36
Population
 (2006 census)
 • Total3,751,140
 • Rank16k ninu 36
 • Density220/km2 (570/sq mi)
Demonym(s)Ògùn
GDP
 • Year2007
 • Total$10.47 billion[1]
 • Per capita$2,740[1]
Time zoneUTC+01 (WAT)
ISO 3166 codeNG-OG
HDI (2016)0.549[2] · 7th of 36

Ìpínlẹ̀ Ògùn jẹ ọ̀kan lára àwọn Ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n da Ìpínlẹ̀ Ògùn sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì, ọdún 1976. Ìpínlẹ̀ Ògùn fi ẹ̀gbẹ́ kan ẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Èkó lápá gúúsù, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lápá àríwá, Ìpínlẹ̀ Òndó àti Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Benin lápá ìwọ̀-oòrùn. Gómìnà ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ni Ọmọọba Dapo Abiodun tí wọ́n dìbò yàn-án wọlé lọ́dún 2019. Abẹ́òkúta ni olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Ògùn àti ìlú tí ó ní ọ̀pọ̀ olùgbé jùlọ ni ìpínlẹ̀ náà. Méjì lára àwọn ìlú míràn tí ó ṣe pàtàkì ni Ìpínlẹ̀ Ògùn ni Ìjẹ̀bú-Òde, olú-ìlú ọba aládé tí Ìjẹ̀bú Kingdom fún ìgbà kàn rí àti Sagamu, ìlú tí ńṣe aṣáájú níbi ká gbin obì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.Ijoba ibile Ado odo ota je okan pataki lara awon ijoba ibile ni ipinle ogun to n se agbateru oro aje to munadoko.

Àwọn ènìyàn tó ti jáde ní ìpínlẹ̀ Ògùn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìpínlẹ̀ Ògún jẹ́ dídílẹ̀ láti ọwọ́ ìjọba Murtala/Ọbásanjọ́ ní ọjọ́ kẹ́ta oṣù kejì, Ọdún 1976 látara níhàa ìwọ̀-oòrùn àtijọ́. Wọ́n sọ ìpínlẹ̀ náà lẹ́yìn odò Ògùn, tí odò náà sàn káàkiri ìpínlẹ̀ náà láti Àríwá lọ sí Gúúsù. Ìpínlẹ̀ náà ní àyíká ìgbìmọ̀ ìjọba agbègbè ogún lọ́wọ́lọ́wọ́. Ìpínlẹ̀ Ògùn ní ọwọ́ ajẹmọ́-ìran mẹ́fà tótóbi, àwọn náà: Ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú, Rẹ́mo, Ẹgbádọ̀, Àwọrí àti Ègùn. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn kékeré mìíràn wà bí Ìkálẹ̀, Kẹ́tu, Ohori àti Anago. Ìwé- ìpamọ́ jẹ́ẹ̀rí pé ìpínlẹ̀ yìí ló ní Fáṣítì Àdáni àti ilé-ìwé gíga ní Nàìjíríà àti ìpínlẹ̀ tó ní Fáṣítì ìpínlẹ̀ ara rẹ̀ méjì ni Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ Ògùn tún jẹ́ ilé fún Fáṣítì fún Ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ àti ìgbẹ̀yìn.[3] [4]

Ìpínlẹ̀ Ògùn tí pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olórí ìjọba ní Gúúsù-Ìwọ̀n Oòrùn. Gbogbo àwọn ara Gúúsù  Ìwọ̀-Oòrùn tó ti jẹ Ààrẹ tàbí olórí ìpínlẹ̀ fún ìlú wá láti ìpínlẹ̀ Ògùn (Ọbásanjọ́, Shónẹ́kàn) wọ́n gba oríyìn láti ìpínlẹ̀ Ògùn. Olóyè Jeremiah Ọbáfẹ́mi Àwọ́lọ́wọ̀, Olórí àkọ́kọ́ fún Agbègbè Ìwọ̀-oòrùn, ó dè jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Ògùn. Àwọn ará Ìjẹ̀bú ní ìpínlè yìí ni àwọn Yóò á àkọ́kọ́ tó nínú ìbásepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará úrópù ní ṣẹ́ńtíúrì kẹrìnlá. Àwọn ènìyàn náà tún gbà wí pé àwọn ni ẹ̀yà Yoòbá  tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní ma lọ owó tí a mọ̀ sí owó-Ẹyọ, tí ó jẹ́ àtawọ́gbà ní gbogbo ilẹ̀ Yorùbá kí wọ́n tí rópò rẹ̀ pẹ̀lú kọ́ìsì nígbà tí àwọn úrópù dẹ́.[5]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 "C-GIDD (Canback Global Income Distribution Database)". Canback Dangel. Retrieved 2008-08-20. 
  2. "National Human Development Report 2018" (PDF). 
  3. "List of Tribes & Local Government in Ogun State Nigeria.". School Drillers. 2021-02-22. Retrieved 2022-04-20. 
  4. "Brief History of Ogun State:: Nigeria Information & Guide". Nigeriagalleria. 1976-02-03. Retrieved 2022-04-20. 
  5. "6 Important Facts about Ogun State You Probably Didn’t Know". Vanguard News. 2017-07-27. Retrieved 2022-04-20. 

Coordinates: 7°00′N 3°35′E / 7.000°N 3.583°E / 7.000; 3.583{{#coordinates:}}: cannot have more than one primary tag per page