Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ado-Odo/Ota

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ado-Odo/Ota
Ado-Odo/Ota is located in Nigeria
Ado-Odo/Ota
Ado-Odo/Ota
Location in Nigeria
Coordinates: 6°38′N 3°06′E / 6.633°N 3.100°E / 6.633; 3.100Coordinates: 6°38′N 3°06′E / 6.633°N 3.100°E / 6.633; 3.100
Country Nigeria
StateOgun State
Government
 • Local Government ChairmanSheriff Adewale Musa (APC)
Area
 • Total878 km2 (339 sq mi)
Population
 (2006 census)
 • Total526,565
Time zoneUTC+1 (WAT)
3-digit postal code prefix
112
ISO 3166 codeNG.OG.AO

Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ado-Odo/Ota jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tó wà ní Ìpínlẹ̀ Ògùn. Ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù karùn-ún, ọdún 1989 ni wọ́n da sílẹ̀. Ìjọba ìbílẹ̀ yìí ni èyí tó tóbi ṣìkejì ní ìpínlẹ̀ Ogun. Olú-ìlú rè wà ní Ota 6°41′00″N 3°41′00″E / 6.68333°N 3.68333°E / 6.68333; 3.68333. Àwọn ìlú mìíràn ní agbègbè náà ni: Araromi-Alade, Ado-Odo, Agbara, Igbesa, Iju-Ota, Itele, Kooko Ebiye Town, Owode, Sango Ota àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ó ní ìwọ̀ ilẹ̀ tó tóbí tó 878 km2 àti èrò ènìyàn tó tó bíi 526,565 lásìkò ìkarí ti ọdún 2006. Ó jẹ́ ilẹ̀ tó dáa fún iṣẹ́ àgbẹ̀, wọ́n sì máa ń gbin ohun ọ̀gbìn bíi: Kòkó, Obi, Epo, kọfí, Ẹ̀gẹ́, Igi Ose, Àgbàdo, àti ẹ̀fọ́.[1]

Àwọn Àwórì ló pọ̀ jù ní agbègbè yìí. Àmọ́, a ní àwọn ẹ̀yà mìíràn bíi Àwọn Ẹ̀gbá, Eguns, àti Yewas (Egbados). Lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn aàfin ọba mọ́kànlá ló wà ní ìjọba ìbílẹ̀ náà, tí ń ṣe: Olofin of Ado-Odo, Olota of Ota, Onilogbo of Ilogbo, Oloja Ekun of Igbesa, Onikooko of Kooko Ebiye, Onitele of Itele, Amiro of Ilamiro, Onitekun of Itekun, Olodan of Odan Abuja Sule, Alagbara of Agbara, Onigun of Odan-Abuja, Onikogbo of Ikogbo, Olu of Owode Ota, Olu of Atan Ota, Olu of Ijoko Ota àti Olu of Tigbo Ilu .[1]

Kóòdù ìfìwéránṣe ti agbègbè náà ni 112.[2]

Alága ìbílẹ̀ náà ni Hon. Sheriff Adewale Musa.

Ìjọba ìbílẹ̀ yìí ni Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, tí ń ṣe Olusegun Obasanjo ti wá, ibẹ̀ sì ni oko rẹ̀ wà, tó pè ní Obasanjo Farms.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 "Ado-Odo/Ota Local Government". Ogun State Ministry of Local Govt. and Chieftaincy Affairs. Archived from the original on 23 February 2013. Retrieved 3 February 2013.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Post Offices- with map of LGA". NIPOST. Archived from the original on 7 October 2009. Retrieved 2009-10-20.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)