Funmilayo Ransome-Kuti

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Funmilayo Ransome Kuti

70 year old Funmilayo Ransome-Kuti on her birthday.png
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí(1900-10-25)25 Oṣù Kẹ̀wá 1900
Abeokuta, Southern Nigeria
(lódeòní : Abeokuta, Ìpínlẹ̀ Ogun)
Aláìsí13 April 1978(1978-04-13) (ọmọ ọdún 77)
Lagos, Lagos State, Nigeria
(Àwọn) olólùfẹ́Israel Oludotun Ransome-Kuti
Àwọn ọmọOlikoye Ransome-Kuti (ọmọkùrin)
Beko Ransome-Kuti (ọmọkùrin)
Fela Anikulapo-Kuti (ọmọkùrin)
Dolapo Ransome-Kuti (ọmọbìrin)
Occupationolùkọ́, olóṣèlú, ajàfẹ́tọ́ ọmọ ènìyàn

Funmilayo Ransome Kuti, MON (Ọjọ́ karùndílógún oṣù kẹwá ọdún 1900 Abeokuta, Nàìjíríà - ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹrin ọdún 1978 Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà),[1] jẹ́ olùkọ́, olóṣèlú, ajàfẹ́tọ́ ọmọ ènìyàn àti agbé ìṣẹ̀ṣe lárugẹ. Ó jẹ́ ọkàn gbọ̀ọ́n lára àwọn olórí nígbà ayé rẹ̀. Ó jẹ́ obìrin àkọ́kọ́ tí ó m,áa kọ́kọ́ wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ní orílẹ̀ èdè rẹ̀.[2] Wọ́n maa ń pe Ransome-Kuti ní ògbóntà obìrin ajàfẹ́tọ́ ọmọ ènìyàn látàrí ipa tí ó kó nínu ìjàfẹ́tọ́ ọmọ ènìyàn, tí wọ́n sì tún maa ń pèé ní "Ìyá Ilẹ̀ Aláwọ̀ Dúdú." Ní ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ó jẹ́ alágbára tí ó ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn obìrin ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ní ọdún 1947, wọ́n pèé ní  West African Pilot pèé ní  "Abo kìnìún ti Lisabi" fún ipa tí ó kó gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn obírin ní Ẹ̀gbá láti ríi wípé àwọn obìrin kò sanwó orí mọ́. Làlà kokofẹ̀fẹ̀ yìí ní ó jẹ́ kí Ọba Ademola ẹ̀ẹ̀kejì fi orí ìtẹ́ sílẹ̀ ní ọdún 1949.

Kuti jẹ́ ìyá ajàfún ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn, Fela Anikulapo Kuti, olórin; Beko Ransome-Kuti, dòkítà àti ọ̀jọ̀gbọ́n Olikoye Ransome-Kuti, tí ó jẹ́ dókítà àti mínísítà.[3] Ó jẹ́ ìyá-ìyà olórin Seun Kuti àti Femi Kuti.

Ìgbésíayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Funmilayo Ransome-Kuti, akàwégboyè

Wọ́n bí Francis Abigail Olúfúnmiláyọ̀ Thomas ní ọjọ́ karùndílógún oṣù kẹwá ọdún 1900, ní ilú Abeokuta, fún Daniel Olumeyuwa Thomas àti Lucretia Phyllis Ọmọ́yẹni Adeosolu. Bàbá rẹ̀ jẹ́ ọmọ ẹrú, Ebenezer Ṣóbọ̀wálé Thomas tí ó wálé láti Sierra Leone, tí orísun rẹ̀ jẹ́ Abeokuta tí a mọ̀ sí Ìpínlẹ̀ Ògùn lóde òní, Nàìjíríà.[4] Ó jẹ́ ọmọ elẹ́sìn ìjọ Anglican faith, tí ó sì padà lọ bá àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ ọmọ Ẹ̀gbá.

Ó lọ sí ilé ìwé Abeokuta Grammar school, ó sì kẹ́kọ́ sí ní orílẹ̀ èdè England. Kòpẹ́ kòjìnàn tí ó padà sí Nàìjíríà tí ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ olùkọ́. Ní ọjọ́ ogún oṣù kínín ọdún 1925, ó fẹ́ Àlùfáà Israel Oludotun Ransome-Kuti. Ó jẹ́ olùgbèjà fún àwọn aláìlẹ́nìkan, ó sì jẹ́ olùdásílẹ̀ Nigeria Union of Teachers àti Nigerian Union of Students.[5]

Ransome-Kuti gba ẹ̀bùn Order of Nigeria ní ọdún 1965. Yunifásítì Ìlú Ìbàdan fi ẹ̀bùn ọ̀mọ̀wé ìmọ̀ òfin dáa lọ́lá ní ọdún 1968. Ó sì tún jẹ́ ìkan lára àwọn olóyè ní ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí olóyè ní ilẹ̀ yorùbá.


Ìjàfẹ́tọ́ ọmọ ènìyàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní gbogbo ìgbé ayé rẹ̀, wọ́n mọ̀ọ́ sí olùkọ́ àti ajàfẹ́tọ́ ọmọ ènìyàn. Oun àti Elizabeth Adekogbe jẹ́ àwòkọ́ṣe olórí fún ìjàfẹ́tọ́ àwọn obìrin ní bíi ọdún 1950. Ó dá ẹgbẹ́ obìrin sílẹ̀ ní ìlú Abeokuta tí iye wọn sí jú ẹgbẹ̀rú lọ́nà ogún lọ, àwọn tó kàwé àti àwọn tí kò kà ló wà nínú ẹgbẹ́ náà.[6]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Funmilayo Ransome Kuti Nigerian Statesmen". 
  2. Modupeolu Faseke (2001). The Nigerian woman: her economic and socio-political status in time perspective. Agape Publications. ISBN 978-9-783-5626-53. https://books.google.com.ng/books?id=VMi3AAAAIAAJ&q=. 
  3. "Family tree: jibolu-taiwo-of-egbaland". 
  4. Margaret Strobel, "Women agitating internationally for change".
  5. Johnson-Odim, Cheryl; Mba, Emma (1997). For Women and the Nation: Funmilayo Ransome-Kuti of Nigeria. University of Illinois Press. ISBN 0-252-06613-8. 
  6. "Nigerian Biography: Funmilayo Ransome-Kuti. Biography and Activism.". www.nigerianbiography.com. Retrieved 2016-05-13.