Action Group

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Action Group (Nigeria))
Action Group
ChairmanObafemi Awolowo
Akọ̀wé ÀgbàAnthony Enahoro / Bola Ige
Ìdásílẹ̀1951 (1951)
Ìtúká16 Oṣù Kínní 1966 (1966-01-16)
IbùjúkòóIbadan
Ọ̀rọ̀àbáSocial democracy
Democratic socialism
Awoism
Ipò olóṣèlúCentre-left
Ìṣèlú ilẹ̀ Nigeria

Ẹgbẹ́ ìṣèlú Action Group jẹ́ ìkan nínú àwọn lààmì-laaka ẹgbẹ́ òṣèlú ajìjà òmìnira fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n dá sílẹ̀ ní Ìlú Ìbàdàn n inú oṣù kẹta ọdún 1951 láti ọwọ́ alagba Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ [[1]] Ìdí tí wọ́n fi dá ẹgbẹ́ yí sílẹ̀ ni láti rú ìmọ̀sílára àwọn ọmọ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti gbé ìgbésẹ̀ àti darapọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ ìṣèlú tókù gba òmìnira, àti láti dá ẹgbẹ́ ìṣèlú NCNC lọ́wọ́ kọ́ pàá pàá jùlọ ní apá Ìwọ̀-Oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn ikọ̀ tí wọ́n jẹ́ àpapọ̀ Ẹgbẹ́ ọmọ Odùduwà tí Alàgbà Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ dá sílẹ̀ nígbà tí ó wà ní London gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́.[2]

Ìtàn egbé òsèlú náà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ni odun 1941, Obafemi Awolowo bèrè egbé Nigerian Youth Movement ní ìlú Ibadan láti ma kó awon òtòkùlú ìlú tí o kàwé. Ni odun 1945, Awolowo tún dá egbé Omo Oduduwa sílè láti mu ki isopo wa larin Yoruba.[3]

Wón ni egbé náà ji se egbe òsèlú sùgbón o wa fun tokunrin tobinrin ile Yorùbá láti mu idagbasoke bá Yorùbá. Òpòlopò eniyan ní ìwò-oorun Nàìjíríà ló se atileyin fun egbé náà.

Ni March 21, odun 1951, Oloye Obafemi Awolowo da egbé Action Group kalè ni ìlú Ibadan. Ni osu kerin odun 1951, Oloye Samuel Akinsanya mú àbá wa pé kí wón pé àwon òtòkùlú ènìyàn ní ìwò-oorun Nàìjíríà láti darapò mó egbé òsèlú náà. Òpòlopò òtòkùlú oloye ni o kopa ninú ipade tí o wáyé ni Ìbàdàn ní osù kèwá dun 1951, láti da egbé òsèlù náà kalè. Bi o tilè jé wipé Dókítá alabere Akinola Maja ti o dari ipade náà ki ise Oloye.

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Awolowo, Obafemi (28 April 1951). "Freedom For All". Archived from the original on 12 July 2019. Retrieved 11 July 2019 – via artsrn.ualberta.ca. 
  2. "Egbe Omo Oduduwa : a study in ethnic and cultural nationalism". www.npg.si.edu (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-04-30. 
  3. Ayoade, John A. A. (1985). "Party and Ideology in Nigeria: A Case Study of the Action Group". Journal of Black Studies 16 (2): 169–188. ISSN 0021-9347. https://www.jstor.org/stable/2784260.