Jump to content

Bọ́lá Ìgè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Bola Ige)
James Ajibola Ige
Gomina Ipinle Oyo 2k
In office
October 20 1979 – October 20 1983
LieutenantSunday Afolabi
AsíwájúPaul Tarfa
Arọ́pòVictor Olunloyo
Alakoso Ijoba Apapo fun eto Idajo
In office
January 3 2000 – December 23 2001
Arọ́pòBayo Ojo
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí(1930-09-13)Oṣù Kẹ̀sán 13, 1930
Esa-Oke
AláìsíDecember 23, 2001(2001-12-23) (ọmọ ọdún 71)
Ibadan
Ọmọorílẹ̀-èdèNaijiria
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAction Group, Unity Party of Nigeria, Alliance for Democracy
(Àwọn) olólùfẹ́Atinuke Ige
Alma materUniversity of Ibadan
OccupationAgbejoro

James Ajibọ́lá Adégòkè Ìgè (September 13, 1930 - December 23, 2001) jẹ́ ọmọ Yorùbá, agbẹjọ́rò ati olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní apá ìwọ̀-Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. A bí Ìgè ní ọjọ́ kẹtàlá oṣu kẹsàán ọdún 1930, ó di olóògbé ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣu kejìlá ọdún 2001. Ìgè di Alákòóso (mínísítà) ìjọba àpapọ̀ fún ẹ̀ka ètò ìdájọ́ àti Agbẹjọ́rò-Àgbà ìjọba àpapọ̀̀ láàrín ọdún 2000 títí di ọdún 2001 tí wọ́n fi fipá gba ẹ̀mí rẹ̀ nínú oṣù Kejìlá ọdún 2001.[1] Ìgè jẹ gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti osù kẹwàá ọdún 1979 títí dé osù kẹwàá ọdún 2003. Lẹ́yìn ìgbàtí ìjọ̀ba olósèlú padà dé ní ọdún 1999.[2]̣̣̣̣̣̣̣̣̣́́́́́́́


Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Jèmísìì Ajíbọ́lá Ìdòwú Adégòkè Ìgè ní ìlú ZariaÌpínlẹ̀ Kaduna ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹsàn-án ọdún 1930 bí ó tiḷẹ̀ jẹ́ pé ọmọ bíbí ìlú Ẹ̀sà ÒkèÌpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni àwọn òbí rẹ̀. [3] Ìgè gbéra lọ sí ìlú Ìbàdàn ní dédé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá láti lọ kẹ́kọ́ nílé ẹ̀kọ́ Ibadan Grammar School ní àárín ọdún 1943 sí 1948. Ó sì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ fásitì ti Ìbàdàn, lẹ́yìn èyí ni ó gbéra lọ sí ilé eré ẹ̀kọ́ University College London níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin ní ọdún 1961.[2]

Bọ́lá Ìgè dá ilé iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ tí ó pe ní Bola Ige & Co ní ọdún 1961, tí ó sì padà di Agbẹjọ́rò Àgbà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [4] Ìgè di ìlú-mọ̀ọ́ká agbẹjọ́rò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà látàrí ìṣọwọ́sọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mú béré béré ati akitiyan rẹ̀ lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó fi mọ́ ìṣèjọba àwa arawa. Bákan náà, Ìgè jẹ́ onígbàgbọ́ nínú ẹ̀sìn kìrìstẹ́nì.[5][6] Bọ́lá Ìgè tún mọ èdè mẹ́ta tó gbajúgbajà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìyẹn èdè Yorùbá, Igbo àti èdè Hausa lásọ yanrantí.[7] Ó kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ìwé, kò sì pẹ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n fi tẹ ìwé kan tí wọ́n fi ṣàkójọ àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí ìgbésí ayé rẹ̀ àti àwọn ìwé tó ń fi ọlá fún un jáde.

Ibẹ̀rẹ̀ ìṣèlú rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lásìkò ìṣèjọba àwa arawa alákọ̀ọ́kọ́, láàrín ọdún 1963 sí 1966 ní déédé ọmọ ọdún mẹ́tàlélọgbọ̀n, ó jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Action Group tí ó kópa nínú rògbòdìyàn tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú AG láàrín olóyè Obafemi Awolowo ati olóyè Samuel Ladoke Akintola [8] Bo la Ìgè di ọ̀tá pẹ̀lú Olusola Olaosebikan fún ìwà ìgbẹ̀yìn-bẹbọjẹ́ fún Olóyè Obafemi Awolowo.[9] Ìgè di kọmíṣọ́nà fún ètò ọ̀gbìn fún agbègbè Western Region nígbà náà láàrín ọdún 1967 sí 1970 lásìkò ìṣèjọba Ọ̀gágun Yakubu Gowon. Ní ọdún 1967, Bọ́lá Ìgè di ọ̀rẹ́ pẹ̀lú olóyè Olusegun Obasanjo tí ó jẹ́ adarí ikọ̀ ọmọ ogun ní bárékè ìlú Ìbàdàn lásìkò náà. [8] Lásìkò ìṣèjọba ológun àkọ́kọ́ ní ọdún 1970, Bọ́lá Ìgè gbógun tako ìpolongo ẹlẹ́yàmẹ̀yà ti àwọn World Council of Churches gbé ìgbésẹ̀ rẹ̀ nígbà náà. [2] Ọdún 1970 ń parí lọ ni ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Unity Party of Nigeria (UPN), ẹgbẹ́ tí ó rọ́pọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú Action Group.[2] Nígbà tí ọ̀gágun Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ gbé ìjọba kalẹ̀ fún alágbádá ní ọdún 1979, wọ́n dìbò yan Bọ́lá Ìgè gẹ́gẹ́ bí gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láàrín ọdún 1979 sí 1983. [4] Adebisi Akande, tí ó padà di gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni ó jẹ igbékejì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gómìnà nínú ẹgbẹ́ ìṣèlú UPN nígbà náà.[10] Ní inú ìdìbò ọdún 1983, tí Bọ́lá tún díje láti padà sípò gómìnà lábẹ́ abùradà UPN, ọ̀mọ̀wé Victor Omololu Olunloyo ló fẹ́yìn rẹ̀ balẹ̀ nínú ìdíje ìbò sípò gómìnà náà. Bọ̀lá Ìgè gbé abájáde èsì ìdìbò náà lọ sílé ẹjọ́, àmọ́ Olunloyo kò ló ju oṣù mẹ́ta lọ lórí alééfà gómìnà kí ọ̀gágun Muhammadu Buhari àti Tunde Idiagbon tí wọ́n jẹ́ ológun tó tún dìtẹ̀ gbàjọba lọ́wọ́ alágbádá. [7] Ìjọba ológun gbé Ìgè ju sátìmọ́lé pẹ̀lú ẹ̀sùn wípé ó fi owó ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ ṣara rindin, àmọ́ wọ́n tu sílẹ̀ ní ọdún 1985 lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba tí ọ̀gágun Ibrahim Babangida ṣe, ó sì padà sẹ́nu iṣẹ́ òjòọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí amòfin, agbẹjọ́rò ati ònkọ̀wé. Ó gbé ìwé kan jáde ní ọdún 1990 tí ó pe ní People, Politics And Politicians of Nigeria: 1940–1979, ìwé tí ó ti ń kọ ṣáájú kí wọ́n tó gbe jù sátìmọ́lé. Ó jẹ́ ìkan pàtàkì lára àwọn péréte tí wọ́n da ẹgbẹ́ afẹ́nifẹ́re sílẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ọ̀gágunSani Abacha wà lórí àlééfà, ó sì ń ṣoro bí agbọ́n lásìkò ìṣèjọba tìrẹ, Bọ́lá Ìgè gbìyànjú láti má da sí ohunkóhun tí ó níṣe pẹ̀lú ìṣèlú lásìkò náà.[2]

Ìjọba alágbádá ìkẹrin

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lẹ́yìn tí ọ̀gágun Sani Abacha papò dà tán tí ìjọba sì padà sọ́wọ́ alágbádá lẹ́ẹ̀kẹrin ní ọdún 1999 ni Bọ́lá Ìgè yọjú wípé òun nífẹ́ láti di Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lábẹ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú Alliance for Democracy, àmọ́ wọ́n kò mu. Lẹ́yin tí Olúṣẹ́gun Obásanjọ́ di ààrẹ tán ni ó fi Bọ́lá Ìgè jẹ Mínísítà fún ohun àlùmọ́nì àti agbára. Ó wà ní ipò yí láàrín ọdún 1999 sí 2000. [11] Ipá Bọ́lá kò fi bẹ́ẹ̀ kájú ipò yí látàrí àwọn ayídáyidà kan tí ó wà nídí ina Ọba. Lẹ́yìn èyí ni Ààrẹ bá tun fi jẹ Mínísítà fún ẹ̀ka ètò Ìdájọ́ àti Adájọ́ Àgbà fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láàrín ọdún 2000 sí 2001 [12] [4] Nínú osù kẹsàán ọdún 2001 ni Bọ́lá Ìgè sọ wípé ìjọba apápọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìṣàtúntò ìwé òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti wípé wọn yóò g e sí ojú-òpó ẹ̀rọ ayélujára fún gbogbo ènìyàn kí wọ́n lè lánfàní si níbi gbogbo. [13] Bọ́lá ṣe ìpolongo tako lílo òfin Ṣàríà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àwọn ìpínlẹ̀ apá òkè ọya .[1] Nínú osù kọkànlá ọdún 2001, Bọ́lá sọ wípé ìjọba àpapọ̀ kò ní fàyè gba ìjọba Ìpínlẹ̀ Sokoto láàyè láti sọ̀kò pa arabìnrin kan tí wọ́n fi ẹ̀sùn àgbèrè kàn, tí wọ́n sì dájọ́ nílé ẹjọ́ Gwadabawa wípé kí wọn lọ sọ̀kò pàá gẹ́gẹ́ bí òfin ṣàríà ti gbe kalẹ̀. Adájọ́ tí ó da ẹjọ́ náà ni adájọ́ Safiya Hussaini.[14] Ó ku diẹ̀ kí wọ́n fi Ìgè sí ipò ńlá kan nínú àjọ United Nations International Law Commission ni wọ́n fi ìbọn gé okùn ẹ̀mí rẹ̀ kúrú ní Ìbàdanìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ní ọjọ́ kẹtalélógún oṣù Kejìlá ọdún 2001, wọ́n yìnbọn pa Bọ́lá Ìgè ní ìlú Ìbàdàn, ṣáájú kí wọ́n tó pàá, òun ati àwọn kan ti ní fàá-kája nínú ẹgbẹ́ ìṣèlú wọn ní Ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun. Ní nkan bí ọ̀sẹ̀ kan sẹ́yìn ṣáájú ikú rẹ̀ ni àwọn kan tí a wọn kò mọ̀ ṣekú pa aṣòfin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Odunayo Olagnaju tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú AD, wọ́n fura wípé ìjà tí ó ń ṣẹlẹ̀ láàrín gómìnà Ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ìyẹn olóyè Bisi Akande ati igbákejì rẹ̀ Iyiola Omisore ti ó ṣokùnfà iku olóògbé náà.[1] Ní kété tí Ààrẹ Olúṣẹ́gun Ọba sàn ńọ́ gbọ́ ìró iku Bọ́lá Ìgè ni ó da Àwọn ṣọ́jà sígboro wípé kí wọ́n ó wà lójú lalákàn fi ń ṣọ́rí kí rògbòdìyàn ó má ba bẹ́ sílẹ̀ látàrí iku akọni olóògbé Bọ́lá Ìgè látàrí bí àwọn kan ṣe gbẹ̀mí rẹ̀ ní fọná-fọnsu.[15] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ògọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ni wọ́n fòfin mú lórí iku Bọ́lá Ìgè, tí ó fi mọ́ Iyìọlá Omisore, àmọ́ wọ́n padà yọ̀nda wọn náà ni. Títí di àsìkò yí, wọn kò mọ ẹni tí ṣekú pa Bọ́lá Ìgè. [16][17] Wọ́n sìnkú rẹ̀ sí ulẹ́ rẹ̀ tí ó wà ní Ẹ̀sà-Òkè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.[18] Nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó ti sọ sílẹ̀ nínú àwọn ìwé rẹ̀ ni ó ti sọ wípé " Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà dùn ńgbé, àmọ̀ òun kò mọ́ bóyá ó yẹ láti kú fún" .[19]

Àwọn ìwé tí ó ti kọ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Golden Quotes: a selection of my favourite inspirational quotations. Ibadan : Pocket Gifts ; Oxford : African Books Collective [distributor], c2000. x, 163 pp.; 19 cm. ISBN 978-129-496-5
  • Detainee's Diary Ibadan : NPS Educational, 1992. 262 p. ; 23 cm. ISBN 978-2556-45-9
  • People, Politics And Politicians of Nigeria: 1940–1979. Heinemann Educational Books. 1994. ISBN 978-129-496-5. 
  • Constitutions and the problem of Nigeria Lagos: Nigerian Institute of Advanced Legal Studies, 1995. 36 pp.; 21 cm. ISBN 978-2353-43-4
  • Kaduna Boy. NPS Educational. 1991. ISBN 978-2556-35-1. 

Àdàkọ:Portal box

Àwọn ẹ̀rí máa jẹ́mi nìṣó

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 1.2 "Troops deployed in Nigeria". BBC News. 24 December 2001. Retrieved 7 November 2009. 
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 Kaye Whiteman (1 January 2002). "Bola Ige – Dedicated lawyer building bridges in Nigerian politics". The Guardian (UK). Retrieved 8 November 2009. 
  3. "Homepage". The Nation Newspaper (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 8 March 2022. 
  4. 4.0 4.1 4.2 "About the Law Firm". Bola Ige & Co. Archived from the original on 10 December 2009. Retrieved 7 November 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. Jan Harm Boer (2006). Christians: secularism, yes and no Volume 5 of Studies in Christian-Muslim relations, Jan Harm Boer. 62. ISBN 9781553069614. https://books.google.com/books?id=fTMRAQAAIAAJ&q=Bola+Ige+Christian. 
  6. Bola Ige; Akinyemi Onigbinde (2000). The essential Ige: tribute to Uncle Bola at 70. Frontline Books. ISBN 9789783537613. https://books.google.com/books?id=aaYuAQAAIAAJ&q=Bola+Ige+Christian. 
  7. 7.0 7.1 FEMI ADEOTI (23 October 2009). "Olunloyo on 1983 Oyo guber". The Sun. Archived from the original on 28 November 2009. Retrieved 7 November 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  8. 8.0 8.1 "Bola Ige". OnlineNigeria. Retrieved 8 November 2009. 
  9. Alhaji Lateef Jakande (27 July 2009). "My Rivalry With Bola Ige". The News. Retrieved 7 November 2009. 
  10. "Emergency Declared in Nigeria After Killing of Justice Minister". The New York Times. 25 December 2001. Retrieved 6 November 2009. 
  11. Duro Onabule (5 June 2009). "Any favour for Sanusi as Gov of Central Bank?". Daily Sun. Archived from the original on 27 August 2009. Retrieved 7 November 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  12. Jim I Akhere. "Power Sector Reform in Nigeria: Plans, Progress and Challenges" (PDF). Nigeria Peoples Forum – USA. Archived from the original (PDF) on 27 February 2012. Retrieved 7 November 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  13. "GOVERNMENT TO REALIGN FEDERATION LAWS" (PDF). United Nations Public Administration Network. 14 September 2001. Archived from the original (PDF) on 27 February 2012. Retrieved 7 November 2009. 
  14. Yakubu Musa, Kano And Isah Ibrahim Maru (18 November 2001). "FEDERAL GOVERNMENT, SOKOTO FIGHT OVER WOMAN'S DEATH SENTENCE". This Day. Archived from the original on 17 March 2008. Retrieved 7 November 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  15. Alex Duval Smith (26 December 2001). "Nigerian troops deploy after minister's murder". The Independent. Retrieved 7 November 2009. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]Àdàkọ:Cbignore
  16. "2003 County Reports on Human Rights Practices: Nigeria". U.S. Department of State. 28 February 2005. Retrieved 5 November 2009. 
  17. Iyabo Lawal (14 September 2009). "Family, friends remember Bola Ige". The Guardian. Retrieved 7 November 2009. 
  18. "Minister buried with honours". News 24. 11 January 2002. https://www.news24.com/News24/Minister-buried-with-honours-20020111. 
  19. Sola Odunfa (2 July 2004). "Is Nigeria worth dying for?". BBC News. Retrieved 7 November 2009. 

Àwọn ìtàkùn ìjá sóde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Banjo, Ayo (ed.), Bola Ige: Passage of a Modern Cicero. An anthology of views, reviews and tributes, dedicated to the Nigerian politician assassinated in 2001. B/w illus, 215pp, NIGERIA. BOOKCRAFT LTD, ISBN 978-2030-49-X, 2003. Paperback
  • Ladigbolu, A. G. A., Prince. The success of Bola Ige administration in the old Oyo State of Nigeria. [Nigeria]: Lichfield Printing Co., [2003] vii, 160 pp.: ill. ; 22 cm. ISBN 978-30498-2-8

Àdàkọ:Authority control


Ìkìlọ̀: Bọ́tìnì ìtò àkọ́kọ́ṣe "Ige Bola" dípò Bọ́tìnì ìtò àkọ́kọ́ṣe "Ige, Bola" tẹ́lẹ̀.