Clement Nyong Isong
Clement Nyong Isong | |
---|---|
Gómìnà ilé ìfówópamọ́ àpapọ̀ tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà | |
In office Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹjọ ọdún 1967 – Ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹsàn-án ọdún 1975 | |
Asíwájú | Alhaji Aliyu Mai-Bornu |
Arọ́pò | Mallam Adamu Ciroma |
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Cross River | |
In office oṣù kẹwàá ọdún 1979 – oṣù kẹwàá ọdún 1983 | |
Asíwájú | Babatunde Elegbede |
Arọ́pò | Donald Etiebet |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 20 April 1920 Eket, Akwa Ibom State, Nigeria |
Aláìsí | 29 May 2000 |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Naijiria |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Nne Clementine Isong |
Àwọn ọmọ |
|
Alma mater | Iowa Wesleyan University(B.A), Harvard Graduate School of Arts and Sciences(AM) |
Clement Nyong Isong, CFR tí wọ́n bí ní ogúnjọ́ oṣù kẹrin ọdún 1920, ó sìn kú ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2000 (20 April 1920 – 29 May 2000). O jẹ́ gbajúmọ̀ olóṣèlú àti onímọ̀ ilé-ìfowópamọ́ tí ó jẹ́ Gómìnà Ilé Ìfowópamọ́-àgbà tí Nàìjíríà lọ́dún 1967 sí 1975[1] nígbà ìṣèjọba ológun Ọ̀gágun Yakubu Gowon. Wọ́n wá padà dìbò yàn án gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Cross River lọ́dún 1979 sí 1983.[2]
ìgbé ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Isong ní ọjọ́ ogún oṣù kẹrin ọdún 1920 ní Eket, Ipinle Akwa Ibom. Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Fásìtì kọ́lẹ́ẹ̀jì Ibadan, lowa Wesleyan College, Mount Pleasant, Iowa, àti Havard Graduate School of Arts and Sciences, nibi ti o ti gba Ph.D. ni Iṣowo. O jẹ olukọni nipa ọrọ -aje ni University of Ibadan ṣaaju ki o to darapọ mọ Central Bank of Nigeria (CBN) gẹgẹbi akọwe, titi ti o fi di oludari iwadii. Otun wa pẹlu International Monetary Fund gẹgẹbi onimọran ni Ẹka Afirika
Àsìkò rẹ gẹgẹ bí Gómìnà banki CBN
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Yakubu Gowon yan Isong gomina CBN ni Oṣu Kẹjọ ọdun 1967, ọfiisi ti o wa titi di Oṣu Kẹsan ọdun 1975. Ohun kan na lo je Gomina banki Naijiria ni àsìkò ogún abele ti Biafra (1967-1970) àti nígbà tí èpò robi burẹkẹ ni orile-ede Naijiria. Ní akoko rẹ Naijiria yago fun jíjẹ gbèsè.O takò bi orile-ede Naijiria ṣe n ṣe ikojọpọ isura jọ sí òkè okun lai fi se idoko owo sí bí to yẹ, bi ọ tile je wipe iyato wa ni eto amayederun ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[3]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Events & Facts". Central Bank of Nigeria | Home. 2006-02-20. Retrieved 2021-10-14.
- ↑ 2.0 2.1 "Dr. Clement Isong". Central Bank of Nigeria. Retrieved 2010-02-28.
- ↑ Àdàkọ:Toka iwe
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |