Jump to content

Adewunmi Onanuga

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Rt. Hon Adewunmi Onanuga
Ọjọ́ìbíOtunba Adewunmi Oriyomi Onanuga
2 Oṣù Kejìlá 1965 (1965-12-02) (ọmọ ọdún 59)
Orúkọ mírànYomi Onanuga

Otunba Adewunmi Oriyomi Onanuga (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejì, oṣù Kejìlá, ọdún 1965),tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn mọ̀ sí IJAYA,ó jẹ́ Olóṣèlú àti oníṣòwò ilẹ̀ Nàìjíríà, tí ó jẹ́ igbákejì sí olóyè tó ń rí sí ètò ìdìbò lásìkò àríyànjiyàn ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojú ṣòfin láti ọdún 2023. Ó jẹ́ aṣojú fún agbègbè àríwá, Ikenne/Sagamu/Remo lápapọ̀ ní ilé ìgbìmọ̀ náà. A bi ní Hammersmith, ní orílẹ̀-èdè London sínú ìdílé òbí tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ ède Nàìjíríà.

Ní ọdún 2019, Otunba Adewunmi Onanuga [1] ó wọlé lẹ́yìn ìdíje dupò gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ilé ìgbìmọ̀ aṣojú ṣòfin tó ń ṣojú àríwá àgbègbè Ikenne/Sagamu/Remo lápapọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ogun, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní abẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress (APC), tí wọ́n sì búra fun gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ kẹsàn-án.Òun ni alága fún ajọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ obìnrin àti ìdàgbàsókè àwùjọ. [2] [3] [4] [5] [6]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Authority control