Jump to content

Àdúgbò Àgọ́-Ìwòyè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Adugbo Ago-Iwoye)

ÀGỌ́-ÌWÒYÈ: ÀDÚGBÒ

1. Ìsámùró:- Babaláwo kan wà ní àdúgbò yì tí orúkọ rẹ ń jẹ́ ìsà, ó má rń gba àwọn Àbíkú ọmọ, o máa ń mú wọn dúró láti má lè jẹ́ kí wọ́n kú. Orúkọ Bàbá yì ni wọ́n fi wá ń pé àdúgbó yí ní ìsámùró.

2. Ìdóbì:- A má ń ta ọbà ní àdúgbò yí. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ún pè ní ìdóbì.

3. Àyégbàmí:- Ọmọ ọkùnrin kan tí ó kọ́kọ́ dé àdúgbò yí ní ó ń jẹ́ àyégbàmí. Ìdí nìyí tí a fi n pè bẹ́

4. Òshọ́ òsì:- Orúkọ olóyè ìlú ni òshóòsì, oyè osì ìlú ni ó jẹ, ìdí nìyí tí a fi ń pè àgbolé yì ní òshóòsì

5. Olóòlù:- Aṣọ òkè ni wọ́n máa ń lù ní agbolé yìí, ìdí nì yí tí wọ́n fi ń pe agbolé yìí ní olóòlù.

6. Akadi eredo:- Agbolé yìí ni agbolé ẹni tí ó kọ́kọ́ jẹ oyẹ (èbùmàrè) ní ìlú Àgó ìwòyè, ìdí nì yí tí a fi ń pe agbolé yìí ní Akádì eredò.

7. Ẹdùwẹ:- Agbolé yì jẹ́ agbolé alágẹmọ, ẹni tí ó sì má ń gbé agẹmọ yì má ń dirun sórí bí ogbe orí àkùkọ adìẹ. Ìdí nìyí tí a fi ń pe agbolé yì ní Edùwe.

8. Bàtàdìran:- Ẹni tí o kọkọ tẹ̀dó si agbo-ile yi aso bata ni o n se pẹ̀lú ẹbi rẹ titi di asiko yi, ìdí niyi ti a fi pe agbole yii ni Batadiran.

9. Agbélékalè bí ère:- Agbolé yìí lati kọ́kọ́ kó ilé tó lẹ́rà jùlọ ní ìlú yìí, ìdí nì yí tí a fí ń pe agbolé yì ní Agbélékalẹ̀ bí ère.

10. Onàbámiró:- Ọ̀gbẹ́ni ọ̀nàbámiró jẹ́ ọ̀mọ̀wé, ó wà lárà àwọn tí ó gbé Àgó-Ìwòyè sókè de ini tí ó wà lónì yìí. Ìdí nì yí tí a fi ń fi orúkọ rẹ̀ pe Agbolé yìí.

11. Dòdùnmú:- Okunrin olukọ kan (teacher) ni o kọkọ wa si àdúgbò yi, ìdí níyi ti a fi ń pe ni dosunmu.

12. Olówó Iranrìn:- Okùnrin kan wà tí óun tá Ianrin ní àdúgbò yí láti bí ọdún pípẹ́ sẹ́yìn, ó sì ti se nkan rere ní ìdí isẹ́ yìí, ìdí nìyí tí a fí ń pé olówó iranrìn.


13. Olópò mérin:- Òpó mẹ́rin kan wà ní àdúgbò yí láti ọdun pípẹ́ wá títí di òní, ìdí nì yí tí a se ń fi orúkọ rẹ̀ pe àdúgbò yí bayi olópò mẹ́rin.

14. Ìmosù:- Osù ni isé tí àwọn ara àdúgbò yí yàn láye láti ọdún pípẹ́ wá títí di òní olónì, ìdí nìyí tí a fi ń pe àdúgbò yí ní Ìmosù.

15. Orogunebi:- Ọkùnrin kan tí ó ní ta ògùn tí ó sì kó ilé ni a n fí ilé rẹ̀ pe àdúgbò yí.

16. Oyinkìńkorò:- Ilé olóyè agẹmọ kan ni ó wà ní agbolé yìí, orúkọ rẹ̀ ni wọ́n sì fi ń pe agbolé yìí.

17. Obamijasi:- Àwọn agbo ilé méjì jà du oyè ọba, agbolé baálẹ̀ ato àti agbo ilé odùdányà, oyè yí wá jámọ́.

18. Bámè ato:- Agbolé èyí ní wọ́n ti kọ́kọ́ jẹ baálè ní ìlú Àgọ́ Ìwòyè (Baálè ató), Orúkọ Baálè yí nì asì fí ń pé agbolé yìí títí di òní olónìí.

19. Opopona ọja:- Inu agbole yi ni o ja ńlá kan wa ìdí niyi ti a fi n pe agbole náà ni opopona ọjà.

20. okenugbo:- Àdúgbò òkènúgbó jẹ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú kan tí à ń pè ní òkénúgbọ́n láti inú ìlú Àgó ìwòyè. Ọ̀nà yí ni wọ́n fi pe àdúgbò.

21. Ajọbì láwé:- Orúkọ àwọn ẹbi kan nìyí wọ́n kó ilé papọ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn, wọ́n àsi ń pe àdúgbò náà ní ajọbì láre.

22. Pàsedà:- Ògbẹ́ni passedà ní ilé-ìwé kan ní àdúgbò yí orúkọ ilé ìwé yìí ni “ọmọ-Edumare Model School” inú àdúgbò pàsedà lọ́nà.

23. Ìtamẹ́rin:- Ilé ìwé kan wà ní àdúgbò yí tí à ń pé ni Ìta mẹ́rin high school. Ìdí nìyí tí a fi ń pé àdúgbò yí ní ìtamẹ́rin.

24. Ìdodẹ̀:- Àgbolè yìí jẹ́ bi tí igi obì wà ìdí èyí ni wọ́n fi pè ní ìdobì.