Jump to content

Aina Gold

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Aina Gold (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹta ọdún 1963) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré àti olóòtú sinimá àgbéléwò. Ó tún jẹ́ gbajúgbajà onímọ̀ káràkátà ilé àti ilẹ̀.[1] [2]

Ìgbésí ayé rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àìná Gold kàwé gboyè ni ilé ìwé gíga ti Yaba Tech, ní ìlú Èkó. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà gẹ́gẹ́ bí olúkọ́ṣẹ́ lábẹ́ Òṣùmàrè Theatre Group àti àgbà òṣèrébìnrin, Ìdòwú Phillips tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Ìyá Rainbow. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni sinimá àgbéléwò tí ó ti kópa pàtàkì, lára wọn ní Alápátirá, Àgékù Àbẹ́là, Ẹ̀rùkẹ́rù, Ìlù Gángan, Akoto Ọlọ́kadà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Yàtọ̀ sí iṣẹ́ tíátà, Àìná Gold tún ní olùdásílẹ̀ ilé ìṣe Àìná Gold Estate ní ìlú Abẹ́òkúta olú ìlú ìpínlẹ̀ Ògùn, àti Multi-Choice Estate ní ìpínlẹ̀ Èkó. [3] [4]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Aina Gold Biography, Age, Family". 360dopes. 2018-07-28. Retrieved 2019-11-24. 
  2. "Age, Profile, Education, Love gossip, Hobbies - MyBioHub". MyBioHub. 2017-07-13. Retrieved 2019-11-24. 
  3. "Aina Gold Biography, Age, Career, Movies, Estate Business". NairaNaira.com. 2019-05-21. Archived from the original on 2020-05-09. Retrieved 2019-11-24. 
  4. "I'd have been making a lot of money if I'm into estate business’—Nollywood actor Aina Gold - The Nation Newspaper". The Nation Newspaper. 2013-08-17. Retrieved 2019-11-24.