Akadianu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí

Akadianu

Akkadian

Èdè sèmítíìkì kan ni eléyìí tí wón ń so ní ilè Mesopotámà láàárín séńtúrù 2300 sí 500 sáájú ìbí kírísítì (c2300 to c500). A tún máa ń pe èdè yìí ní Accadian. Ìgbà mìíràn a tún máa ń pè é ní Assyro-Babylonian. A mú orúko tí ó gbèyìn yìí láti ara àwon èka-èdè rè méjèèjì (Assyrian àti Babylonian). Èdè yìí ni ó rópò Sumerian tí wón ti ń so ní ìpínlè yìí télè. Èka-èdè Babylonian ni wón ti ń lò gégé bí èdè ìfisejobí (lingua france) láti ìbèrè pèpè láti nnkan bíi mìléníònù kìíní sáájú ìbí kírísítì (1st millennium B.C) sùgbón láàárín séńtúrì díè èdè Aramaic ti gba ipò rè síbè Babylonian sì tì jé èdè tí wón ń lò fún ìwé kíko àti kíkà tí di mìléníònù kìíní léyìn ikú kírísítì (1st Millenium A.D). Àkotó kúnífóòmù (Cuineform script) ni wón fi ko Akkadian sílè. Séńtúrì kokàndínlógún (19th century) ni wón tú u palè (decipher) sí èdè tó yé tawo-tògbèrì.