Jump to content

Aláàfin Ajíbòyèdé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ajíbóyèdé
Iṣẹ́Àlááfín

Àlááfín Ajíbóyelèdé jẹ́ ọba Àlááfín Ọ̀yọ́ apàṣẹ wàá tí Ọ̀yọ́ àti àwọn àgbègbè rẹ̀ ní sẹ́ńtútì kẹrìndínlógún.[1] He succeeded Orompoto.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó sẹ̀ nígbà ìjọba rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gẹ́gẹ́ bí ìtàn Ọ̀yọ́ kan ṣe sọ, Ọba àwọn ará Nupe, Lájọmọ ló kógun ja Ọ̀yọ́ nígbà ìjọba Ajíbóyelèdé. Ní ìbẹ̀rẹ̀, ogun náà ti ń gbe àwọn àrè náà kí nǹkan tó yí padà díẹ̀ látàrí ète akoni kan tí Ajàǹlápá, tí ó jẹ́ òsì-ìwẹ̀fà ṣe, tí ogun náà sì yíwọ́ padà wá gbé Ọ̀yọ́. Láti bọlá fún ìwà akíkanjú tí Ajàǹlápá ṣe, Ọba dá oyè kan sílẹ̀ láàfin láti bọlá fún ọmọ Ajàǹlápá. Wọ́n fún ọmọ Ajàǹlápá ní láti jẹ́ àlejò pàtàkì ọba láàfin àti láti máa rọ́pò ọba lórí ìtẹ́ nígbà mìíràn. Láìfọ̀rọ̀ gùn, ipò yìí jẹ́ ipò tí wọ́n ní láti tẹ ọmọ Ajàǹlápá lọ́dàá gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn Ọ̀yọ́mèsì. Ajíbóyelèdé lọ́kàn rẹ̀ rò pé yóò jẹ́ ìwà àìmore bí òun bá jẹ́ kí wọ́n tẹ ọmọ Ajàǹlápá lọ́dàá, ṣùgbọ́n àwọn olùmọ̀nràn rẹ̀ gbà á níyànjú láti ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣà ṣe làálẹ̀. Ọba tẹ̀lẹ́ ìmọ̀ràn wọn, wọ́n sì tẹ ọmọ náà lọ́dàá.

Ajíbóyelèdé ni ìtàn sọ pé ó bẹ̀rẹ̀ ọdún Bẹbẹ tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dún mẹ́ta mẹ́ta, láti ṣe àjọyọ̀ bí orí ogun àwọn Nupe àti ayẹyẹ ìjọba Ajíbóyelèdé lórí ìtẹ́ ọba.[1] Lásìkò ìjọba rẹ̀, àlàáfíà wà nílùú, àwọn àgbẹ̀ rí ère-oko tó dára, tí olú-ìlú tuntun, Igboho sì ń dàgbà sókè, pàápàá jù lọ nítorí àgbègbè àti àwọn ènìyàn tí wọ́n wà nílùú. Lásìkò náà, ọjà ńlá méjì ni wọ́n dá silẹ, tí ìlú náà sì wà jẹ́ ìlú pàtàkì tí ó lọ́jà tí àwọn Hausa ti máa ń wá ra ẹṣin.

Kò pẹ́ tí ọdún Bẹbẹ bẹ̀rẹ̀, àkọ́bí ọmọ Ajíbóyèdé, èyí tí ó jẹ́ Arẹ̀mọ Oṣemọ̀lú kú.[2] Whilst Ajiboyede was mourning and fasting he reportedly had some chiefs visiting him executed for supposedly having eaten food, which nearly caused a rebellion.[2]

Ọba Abipa ni ó jọba lẹ́yìn Ajíbóyèdé

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 Ogundayo, 'BioDun J., ed. African sacred spaces : culture, history, and change. ISBN 9781498567428. OCLC 1077789018. 
  2. 2.0 2.1 Smith, Robert (1965). "The Alafin in Exile: A Study of the Igboho Period in Oyo History". The Journal of African History 6 (1): 57–77. doi:10.1017/s0021853700005338. ISSN 0021-8537.