Jump to content

Aláàfin Awónbíojú

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Aláàfin Awónbíojú jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọba Aláàfin Ọ̀yọ́ tí ó j'ọba lọ́dún 1750 fún àádóje ọjọ́ (130 days) péré kí Baṣọ̀run Gáà fi jẹ́ kí ó pa ara rẹ̀.[1] Òun ni ó j'ọba lẹ́yìn Aláàfin Olabisi. Ó jẹ́ ọba tó rẹwà pẹ̀lú ìwà tútù. Ìtàn sọ wípé Baṣọ̀run Gáà ló ràn án lọ́wọ́ láti jọba ṣùgbọ́n Gáà pàpà hùwà burúkú rẹ́ fún òun náà débi pé, ó mú u pa ọ̀rẹ́ rẹ̀ ó sì bá òun náà fa wàhálà débi pé fúnra rẹ̀ ló gbẹ̀mí ara rẹ̀ nítorí ìwà ìkà tí Gáà u hù tí kò sì sí eni ti ó lè k'ojú rẹ̀. Aláàfin Awòbíojú pa ara rẹ̀ nítorí pé Gáà pàṣẹ fún un pé kó dọ̀bálẹ̀ kí òun, ìwọ̀sí yìí ni Aláàfin Awọbíojú kọ̀ tí ó fi pa ara rẹ̀.[2] [3]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Akinbode, Ayomide (2019-04-07). "Bashorun Gaa: The “Wicked Prime Minister” of the Old Oyo Empire – HistoryVille". HistoryVille. Archived from the original on 2022-09-22. Retrieved 2024-06-24. 
  2. Okùnadé, Johnson (2020-03-11). "The History of Old Oyo Empire (Oyo Ile) and Past Alaafin". Johnson Okunade Afro-Cultural Hub. Retrieved 2024-06-24. 
  3. "IS OYO HISTORY REPEATING ITSELF?". Google Accounts. 2007-10-22. Retrieved 2024-06-24.