Aláàfin Kánran
Aláàfin Kanran, tàbí Aláàfin Karan, jẹ́ Ọba ti Ọ̀yọ́ àti àgbègbè rẹ̀. Òun ló jọba lẹ́yìn Aláàfin Odawuru.
Wọ́n kà á sí ọba oníwàháià àti jàgídíjàgan, wọn sọ wípé onírúurú ìyà ni ó fi máa ń jẹ àwọn ará ìlú tí ó bá ṣẹ̀. Ìwà rẹ̀ ni ó bí òwe Ọ̀yọ́ kan tó sọ wípé " ó n'íkà nínú ju kánran". [1]
Nítorí ìwà ìkà tó ní láti ma ṣe ìjàmbá fún àwọn ará ìlú, àwọn olóyè kan gbìmọ̀ ọ̀tẹ̀ láti rọ̀ ọ́ lóyè. Àwọn Ọ̀yọ́mèsì máa kọ̀ọ́, wọ́n rọ̀ ọ́ lóyè. Òun náà kọ̀ láti pa ara rẹ̀.[2] Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun wọnú ìlú wá, ìtàn sọ pé Kánran sáré gun orí orùnlé ààfin rẹ̀, tí ó sì ń t'afà fún wọn títí wọ́n fi dáná sun ààfin ọba.[3]
Ọmọ rẹ̀, Janyin ló Jọba lẹ́yìn rẹ̀.
Àwọn àyọkà kan láti inú ìtàn Ọ̀yọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]"Kánran rán àwọn ọmọ-ogun láti ja àwọn ará ìlú Àgà Oìbó l'ógun, ṣùgbọ́n kí wọ́n tó kógun jàwọ́n, àwọn ọlótẹ̀ ti ránṣẹ́ sí ọba láti fi agbọ́pàá rẹ̀ ṣ'ètùtù."
"Kánran gbà láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, wọn sì gbé oúnjẹ ètùtù fún ọba láti jẹ. Bí Kánran ṣe jẹran ètùtù tán, àwọn ọlótẹ̀ kéde pé Kánran ti j'ẹran agbọ́pàá ara rẹ́"
"Lẹ́yìn èyí, nítorí ohun burúkú tí ọba ṣe, wọ́n kéde pé àṣẹ ọba kò ṣe é tẹ̀lé mọ́ fún ẹnikẹ́ni, pàápàá jù lọ àwọn ọmọ Ogun Ọ̀yọ́. Àwọn ọlọ́tẹ̀ wá pàṣẹ kí ọba pa ara rẹ̀, èyí tó túmọ̀ sí kí ọba kúrò lórí ìtẹ́. Nípa èyí àwọn jagunjagun Ọ̀yọ́ ti kẹ̀yìn s'ọ́ba nítorí pé ó ti jèwọ̀ àwọn òrìṣà."
"Páńpẹ́ tí wọ́n dẹ fún Kanran mú un, ìjà yìí niKánran ń bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà tí ó fi kú."
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Law, R. C. C. (1971). "The constitutional troubles of Ọyọ in the eighteenth century". The Journal of African History 12 (1): 25–44. doi:10.1017/s0021853700000050. ISSN 0021-8537.
- ↑ Ajayi, J. F. A.; Crowder, Michael (1987). History of West Africa. Longman. ISBN 0582016045. OCLC 476413782.
- ↑ Johnson, Samuel (August 2011). The history of the Yorubas : from the earliest times to the beginning of the British Protectorate. ISBN 0948390891. OCLC 989713421.