Aláàfin Onígbógi
Aláàfin Onígbógi jẹ́ ọba Aláàfin Ọ̀yọ́ àti àwọn àgbègbè-ìṣèjọba Ọ̀yọ́ lápá ìwọ̀-oòrùn Africa tí ó gorí ìtẹ́ lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀, Àlááfín Oluaso tó j'ọba Alááfin ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ n'ilu Ọ̀yọ́.
Gẹ́gẹ́ bí ìtàn kan tí Samuel Johnson tẹ́ jáde, ìyá rẹ̀, arugbá ifá fi ìlú rẹ̀ Ọ̀tà ní Ìpínlẹ̀ Ògùn ní Nigeria lati lọ gbé lọ́dọ̀ ọmọ rẹ̀ tí ó sì ń gbé ibẹ̀ gẹ́gẹ́ agbaninímọ̀ràn ọmọ rẹ̀. Nígbà tí ó ń bọ̀ ó kó ifá dání láti ma dá ààbò bo ọmọ rẹ̀ Ọba ìlú Ọ̀yọ́. Nígbà tó yá àwọn Ọ̀yọ́ Mèsì takò àbá rẹ̀ pé kí wọ́n máa bọ ifá. Nítorí ìdí èyí, ó bínú padà sí Ọ̀tà, lọ́nà nígbà tí ó ń padà sí ọta, Aládó gbáà lálejò tí ó sì pèsè àwọn nǹkan tó nílò fún ìrìn-àjò rẹ̀. Oore lore ń wọ́tọ̀, nítorí pé Aládó gbà á tọwọ́tẹsẹ̀ òun náà fi ọ̀nà ifá dídá han Aládó, ó sì fún ní òrìṣà ifá láti san oore padà fún un. Lẹ́yìn ọdún púpò, òrìṣà ifá wá di gbajúmò káàkiri ní Ọ̀yọ́ àti ní abúlé Aládó.
Ìgbà ìjọba rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Nígbà ọba Onigbogi, àwọn jagunjagun ọba àgbègbè-ìṣèjọba Nupe ráàyè wọ̀lú Ọ̀yọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ibasepo tó dára wà láàárín àwọn Yorùbá àti àwọn Nupe lásìkò ọba Aláàfin Ṣàǹgò, ọba kẹta ìlú Ọ̀yọ́, lásìkò yìí ni ìjà bẹ̀rẹ̀ láàárín wọn. Àwọn jagunjagun Nupe gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Ọ̀yọ́, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní dárí olú-ìlú Ọ̀yọ́, Ọ̀yọ́ ilé. Nígbà tó yá, Onigbogi sá kúrò lórí ìtẹ́ lọ sí ìlú àjèjì ní Borgu.