Àpíìrì

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Apiiri (Drum))
Jump to navigation Jump to search

Apiiri

Àpíìrì tàbí sẹkẹrẹ:

Aré yi wọ́pọ̀ lágbègbẹ̀ Èkìtì. Ó yàtọ̀ sí ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ti a kọ́kọ̣́ sàlàyé rẹ̀ nítorí pé a kìí lu aro, koso, àti bẹ̀mbẹ́ síi. Kìkì ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ là ń lù nìbi ti a ba nsere apíìri. Orìṣii ṣẹ̀kẹ̣̀rẹ̀ mẹ́ta là ń lù si apiiri.

(a) Ìya-àjẹ́: Àgbe to tobi díẹ̀ la fi n ṣe Iya-aje. E so igi kan bayi la n ṣe sara owu ti a ran. Bi a ba ti seetan, a o fi owu ti a se eso si yi kọ ara agbe náà lọwọọwọ titi de ọrun rẹ̀. Eso ara agbe yi ni n dun lara rẹ nìgba ti a ba n luu.

(b) Emele-ajè: Emele-aje meji la n lu si apiiri. Agbe la fi n ṣe e bi ti iya-aje. Agbe ti a fi n se emele-aje ko tobi to eyi ti a fi n se iya-aje. Ìdi niyi ti didun wọn ko fi fẹ dodo bi ti Ìya-aje.