Jump to content

Fìlà aṣo òfì

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Aso oke hat)

Fìlà aṣọ òfì (aṣo-òkè)ẹ̀yà fìlà tòmí rìrọ̀ jẹ́ fìlà Yorùbá tí wọ́n ń fi aṣo òfì húnhun ṣe,òwú àrán tàbí dàmáàsì.Nínú èdè Yorùbá irú rẹ̀ ni wòn ń pè ní fìlà.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ọorírun fìlà ni Nàìjíríà,ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin ni wọ́n ń wọ̀ ọ́ nínú ìran aláwọ̀ dúdú. Ìmọ́lára òkè fìlà gígẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan ni,ìyókù á sì tayọ etí ẹni tí ó dé e sókè.Àwọn kan sọ pé gígé fìlà sí apá ọ̀tún ń tọ́ka sí Àpọ́n kùnrin nígbà tí ẹ̀gbẹ́ òsì ń ṣàfihàn ọkùnrin tí ó ti níyàwó.wọ́n máa ń sáábà wọ̀ ọ́ pẹ̀lú aṣo ìmúròde yorùbá Agbádá(ṣe bákan náà pẹ̀lú aṣo òfì,léèsì tàbí aṣọ olówùú)tàbí dàńsíkí tí wọ́n fi aṣọ ṣẹ̀dá ṣe tí ó máa ń ní àwòrán lára. Púpọ̀ nínú àwọn ọkùnrin máa ń wọ fìlà bí i akẹ̀tẹ̀ pẹ̀lú aṣo léèsì dàńsíkí.síbẹ̀síbẹ̀ fìlà aṣọ òfì àrà aládé fìlà kúfí ni ó gbajúmọ̀ fún yíyàn tí a bá ń wọ aṣọ ìmúròde mìíràn.

Àwọn obìrin náà kò gbẹ́hìn tó bá dé bi kádé fìlà, wọ́n sábà máà fi rán akẹ̀tẹ̀ tàbí dé irúfẹ́ ti ọkùnrin. wọ́n sì máàn fẹ́ràn áti ṣeé ní ẹ̀ṣọ́ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ pẹ̀luu gíláásì bí òkúta kékèéké aláwò oríṣíríṣi tàbí, ìlẹ̀kẹ̀.