Fìlà aṣo òfì

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Fìlà aṣọ òfì (aṣo-òkè)ẹ̀yà fìlà tòmí rìrọ̀ jẹ́ fìlà Yorùbá tí wọ́n ń fi aṣo òfì húnhun ṣe,òwú àrán tàbí dàmáàsì.Nínú èdè Yorùbá irú rẹ̀ ni wòn ń pè ní fìlà.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ọorírun fìlà ni Nàìjíríà,ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin ni wọ́n ń wọ̀ ọ́ nínú ìran aláwọ̀ dúdú. Ìmọ́lára òkè fìlà gígẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan ni,ìyókù á sì tayọ etí ẹni tí ó dé e sókè.Àwọn kan sọ pé gígé fìlà sí apá ọ̀tún ń tọ́ka sí Àpọ́n kùnrin nígbà tí ẹ̀gbẹ́ òsì ń ṣàfihàn ọkùnrin tí ó ti níyàwó.wọ́n máa ń sáábà wọ̀ ọ́ pẹ̀lú aṣo ìmúròde yorùbá Agbádá(ṣe bákan náà pẹ̀lú aṣo òfì,léèsì tàbí aṣọ olówùú)tàbí dàńsíkí tí wọ́n fi aṣọ ṣẹ̀dá ṣe tí ó máa ń ní àwòrán lára. Púpọ̀ nínú àwọn ọkùnrin máa ń wọ fìlà bí i akẹ̀tẹ̀ pẹ̀lú aṣo léèsì dàńsíkí.síbẹ̀síbẹ̀ fìlà aṣọ òfì àrà aládé fìlà kúfí ni ó gbajúmọ̀ fún yíyàn tí a bá ń wọ aṣọ ìmúròde mìíràn.